Ẹ káàbọ̀

Initiation and improvement courses in Yorùbá language
with new technology tools from Omoluwabi University

Information and Registration…

Èdè
Èdè ẹ̀kó wa ni yorùbá, pẹ̀lú àwọn àṣàyàn nínú Faransé àti gẹ́ẹ̀sì. Èdè abínibí jẹ́ èdè tó tọ pẹ̀lú tó yẹ fi kọ́ àwọn ọmọ wa lẹ́kọ́. Ìmọ̀ tótó èdè yorùbá ( kíkọ́, kíkà àti sísọ́ ) pẹ̀lú èdè Faransé àti gẹ́ẹ̀sì ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa ti kọ́ sẹ́yìn máa jẹ́ kí  wọ́n ní àǹfààní láti tètè ríṣẹ́.

Ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìṣirò àkànṣe ( Αpplied mathematics )
Ẹ̀kọ́ Ìṣirò jẹ́ ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì fún àwọn ẹ̀kọ́ gbogbo tó kù. Ìgbìyànju YUNIFÁSÍTÌ wa ni kí àwọn akẹ́kọ́ wa ní ìmọ̀ tó múná dóko nínú ìṣirò láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn péye.

Àwọn àkọọ́lẹ̀ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Ìṣirò àkànṣe ( Αpplied mathematics )

Ìmọ̀ ìṣàkóso àti ìṣòwò ( Economic sáyẹ́nsì )
Pẹ̀lú ìmọ̀ nínú ẹ̀kọ́ ìṣàkóso, ìṣòwò…,àwọn akẹ́kọ́ wa máa ń ṣisẹ́ nínú àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba tàbí ti àdání. Àwọn isẹ́ tí àwọn akẹ́kọ́ máa dáwọlé ni, iṣẹ́ ọga ilé-iṣẹ́ ìṣiró, ìṣòwò tàbí ọga ilé-iṣẹ́ pátápátá. àwọn ìwé-ẹ̀rí ìpele ìwé marùn ún ni máa ń gbé wọn dé àwọn ipò wọ̀nyìí.

Ìmọ̀-ẹ̀rọ Kọ́ńpútà ( computer technology )
Ayára bíi àṣá ( Kọ́ńpútà ) jẹ́ irínsẹ́, ìfigagbága, ìlọ́síwájú, ìfipamọ́ àwọn ọ̀rọ̀, àti tí  àwọn ètò ìṣàkóso. Ó rọrùn púpọ̀ fún àwọn akẹ́kọ́ ayára bíi àṣá láti rísẹ́ lónìí. Àwọn ìmọ̀-ẹ̀rọ kọ́ńpútà àti ti ìbáraẹnisọ̀rọ̀ máa ń fún wọn ni àǹfàánì láti tètè ríṣẹ́. Áfíríkà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ kù láti ṣe.

Àwọn àkọọ́lẹ̀ ẹ̀kọ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ Kọ́ńpútà ( computer technology )

 

Ìmọ̀-ẹ̀rọ-ìtanná ( Electronic thechnology )
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ìmọ̀-ẹ̀rọ-ìtanná máa ń riṣẹ́ nínú àwọn ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ rédíò dé ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfúrufú ogun. Elẹ́rọ ìtanná máa  ń fẹ́ran láti fọ́wọ́ sínú àwọn okùn iná. Àwọn ẹlẹ́rọ ìtanná máa ń  ríṣẹ́ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ nítorí wí pé iṣẹ́ ìtanná wà níbi gbogbo. àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa máa tètè ríṣẹ́ tí wọ́n bá pari ìkọ́ṣẹ́ nínú àwọn iléṣẹ́ ẹ̀rọ kọ́ńpútà ìgbàlódé tí wọ́n ń lò nínú mọ́tò, ọkọ̀ òfurufú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ…

Àwọn àkọọ́lẹ̀ ẹ̀kọ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ-ìtanná ( Electronic technology )

 

Ìmọ̀-ẹ̀rọ-iná ( Electric technology )
Inú àwọn ilé-iṣẹ́ gbogbo ni iná wà, àti níbi gbogbo ní ayé wa. Àwọn ẹ̀kọ́ wa nínú ìmọ̀-iná ni á fún àwọn akẹ́kọ́ wa ni àǹfààní láti mọ̀ ìjìnlẹ̀ àwọn iṣẹ́ wọ̀nyìí. Àwọn ẹ̀yà iṣẹ́ iná ti àwọn akẹ́kọ́ lè ṣe ni wọ̀nyìí :

 

Ìfa okùn iná

Ìfa iná sínú àwon ilé àti àwon ilé-iṣẹ́

Àmójútó àwọn ẹ̀rọ iná                                            
Ìṣàkóso àwọn òṣìṣẹ́ iná

ìṣàkóso àwọn iṣẹ́ iná

Ọga ilé-iṣẹ́.

Àwọn àkọọ́lẹ̀ ẹ̀kọ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ-iná ( Electric technology )

 

Ìmọ̀-ẹ̀rọ-ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ( Telecommunication technology )
Nígbà ti àwọn akẹ́kọ́ wa bá pari ẹ̀kọ́ wọn, inú àwọn ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ti ìjọba tàbí ti àdání  ni wọ́n a máa  rísẹ́ sí í. Àwọn akẹ́kọ́ wa máa ń tún ní àǹfààní láti kẹ́kọ́ fikún fi gbá ìwé-ẹ̀rí ìpele márùn ún. Àwọn isẹ́ ti àwọn akẹ́kọ́ wa máa lè dáwọlé ni àwọn wọ̀nyìí :


Ẹlẹ́rọ ti  ìwádi àti ti ìdàgbàsóke

Ẹlẹ́rọ alákójọ nẹ́tíwọ̀ọ́kì                                          

Ẹlẹ́rọ alákóso iṣẹ́ àgbéṣe ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀

Αlámọ̀ràn nínú ìmọ̀-ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀.

 

Àwọn àkọọ́lẹ̀ ẹ̀kọ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ-ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ( Telecom technology )

 

Ìmọ̀-ẹ̀rọ àti Ìmọ̀-ẹ̀rọ iṣiṣẹ́ ọkọ̀ òfúrufú (aeronautics) 
Àwọn akẹ́kọ́ wa máa ń kọ ọ̀nà tí a máa ń gbà fi rọ ẹ̀ńjínì àti àwọn ẹ̀rọ ìgbékalẹ̀ òkè. Wọ́n sì tún máa ń kọ àmójútó àwọn ọkọ̀ òfúrufú. lẹ́yìn tí wọ́n bá pari ẹ̀kọ́ wọ́n à á lè ṣiṣẹ́ àwọn iṣẹ́ wọ̀nyìí :

Ìṣàkóso ìṣe àwọn ọkọ̀ òfúrufú

Ìṣàkóso àwọn àkànṣe                                                  

Àmójútó àmúyẹ ìrọ́ ọkọ̀ òfúrufú

Àmójútó àwọn àlàkalẹ̀ ìrọ́ ọkọ̀ òfúrufú

 

Àwọn àkọọ́lẹ̀ ìmọ̀-ẹ̀rọ àti ìmọ̀-ẹ̀rọ ìṣiṣẹ́ ọkọ̀ òfúrufú

 

Ìṣèrànlọ́wọ́ fún ìwádì sáyẹ́ǹsì
tipẹ́tipẹ́ nínú èdè  Yorùbá NÍBÍ