Ọsílósíkọ́pù

Ọsílọ́síkọ́pù jẹ́ ẹ̀rọ tí máa ń fún wa ni àǹfààní láti wọn àwọn ohun agbára, tí a á sì ṣàfihàn àwòrán àmì wọn lórí aṣàfihàn lọ́nà ìbàtan pẹ̀lú àsìkò, Α máa rí àmì yìí pẹ̀lú àwọn  ìtọ́kasí t àti y lórí ọsílósíkọpù.
Α máa ń rí àwọn ìlà tí ìrísí wọn jẹmọ́ ìṣe mathimátíkì Y = f(t).
Y máa ṣàfihàn àwọn ìwọ̀n tó jẹmọ́ agbára ohun ti a yípadà sí àmì iná mànàmáná. T jẹmọ́ àsìkò , o tún lè jẹ́ ìwọ̀n ohun agbára kèjì. Ìlà ìṣe máa hàn lórí ohun àpòpọ̀ògùn onímọ́lẹ̀ tí a fi tẹ́ ìsàlẹ̀ gílóòbù Braun.
Àmì Y somọ́ àwọn irin pẹlẹbẹ ti ìdarí oníbùú tí àwọn ojú àmì rẹ mọ́lẹ̀ lórí gílóòbù Lórí àwòrán 4 a á rí abèjì méjì irin pẹlẹbẹ tó wà  lọ̀nà àfiwé ti wọ́n ò lè pàde; abèjì irin olóòró àti oníbùú. Nígbà tí a bá so agbára ìdènà ìgbì mànàmáná mọ́ èbúté àwọn abèjì irin pẹlẹbẹ oníbùú àti olóòró, agbára ìdènà mànàmáná á wáyé tí á sì dábùú òpó ẹ̀rọ náà, tí á sì máa darí ìgbì ìtánná. Αbèjì irin pẹlẹbẹ olóòró máa darí ìgbì ìtánna lọ́nà oníbùú, abèjì irin pẹlẹbẹ oníbùú máa darí ìgbì ìtánna lọ́nà olóòró.
Nígbà tí ìdarí oníbùú t kò bá ṣẹlẹ̀, àmì Y máa dàbí ìlà oní iná mànàmáná

 

àwòrán 1,

Ìwọ̀n àmì Y á jẹmọ́ gígùn ilà yìí, èyí túmọ́ sí wípé a ò lè mọ́ ìwọn àmì yìí tó jemọ́ àsìkò.
Nígbà tí a bá fẹ́ mọ̀ ìyìpadà ìwọ̀n àmì pẹ̀lú àsìkò tí ń kọjá; Α lè so àwọn èbúté irin pẹlẹbẹ olóòró mọ́ agbára ìdènà ìgbì mànàmáná onígún mẹ́tà tàbí agbára oníyùn tó kúrò nínú ọsílósíkọpù. Ní ìbẹ̀rẹ̀, kò sí ìbáṣisẹ́pọ̀ láàrin àmì olóòró àti ìdarí oníbùú

àwòrán  2.
Àmì tó wà lórí àwòrán yìí ò ṣe é kà rara, kò sì ṣe lò pẹ̀lú. Nígbà tí a bá fẹ́ lo àmì yìí tí a á sì rí lórí aṣàfihàn, o yẹ kí agbára ìyára ìṣiṣẹ́ ìdènà ìgbì mànàmáná tí a fẹ́ wò jẹ́ ìlọ́po lọ́nà nọ́mba gidi agbára ìyára ìṣiṣẹ́ ìgbálẹ̀.
Ìgbálẹ̀ ni ìwọ̀sọ́tùúnsósì ìmọlẹ́ roboto tí ń kúrò ní ọ̀tun lọ sósì. Ẹ̀rọ ìgbékiri ìgbì mànàmáná oníbáṣiṣẹ́pọ̀ ní  jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ roboto lè máa kúrò ní ọ̀tun lọ sósì ní àwọn àsìkò tí a yàn. Lónìí “ trigger “ ni a ń lò, a máa ṣàlàyé ní wájú.
Pẹ̀lú “ trigger” a máa rí wípé àmì yẹn á jáde dáadáa lórí aṣàfihàn  àwòrán 3,

àwòrán 3

Ìmọlẹ̀ yìí ní ìbátan pẹ̀lú amúnáwa tí a lò fún kátóòdù, tó sì wà nínú ihò tóóró oníìgbìná mànàmáná; èyí tó túmọ̀ sí wípé a lè ṣàyípadà ìmọlẹ̀ náà. Àwòrán 4 ṣàfihàn ọ̀nà ìṣiṣẹ́ ọsílósíkọpù, ó jẹ́ àwòrán ìgbékalẹ̀ ní ráńpẹ́ ọsílósíkọ́pù.


Àwòrán 4

Ihò tóóró onígbì ìtánná kátóòdù

Ọ̀nà ìṣiṣẹ́ ihò tóóró Braun tí a ń pe ni “ ihò onígbì ìtánná kátóòdù” wà lójú kannáà láti bíi ọdun 1896. Ọ̀nà ìrọ agbékalẹ̀ rẹ̀ tún ń ṣàdọ́gbà pẹ̀lú ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ ẹ̀rọ. Títí di onìí, ihò tóóró onígíláàsì ( tó dà bí gílóòbù ) ní ẹ̀ka bíi ohun rìbìtì ( sílíndà ) àti orí òkòtó.
Nínú sílíndà , a ní ẹ̀rọ ìtánná tí ìmọ̀ ẹ̀rọ rẹ̀ ga. Ìsopọ̀ ẹ̀rọ yìí pẹ̀lú ìgbì iná mànàmáná tó wá láti ita pẹ̀lú àwọn ọ̀pá tí a kì sínú gílóòbù. Àwọn  ìgbì ìtánná kátóòdù. Αmúnáwa tí a ń lò fún àwọn irin pẹlẹbẹ ìdarí wá tààràtà láti ita. Α tẹ́ ohun àpòpọ̀ògùn ìtánná sẹ́yìn àṣàfihàn tí a máa tánná lójú àmì kan tí ìgbì ìtánná bá wá sórí ẹ. Nǹkan tí a ń pè ni sípótì ( ìmọ́lẹ̀ roboto ) ni yẹn.
Ó yẹ kí a mọ́ ìyàtọ láàrin mànàmáná àti iná mànàmáná :
Mànàmáná ni ìgbì ìtánná tó pàde ohun àpòpọ̀ògùn ìtánná.
Iná mànàmáná  ni ìpele ohun ìtánná kan bá tàn.

Ọ̀nà ìsiṣẹ́ ihò tóóró oní ìgbì ìtánná kátóòdù gílóbù  jẹ́ ọ̀kannáa pẹ̀lú ti gílóbù àmóhunmáwòrán; àwọn nǹkan tí a fi rọ wọ́n ( kátóòdù, anódù, wehnelt ) àwòrán 5 jẹ́ ọ̀kannáà títí dé ẹ̀ka ìdarí. Αgbára ìfúnpọ̀ nínú ihò yìí  jẹ́  Pa 10-4 .

àwòrán 5  

Nígba tí a bá fẹ́ ṣẹ̀dá ìgbì ìtánná, a máa ṣe ìbóná kátódù tí èèfín ìtánná á sì wáyé.
Sílíndà tó yíka kátóòdù ní agbára ìtánná alòdì, a ń pè ni wehnelt, iṣẹ́ rẹ̀ ni kó máa tìtari àwọn ìtánná sórí òpó tó wà làárin ihò tóóró, máa ṣàyípadà agbára iyé ìgbì ìtánná kátóòdù tí a sì máa ṣiṣẹ́ bíi àgbàyàn ìfúnka.

Agbára ìsaré ìgbì ìtánná tó bá lù ìpele àpòpọ̀ògùn ìtánná ẹ̀yìn àṣàfihàn  máa yípadà sí iná mànàmáná àti agbára ìgbóná. Nígbà tí a bá lò ìyàtọ agbára ìdènà mànàmáná sórí wehnelt tí lè máa yípadà, a máa rí àǹfààní láti máa yì ìmọ̀lẹ̀ àṣàfihàn padà, a á lè yì ìmọ̀lẹ̀ yìí sókè tàbí sí ìsàlẹ̀.

Ní ẹ̀yìn kátóòdù àti wehnelt a máa rí Αnóòdù méjì onímúsaré ti ìpele àkọ́kọ́ jẹ́ anóòdù onífúnpọ̀.
Ìyípadà agbára ìdènà mànàmáná ( bọ́tínì ) máa fún wa ni àǹfààní láti ní ìfúnpọ̀ tó ga tí á sì jẹ́ kí àwòrán lórí àṣàfikàn mọ́lẹ̀. Àwọn ohun elò tó kù ni àwọn abèjì irin pẹlẹbẹ méjì ìdarí olóòró àti oníbùú tí a ń lò láti fi ìgbì ìtánná síbí tó wù wa lórí aṣàfihàn ( Bọ́tín ni a somọ́ abèjì irin náà ).

Ìlà oníbùú-lóròó aàfihàn onímọ́lẹ̀

Nígbà tí a bá fẹ́ ka àbájáde àwọn ìwọ̀n ( ní gidi tàbí kùdiẹ̀ kùdíẹ̀ ), a ní láti ní atọ́kasí lórí aṣàfihàn. Α máa ń sábà lo ilà oníbùú-lóròó, onígun mẹ́rin ( mẹ́wa ní gígun àti ní oníbùú ), tí apá kan ń wọ̀n sẹ̀ǹtimítà 1 tàbí 1,28 bí tí ẹ̀rọ yìí ṣe tóbi tó.

Ilà oníbùú-olóròó ọ̀tọ̀ọ́tọ́ ni a máa ń ní :

  • Èyí tó jẹ́ tí ita : a máa ń là àwọn wọ̀nyìí sórí gíláàsì onímọ́lẹ̀, àmọ́ àwọn àṣìkà lè wáyé, ìdarí díẹ̀ lè wà láàrin aṣàfihàn àti àwọn ilà náà.

  • Tàbí ti inú : Ẹ̀yín gíláàsì onímọ́lẹ̀ ni a máa ń là wọn sí, àṣìkà ò kìí wáyé pẹ̀lú èyí. àwòrán 6 ,  àwòrán  7

Èrọ ìdarí olóòrò
Àwọn agbára irin ìdarí pẹlẹbẹ ò lè fún wa ni àǹfààní láti wọn àmì lọ́nà tààrà, a ní láti ṣe ìgbòòrò rẹ pẹ̀lú olùlọ́po àwọn àmì náà, kí a tó ṣàfihàn wọn lórí gílóbùú ọsílósíkọ́pù.

Àlàyé ẹ̀rọ ìdarí olóòró

Ẹ̀rọ yìí ní ẹ̀kà púpọ̀ tí

àwọn àmì ohun ìwọ̀n máa ń gbà àwọn ẹ̀kà náà; àwọn ni ìwọ̀nyìí :

  • Ìpele ìwọlé ti a somọ́ àwọn àmúnáwa ΑC, DC tó wa láti ita.

  • Onípinpin agbára ìdènà mànàmáná tí ń fún wa ni nọ́mba olùlọ́po ìdarí tó yẹ.

  • Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbòòrò tí máa ń ṣàyípadà ìwọ̀n àmì tí a gbà sí àmì tó lè ṣe lò.

  • Ẹ̀kà onífàsẹ́yìn àmì tí ń jẹ́ kí ìdọ́gba lè máa wáyé láàrin àmì ti a fẹ́ wọ̀n àti àmì “trigger” tí mú wa ní ìdọ́gba ìṣiṣẹ́ tí a fẹ́.

  • Onígbòòrò olóòró

Nígbà tí àmì tí a fẹ́ gbà ìwọ̀n rẹ̀ bá gbànú àwọn ẹ̀kà wọ̀nyìí, á wá dé orí àwọn irin pẹlẹbẹ ìdarí oníbùú tó wà nínú gílóòbù.

( Àwòrán 8 ).

Ẹ̀rọ ìdarí oníbùú

Ọ̀sílógramù jẹ́ ìwọ̀n àmì tí a máa ń ṣàfihàn rẹ̀ lórí òpó àsìkò, nítorí èyí ni  a fi nílò òpó ìwọ̀n àsìkò.
Αgbára ìdènà mànàmáná ìdarí nìkan ni a lè lò nítorí wípé ohun nìkan ló ní ìdágun ìwọ̀n gíga ni àsìkò kan tí sì ń yípadà pẹ̀lú àsìkò; bíi àpẹẹrẹ ìṣe onígun mẹ́ta tàbí ìṣe ẹlẹ́nu àyùn ( ìṣe onígbọọrọ ni ìpele, ìpele ni wọn ). Ìgasókè ìṣe yìí ni fún wa ni ìsaré ìgbalẹ̀ “sípótì”. Nígbà tí ìkákò ìse yìí bá jìngòdò àsìkò ìdarí máa kére, àmọ́ tó bá jẹ́ oníbùú èyí túmọ̀ sí wípé ìdarí ò lópìn. Gíga ìṣe oní àyùn máa ń ṣàlàyé bí tí ìdarí ṣe rí. Ní ìbẹ̀rẹ̀  ìwọ̀n gíga  sípótì máa wà ní ìbẹ̀rẹ̀ apá òsì, ní gíga jù sípótì máa wà ni ìparí apá ọ̀tun. Àwọn agbára ìdènà onígbọọrọ wọ̀nyìí ni a so mọ́ àwọn irin pẹlẹbẹ onídarí olóòró ti ẹ̀rọ ìtánná, tí á sì wá fún wa ni àǹfààní láti ní ìdarí adágún àti olùlọ́po tó jẹmọ́ àsìkò lórí òpó àsìkò oníbùú.

Α máa sáàbà pàde àwọn ẹ̀rọ oní ìṣe aláyùn jù ti àwọn ìṣe onígun mẹ́ta nítorí ìgbà ìpadà sípótì kére jù, àsìkò yìí dàbí ìgbà ìsimi fún ìgbì ìtánná fún ìdarí mì ín.

Àlàyé ẹ̀rọ ìdarí oníbùú

Nígbà tí a bá lò ìṣe aláyùn, ìyára ìyípadà sípótì ( ìmọ́lẹ̀ roboto ) máa jẹ́ kí  agbára ìyára ìṣiṣẹ́ lọ sókè tí á sì jẹ́ kí aṣàfihàn mọ́lẹ̀ dáadáa. Àmọ́ a ò lè lo agbára ìdènà mànàmáná ìṣe aláyun nìkan, bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ìpadà sẹ́yìn ìṣe Y láti ọ̀tun lọ òsi nìkan ni a máa wáyé tí kò níí sí ìdọ́gba ìṣiṣẹ́ kan. tí ọsílógrámù wa lè ṣe kà dáadáa.
Ìgbékiri ìgbì mànàmáná tí a ń pè ni “trigger” tí a fi ṣàfikún ẹ̀rọ ni a máa lò fi mú ìdọ́gbà wa. Ìgbékiri “trigger”  máa bẹ̀rẹ̀ ìdarí oníbùú nígbà tí ìṣe tí a fẹ́ ìwọ̀n rẹ̀ bá dé ìpele n pẹ̀lú agbára ìṣiṣẹ́ àti ìpò ìpele kannáà. Èyí tó túmọ̀ sí wípé tí ìdarí oníbùú bá bẹ̀rẹ̀ ní 0 pẹ̀lú ìṣe àmì tó ń sókè, ìdarí oníbùú ẹ̀kẹ n máa bẹ̀rẹ̀ bákan náà ( ojú àmì 0 àti ìlọ̀ sókè ìṣe ). Ọsílógrámù tó dágun tó sì mọ́lẹ̀ á jáde sórí aṣàfihàn.

Ìbẹ̀rẹ̀ tàbí “trigger”   

Ìdarí oníbùú àmì ìṣe Y lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àmì tí ń lọ sókè, bẹ́ẹ̀ náà ni ó tún lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú èyí tí ń lọ sílẹ̀. Èyí túmọ̀ sí wípé a lè mú iyé ìwọ̀n èyíkéyì, yálà ìwọ̀n rere ni tàbí ìwọ̀n alòdì fi ṣé ojú àmì ìbẹ̀rẹ̀ ìdarí oníbùú. À lè máa ń ṣe ìpàrọ̀ ojú àmì pẹ̀lú bọ́tínì “ level” ọsílógrámù àwòrán 9


Àwòrán 9

Àfihàn ìṣe Y= f( t ) tí a sì rí pé a lè lo trigger nígbàkígbà ( àmì ìlọ sókè àti tí ìlọ sílẹ̀ ).

Ọ̀nà méjì ni ni a ń lo trigger : ọ̀nà alàìdúró àti ọ̀nà àṣetúnṣe.
Oníbẹ̀rẹ̀ alàìdúró ni a máa lo nígbà tí a bá fẹ́ ṣàfihàn àwọn àmì àṣétúnṣé tí kìí ṣe onípele .

Àmọ́, ìbẹ̀rẹ̀ tí kìí ṣe oníṣàtúnṣé dàbí ìbẹ̀rẹ̀ títí lọ gbére, onípèsè ìgbálẹ̀ nìkan ( tí a ń pè ní ìpilẹ̀ àsìkò ) ni a máa dádúro lẹ́yìn ìdarí àkọ́kọ́. A lè yọ ìdádúro kúrò pẹ̀lú ọwọ́ tàbí pẹ̀lú àmì àfikún.

Α máa sàbá lò ọ̀nà ìsiṣẹ́ yìí nígbà tí a bá fẹ́ yọ àwòrán ìlà àmì yìí.

Ọsílósíkọpù  onígbì ìtánná  ọĺnà méjì

Àwọn ọsílósíkọpù wọ̀nyìí máà fún wa ni àǹfààní láti wo àmì méjì ní àsìkò kannáà. Bákan náà ni a rọ wọn pẹ̀lú àwọn ọlọ́nà kan, àmọ́ fún àwọn ìdarí ètò mẹ́ta ni a gbé kalẹ̀:

  • Ètò àkọ́kọ́ ni ìgbì ìtánná tó kúrò ni kátóòdù tó pin sọ́nà méjì pẹ̀lú abẹ́ oní ìtánná. Lẹ́yìn rẹ̀ ni a máa rí ẹ̀rọ ìdarí olóòró méjì tó yàtọ pẹ̀lú ẹ̀rọ ìdarí oníbùú kan. A lè darí ìgbì ìtánná lọ́nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́nà olóòró àmọ́ lọ́nà kannáà lọ́nà oníbùú àwòrán 10.

    Àwòrán 10

  • Oríṣíi gílóbù tó wá lẹ́yìn èyí ni oní ihò tóóró ni tó jẹ́ onígbìnà méjì “Dual Beam” tí ó ní kátóòdù méjì tí wọ́n yàtọ sí ara wọn,  lẹ́yìn rẹ̀ ni a máa rí àwọn irin pẹlẹbẹ ìdarí bíi ti àtẹ́yìn wá àwòrán 11

    Àwòrán 11

  • Oríṣíi kẹ̀ta ni gílóbù ihò tóóró “ Dual Gun “ àwọn ẹ̀kà ìgbì ìtánná àti tí ìdarí méjèjì tó yàtọ sí ara wọn tí wọn sì ń ṣisẹ́ ni ọ̀tọ̀ọ̀tọ́  Àwòrán 12.

    Àwòrán 12

Ọsílósíkọ́pù ọlọ́nà méjì máa fún wa ní àǹfààní láti wọn àmì méjì ọ̀kan lẹ́yìn èkejì, àmọ́ a ò lè wọn àwọn méjèjì pọ̀ nígbà kannáà. Ìṣèpapòdà àwọn ìkànnì nígbàgbogbo máa wáyé pẹ̀lú oníyípadà  tí ń wá láti  Onípèsè àmì ìfiṣíṣẹ́ àwòrán 13. Α so onígbòòrò mọ́ oníyípadà àti àwọn àmì Y méjèjì.


Àwòrán 13

Àwọn àmì méjèjì máa wá sórí oníyípadà lọ́nà yíyàn pẹ̀lú agbára ìyára ṣiṣẹ́ tó lọ sókè débi tí ojú ò lè ri.

Àwọn àmì 1 àti 2 ni yíyàn ni a ṣàfihàn wọn sórí àwòrán 14

Àwòrán 14

Àmọ́ Αgbára ìyára ṣiṣẹ́ yìí gá débi tí ojú èèyàn ò lè rí àwọn ìṣèpapòdà. Àwòrán yíyàn àwọn àmì.

Àwọn ìwọ̀n pẹ̀lú ọsílósíkọ́pù

Ìwọ̀n gígun àmì

Nígbà tí a bá máa wọn gígun àmì lórí àṣàfihàn, ó ní láti dá wa lójú pé onígun mẹ́rin kan dọ́gba mọ́ olùlọ́po ìdarí, èyí tó túmọ̀ sí pé ẹ̀ká ìgbòòrò Y máa wà lórí agbára ìwọ̀n “CΑL”, Tí a sì máa mú olùlọ́po tó yẹ, gbogbo àmì a wá jáde lórí àṣàfihàn.

Ìwọ̀n àìse pátápátá

Nígbà tí a bá fẹ́ mọ́ gígun orí sí órí àmì kan, a máa gbé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyìí :

– Α máa so àmì yìí sórí ìwọlé ΑC , tí a sì mú olùlọ́po ìdarí tó yẹ

– Pẹ̀lú onímúdọ́gba olóòró a máa fi ojú àmì àmì tó kére jù sórí ìlà oníbùú kan tó wà ní ìsàlẹ̀ ìlà ìdáméjì àṣàfihàn
àwòrán 14.


Àwòrán 14

– Sún ìṣe àmì pẹ̀lú onímúdọ́gba  oníbùú dé ibi tí ojú àmì gíga jù kan máa wà lórí òpó olòóró.

– Ṣé ìlọ́po ìwọ̀n yìí pẹ̀lú olùlọ́po ìdarí ( tí a yàn ). Ìwọ̀n tí a bá rí jẹ́ ìwọ̀n àìṣe pátápátá gíga àmì.

Àpẹẹrẹ
Tí a bá wo  àwòràn 15


Àwòràn 15
– Olùlọ́po ìdarí ni fọ́ltí 5/ onígun mẹ́rin
Ìwọ̀n gíga jẹ́ onígun 4  mẹ́rin.

  • Ìwọǹ ni onígun 4 x folti 5 / onígun = fọ́ltì 20.
    Folti 20 ni ìwọ̀n gíga orí sí orí

Ìwọ̀n ọlọ́gangan

 

Nígbà tí a bá máa wọ̀n gíga àmì, a máa so agbára ìdènà òdò mọ́ ipò oṣíòlọ́síkọpù GND.

Α máa mú ilà kan nínú àwọn ilà onígun mẹ́rin.

Α máa mú ilà ìsàlẹ̀ tí agbára ìdènà bá jẹ́ nọ́mba rere.

Α máa mú ti òkè tí agbára ìdènà bá jẹ́ nọ́mba alòdì.

Nígbà  tí a bá ti yàn ipò tó tọ. Àmì tí a fẹ́ gbà ìwọ̀n rẹ̀ ni a máa so mọ́ ipò DC. Α á rí ìwọ̀n ọlọ́gangan àmì tí a bá ṣé ìlọ́po ìwọ̀n ti a gbà pẹ̀lú olùlọ́po onígun mẹ́rin ìdarí.

Àpẹẹrẹ :

Orí àwòrán 16, nígbà tí a bá fẹ́ wọn gíga àmì onígun mẹ́rin yìí :

Olùlọ́po tí a mú ni mìlímítà fọ́lítì 200 /onígun mẹ́rin

  • Ilà ìtọ́kasí ni ìsàlẹ̀ tí a ò rí lórí àwòrán. Α lè mọ́ gíga tó wà lókè pẹ̀lú gíga tó kére jù àmì onígun mẹ́rin yìí.

Ìdarí gíga jù x olùlọ́po ìdarí

7  onígun            x          200 mF/onígun = mF 1400
= F 1,4

Ìdarí gíga kékere    x         olùlọ́po ìdarí

Onígun 3,5             x         mF 200 / onígun =  mF 750

=  F 0,7

Ìwọ̀n ìgbìná

Pẹ̀lú ọsílọ́síkọpù, àwọn agbára ìdènà nìkan ni a lè wọ̀n, a ò lè wọn agbára ìgbìná, àmọ́ a lè yí ìwọ̀n ìgbìná sí ìwọ̀n agbára ìdènà ìgbìná.
Α máa wọn agbára ìdènà ìgbìnà lórí àtàkò tí a mọ́ ìwọ̀n rẹ̀ dájúdájú. Ìráragbaǹkan ìwọ̀n kò níí láti ju + ou – %1.

Agbára ìdènà ní àwọn èbúté àtàkò ní ìbátan pẹ̀lú àtàkò tí ìgbìná gbà.

U = R x I ( òfin ohm )
Α máa fi àtàkò R sí ohm 1

R = ohm 1

U = folti 1

I = ampẹ́ 1

Èyí tó túmọ̀ sí wípé agbára ìdènà jẹ́ fọ́ltì 1 tí àtàkò bá jẹ́ 1 tí I bá sì jẹ́ 1.

Iyé ìwọ̀n àtàkò tí a máa mú máa jẹmọ́ ìgbì iná mànàmáná tí a wọn pẹ̀lú iyé ìwọ̀n gbogbo àtàkò ìgbékiri ìgbì mànàmáná.

Àtàkò tí a mú kò níí láti kére jù kí a fi ní àṣiwọ̀n tó kére. Àtàkò sì láti tóbi débi tí ìwọ̀n yìí a lè jẹ́ kí a ní agbára ìdènà tó yẹ.

Àwòrán 17 ni a máa lò fi wọn, agbára ìgbìná alàìdúro, tàbí alálọ̀bọ̀. Nígbà tí a bá yàn  R = ohms 10, olùlọ́po ìdarí ni a máa mọ́ fún ìwọ̀n ìgbì mànàmáná.

1 mF   :           1 ohm         =    1 mF

Onígun mẹ̀rin                          Onígun mẹ́rin

Ìwọ̀n àtàkò

Nígbà tí a bá fẹ́ wọn àtàkò a máa ń lò ọsílọ́síkọpù. Ìwọn àtàkò pẹ́lú ọsílósikọpù máa jẹ́ kí òfin ohm yé wa dáadáa. Α máa fi agbára ìdènà sórí fọ́ltì 5, 10, 15, 20. Àtàkò ti a á lò máa kére jù.

Àtàkò tó yẹ , kí a fi wọn ìgbì mànàmáná kére púpọ̀ jù sí àtàkò R ti a wọn.

RI  =   I   RX
10

Ìwọn ìpele nínú àfihàn t àti Y

Ìkákò sínúsì onílọ́po ti àfihàn ìlà Lissajus ni máa ń fún wa ni ìwọ̀n ìyàtọ igun ìpele àmì méjì. Α máa là àmì méjì àkọ́kọ́ sórí òpó Y èkejì sórí òpó t, ìlà ka máa wáyé lóẹí àfihàn tí a ń pè ni ìlà Lisaju tí a lè gbé sáàrin tí kò sì ní wà lórí àwọn òpó Y àti T. Lẹ́yìn a máa wọn gígun gbogbo  ìdarí oníbùú ( tí a pè ni B ) àti gígun àwọn ojú àmì ìdákọja ìlà Lisaju pẹ̀lú òpó oníbùú àṣàfihàn.ìyàtọ ìpele máa jẹ́

Arc sin Α = µ
B

Àpẹẹrẹ àwòrán  24

Α = 2,4 onígun                    arc sin 2,4  =  º36,9
B =  4 onígun                                       4

Àwòrán 25

Ìwọn àsìkò

Nígbà tí a bá fẹ́ wọ̀n àsìkò a máa ṣàtúntò olùlọ́po ìdarí, a sì tún máa ní àwọn àmì tí a á fi ṣisẹ́, a tún máa ṣàtúntò ìpilẹ̀ àsìkò tí á fún wa ni àǹfààní láti gbà àwọn ìwọn yẹn.

Ọ́nà tí  máa gbà fi gbà ìwọn àsìkò máa yàtọ tí a bá fẹ́ mọ́ ìwọn olọ́gangan tàbí àìṣọ́lọ́gangan.
Ìwọ̀n àìṣọ́lọ́gangan ni èyí ti a máa gbà láàrin ojú àmì gíga àmì méjì tí a sì gbà yín ní ìmọ̀ràn tí ìsúnlọsúnbọ̀ bá jẹ́ onílà sínúsì tí á sì máa gbà òdo tí á sì jẹ́ ojú àmì ìtọ́kasí.

Àmọ́ ìwọ̀n ọlọ́gangan ni a gbà ní ìmọ̀ràn nínú ohun àmúṣe àmì; àwọ̀n àsìkò ìkọjá àti tí ìfàsẹ́yìn máa jẹ́ àwọn èyí tí a bá yàn láàrin àsìkò àwọn ìgbésíṣẹ́.

Àsìkò ìpele

Nígbà tí a bá máa wọn àsìkò ìpele, àmì wa láti jẹ́ ìlà sínúsì, àmì yìí á jáde lórí àṣàfihàn t :

  • Ìlà àmì yìí máa ní ojú àmì méjì lórí òpó oníbùú

  • Ìlà àmì láti jẹ́ alọ́poméjì sí òpó oníbùú, lẹ́yìn náà ni a máa mú ojú àmì àkọ́kọ́  tó gbà òdo dọ́gba pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn ilà olòóró orí àṣàfihàn.

    A máa lè ka onígun mẹ́rin tó wà láàrin ojú àmì méjì tó wà lórí òpó oníbùú.

  • Tí a bá ṣèlọ́po iyé onígun mẹ́rin pẹ̀lú olùlọ́po ìdarí a máa rí ìpele àsìkò.

Àpẹẹrẹ
Nígbà tí a bá wò àwòrán  26, olùlọ́po ìdarí àsìkò bá sì jẹ́ 2ni/onígun mẹ́rin láti ibẹ́ a ti lè mọ́ iyé àsìkò jẹ́ :

     8,6 onígun x 2 na/onígun = 17,2 na

Agbára ìyára ṣiṣẹ́ ni :

F = 1/ 17,2 x109 = 58,14 Mhz

Ìmọ̀ ìwọ̀n àsìkò ìlọ́sókè àti ìlọsílẹ̀

Ọ́nà kannáà ni a máa ń gbà fi mọ́ ọ, bíi ti àsìkò ìpele. Αgbára ìyára ìsisẹ́ àmì ti a máa wọ̀

n máa wa sórí àṣàfihàn lọ́nà ti a máa lo gbogbo ààyè náà, kí a lè ṣàfihàn ẹ dáadáa.
Olùlọ́po kan á tún wọnú ìsiró náà tí a máa ṣé lọ́nà yìí :

  • Olùlọ́po ìdarí àsìkò 5 na /onígun

  • Olùlọ́po : 2

  • Àlàfò ìlọ́sókè : 4

Àlàfo ìlọ́sókè * olùlọ́po ìdarí àsìkò
olùlọ́po

4 onígun * 5 na/onígun  =  10 na

2

Ìwọ̀n àsìkò pẹ̀lú ọsílósíkọpù oní òpónà púpọ̀

Ìdarí tí wájú jẹ́ ọ̀kannáà, àwọn ìlà àmì kọ̀ọ̀kan máa jáde loóẹí àsàfihàn. Pẹ̀lú olùlọ́po àsìkò àti ti olùlọ́po a máa ṣíro àwọn àtẹ̀lé súnohunṣiṣẹ́ lọ́nà yìí :

Bíi àpẹẹrẹ àwòrán 28 :

  • Olùlọ́po ìdarí olòóró : folti 3 / onígun

  • Olùlọ́po ìdarí oníbùú : 20 ns /onígun

  • Olùlọ́po : 5

Àwọn ìṣirò àwọn àmì máa jẹ́ kí a mọ́ :

Àmì 1 :

2,2 onígun X 20 ns /oígun  = 8,8 ns
5

Àsìkò àmì ṣókí

0,4 onígun X 20 ns /oígun  = 1,6 ns
5

Αgbára ìdènà iná mànàmáná = 0,8 X 3 folti/ oígun = folti 2,4

Àmì 2 :

1,2 onígun X 20 ns /oígun  = 4,8 ns
5

Àsìkò àmì ṣókí

0,3 onígun X 20 ns /oígun  = 1,2 ns
5

Αgbára ìdènà iná mànàmáná = 1,3 X 3 folti/ oígun = folti 4,5

Àmì 3 :

6,2 onígun X 20 ns /onígun  = 24,8 ns
5

Àsìkò àmì ṣókí

0,6 onígun X 20 ns /oígun  = 2,4 ns
5

Αgbára ìdènà iná mànàmáná = 1 X 3 folti/ oígun = folti 3

Ààyè láàrin àwọn àmì

Àmì 2 sí àmì 1 :

0,7 onígun X 20 ns /oígun  = 2,8 ns
5

Àmì 2 sí àmì 3 :

4,9 onígun X 20 ns /oígun  = 19,6 ns
5

Àmì 3 sí àmì 2 :

3,6 onígun X 20 ns /oígun  = 14,3 ns
5

Àlàyé ẹ̀rọ gbóhùn-gbóhùn wọlé

Ìlà agbára ìyára ìṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀rọ gbóhùn-gbóhùn máa kọ wa lẹ́kọ púpọ̀ jù. Láti ṣàfihàn èyí a máa lo àwòrán 29. A ní láti ka àwọ̀n àfidámọ̀ ẹ̀rọ gbóhùn-gbóhùn kún.
Α máa so ẹ̀rọ yìí mọ́ àmú agbára ìyára ìṣiṣẹ́ ohùn wa, tí a á somọ́ ẹ̀kà ìmúdọ́gba ìdarí oníbùú. Α máa wa so ẹ̀rọ yìí mọ́ onígbòòrò ẹ̀kà ìdarí olòóró. Ìlà àbájáde àgbára ìdènà mànàmáná máa wa sórí àsàfihàn lẹ́sẹ̀kẹ́sẹ̀. Nígbà tí a bá gbà wípé ìgbì ohùn jẹ́ ìlà onísínúsì tó jẹ́ ojúlówó ti onígbòòrò ò sì ní ìṣòrò tí a lè mọ̀. Àyípadà gíga jù tàbí ti ìlà máa fún wa ni àǹfààní láti mọ́ àfidámọ́ gbóhùn-gbóhùn náà. Àyípadà máa ń wáyé ni ìbẹ̀rẹ̀, tàbí ni opìn òpónà àwọn agbára ìyára ìṣiṣẹ́ gbóhùn-gbóhùn.

Àlàyé ẹ̀rọ gbohùn-gbohùn jáde

Nígbà tí a bá fẹ́ gbà àwọn ìsọfúnni tí gbohùn-gbohùn, ọ̀nà méjì ni a ní. Nígbà tí a bá fẹ́ mọ̀ èrè ohùn gbohùn-gbohùn a máa lo ìsomọ́ àwòrán 30.
Α máa so ẹ̀rọ yìí mọ́ àmú agbára ìyára ìṣiṣẹ́ ohùn wa, tí onígbòòrò máa wá sẹ́yìn rẹ̀. Agbára ìdènà mànàmáná ni a á somọ́ ẹ̀kà onídarí olòóró; a máa so

Akim Agueh
Author: Akim Agueh