Àwọn ìpele ilé-ẹ̀kọ́ omoluwabi

Ìgbìmọ̀ olùdárí

Àwọn ìgbìmọ̀ olùdárí ilé-ẹ̀kọ́ omoluwabi  jẹ́ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsì, àwọn amọ́yé, àwọn ọ̀jọ̀gbọ̀n onímọ̀ ìjìnlẹ̀.
Àwọn olùdárí yìí ni máa ń gbìmọ̀ ibi-afẹ́dé pẹ́lù ìdàgbàsóke ìmọ̀ àti ìwàdi ilé-ẹ̀kọ́ nínú sáyẹ́nsì. Àwọn olùdárí yìí náà ni máa ń yàn ìgbìmọ̀ alámojútó ẹ̀kọ́ àti ìgbìmọ̀ sáyẹ́nsì láti mú wọn sí ìmuse.

Ìgbìmọ̀ alámojútó ẹ̀kọ́

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ métà ló wà nínú ìgbìmọ̀ alámojútó ẹ̀kọ́. Αsíwájú wọ́n jẹ́ olùṣàkóso alámojútó ẹ̀kọ́ àti àwọn ètò. Àwọn olùṣàkóso yìí náà ni ṣálámojútó ètò ẹ̀kọ́, wọ́n tún ṣàkóso àwọn isẹ́ àwọn olùkọ́, wọ́n sì tún mójútó ìdágbàsókè ẹ̀kọ́.

Ìgbìmọ̀ sáyẹ̀nsì

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ ìmọ̀ ni wọ́n ṣàkóso àwọn àbájáde àwọn ìwàdi àwọn ẹ̀kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ wa , àwọn náà ni wọ́n á tún ṣérànlọwọ́ fún ìdàgbásóke àwọn ibi-afẹ́dé àwọn ìwàdi nínú ilé-ẹ̀kọ́.