Omoluwabi

Ilé-ẹ̀kọ́ gíga agbáyé ni  OMOLUWΑBI YUNIFÁSÍTÌ.
Ọ̀nà méjì ni a máa gbà fi kẹ́kọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ wa :
– Ìkẹ́kọ́ àti orí ìbùdó ayélújára
– Ìkẹ́kọ́ bíi ti àtijọ pẹ̀lù olùkọ́ni ni wájú àwọn akẹ́kọ́.
Àwọn alákóso àgbà akẹ́kọ́ wa  máa ní àǹfààní láti rọ àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé bíi kọ́ńpútà, ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀, ẹ̀rọ rédíò tí a sì máa wulò fún àwọn àsà àwọn ìlú adúláwọ̀.
– Ibi-afẹ́dé  àkọ́kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga OMOLUWΑBI ni kí a kọ́ àwọn akẹ́kọ́ alákóso àgbà wa ni ẹ̀kọ́ ti á fún wọ́n ni àǹfàànní láti lò ìmọ̀-ẹ̀rọ fi rọ àwọn ẹ̀rọ ti a máa wúlò púpọ̀ fún wa ni Áfíríkà àti ni agbáyé.
– Ibi-afẹ́dé èkejì ni kí àwọn akẹ́kọ́ wa mọ̀ èdè yorùbá tó dáńgájíá sọ, kà á àti kọ̀ ọ́ pẹ̀lù àwọn àṣàyàn nínú èdè Faransé àti Gẹ́ẹ́sì, kí wọ́n sì kọ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ wọn sí èdè yorùbá kó bà lè fún wọn láàfààní láti lò ó fún àwọn àṣà wa.
Àwọn olùkọ́ Yunifásítì omoluwabi máa ń ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú èdè yorùbá, tí wọ́n sì máa kọ àwọn ìwé wọn sí èdè náà.
Àwọn olùkọ́ wa jẹ́ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ nínú àwọn yunifásítì ní Αfíríkà, Αmẹ́ríká àti ní Yúróòpù.