Àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ìtanná máa ń darapọ̀ mọ́ àwọn amóju ẹ̀rọ ( ẹnjiníà ) tí ń rọ ẹ̀rọ tàbí tí ń tún wọn ṣe.
wọ́n sì tún máa darapọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́rọ tí ń ṣe àwọn ẹ̀rọ wọ̀nyìí, tí ń ṣe àṣéyẹ̀wò wọn tàbí tí ń ṣàtúnṣe wọn. Àwọn onímọ̀ọ́tótó ní máa n ṣé àwọn iṣẹ́ wọ̀nyìí.
Àwọn iṣẹ́ ìmọ-ẹ̀rọ ìtanná :
- ìṣé àwòrán ẹ̀rọ ìtanná
- ìrọ káàdì ẹ̀rọ ìtanná
- Darapọ̀ mọ́ àwọn ẹlẹ́rọ láti ṣe ìfilọ́lẹ̀ tó súwáju àtọwọ́da wọn.
- Wa ọ̀nà ìbájáde ìṣòro, àtunṣe àti àṣeyọrí àwọn ẹ̀rọ
- Ṣé àtunṣe àwọn ẹ̀rọ tàbí ṣe ìpàrọ àwọn ẹ̀yà tó bàjẹ
- Ṣe ìwàdìí ìtẹ̀síwájú àwọn ẹ̀rọ ìtanná tuntun
- Àmójútó àwọn ẹ̀rọ àwọn olùmúló láti ọ̀nà jínjìn
Àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ìtanná máa ń ní ìmọ̀ tó jìnlẹ̀ nínú ẹ̀rọ yìí, wọ́n máa tọpinpin àwọn ìmọ̀-ẹ̀rọ tuntun ìgbàlódé, o máa ní àwọn ìmọ̀ nínú àwọn ẹ̀rọ mìí, bíi ( ìmọ̀-ẹ̀rọ ìṣiṣẹ́, ìmọ̀-atẹ́gun…) á tun mọ́ orúkọàwọn irinṣẹ́ sí èdè gẹ́ẹ̀sì.
Pẹ̀lú èmí ìdíje gbòde lẹ́nu iṣẹ́, àwọn onímọ̀ ìtanná máa ń wa ìmọ̀ nínú ẹ̀rọ kọ́ńpútà, àti ìmọ̀-ẹ̀rọ ìtanná tín-tìn-tín. Àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ tún máa nímọ̀ ìbániṣiṣẹ́pọ̀ pẹ́lú àwọn oníbàárà.