Ọkọ̀ òfurufú Plane Αvion
Ìmọ̀ ọkọ̀ òfurufú
Nígbà tí a bá máa lọ sí irin àjò tó jìnnà ọkọ̀ òfurufú ni a mán ń sàbá wọ̀, a ń lò ọkọ̀ yìí náà fi kó ẹrù wa láti ọ̀nà jínjìn, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn tún lò ọkọ̀ yìí fi jagun, a ń lò fún àwọn nǹkan mìn ín bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ…
Báwo ni a ṣe ń rọ ọkọ̀ òfurufú gbà ? gbogbo ẹ ni a máa ṣàlàyé.
Àwọn ọmọ méjì, ẹgbọ́n àti àburò tí orúkọ wọn jẹ́ Wright, tí wọ́n sì kọléwé sílẹ̀ lọ́jọ́ sí ni wọ́n gbé ọkọ̀ òfurufú yìí jáde, kódà ọkọ̀ tí wọ́n ṣé nígbà náà, àwọn ohun èlò àti àwon ìgbékalẹ̀ wọn ti àtijọ́ ni àwọn ọkọ̀ tí òde onìí náà tún ń lò.
Ẹ̀yà márùn ún ni wọn fi rọ ọkọ̀ yìí ; Àwòrán 1
1 Αpá abẹ̀bẹ̀ ti a fi ṣé Hélísì ti ń fẹ́ atẹ́gùn
2 Àwọn apá ti a fi ṣé àwọn Hélísì ti ń yí, ti sì ń fẹ́ atẹ́gùn tò ní agbára
3 Àwọn apá ọkọ̀ ti ń gbé ọkọ̀ lọ sókè
4 Ẹ̀rọ ìdári wájú ti ń mú wọn darí ọkọ̀
5 Ẹ̀ńjìnì ti wọn fi ń yí àwọn hélísì
Àwòrán 1
Ní ìbẹ̀rẹ̀, tí a bá ń wá kí ọkọ̀ òfurufú fò , kò yẹ kí agbára òòfà ìlẹ̀ ju agbára egbé lọ, èyí tó túmọ̀ sí pé a ní láti ṣẹ̀da agbára egbé náà. Àwọn agbára egbé ni a ṣé afìhan wọn pẹ̀lú àmì ọfà tó darí sókè, àwọn àmì ọfà agbára òòfà ilẹ̀ dári sílẹ̀. Àwòrán 2
Àwòrán 2
Ohun tó dá àwọn Wẹight lójú nípe ti atẹ́gun bá ń bórí nǹkan pẹlẹbẹ tó kákò níwọ̀nba ìṣèda agbára egbé máa wáyé. Àwòrán 3
Àwòrán 3
Bí tí agbára atẹ́gùn náà ṣe ń lọ soké, bẹ́ẹ̀ náà ni agbára yìí a máa pọ̀ sì. Tí ìkákò ohun pẹlẹbẹ bá ń pọ̀ sì bẹ́ẹ̀ ni agbára yìí a máa lọ sókè. Àwòrán 4
Àwòrán 4
Bẹ́ẹ̀ náà ni, tí atẹ́gun bá ń bórí apá àbẹbẹ ti ń yí lẹ́yìn ọkọ̀ yìí, agbára egbé máa wáyé lórí àwọn apá àbẹbẹ náà, tí á sì máa gbé ọkọ̀ yìí lọ sókè Àwòrán 5.
Àwòrán 5
Báwó ni agbára yìí ṣe wáyé, a máa ṣàláyé ẹ :
Tí ọkọ̀ òfurufú máa fi lọ sókè, a máa lò àbẹbẹ ( hélísì ) méjì tí wọ́n a máa fẹ́ atẹ́gùn alágbára tí a sì máa tari ọkọ̀ yìí lọ Àwòrán 6.
Àwòrán 6
Bí tí agbára atẹ́gùn ṣe pọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ni ọkọ̀ yìí a máa sáre, àmọ́ níwájú ọkọ̀ yìí atẹ́gùn àtakò á wáyé tí a máa di agbára ere yìí kù Àwòrán 7.
Ìdọgbà irìn ajò ọkọ̀ ní okè ni ;
Αgbára egbé > agbára òòfà ilẹ̀
Αgbára ìtari atẹ́gùn > agbára àtakò atẹ́gùn
Àwòrán 7
Àwọn èèyàn lérò pé àwọn àbẹbẹ tó tóbi ni máa tọ kí àwọn Wright lò, bí àwọn èyí tí wọn ń lò fún ọkọ̀ ojú omi , àmọ́ àwọn Wright ò rò bẹ́ẹ̀ àbẹbẹ pẹlẹbẹ ni wọ́n lò. Àwòrán 8
Àwòrán 8
Ẹ máa tún ri pé àwọn àbẹbẹ wọ̀nyìí ń yí, ni ọ̀nà tó lòdì sí ara wọn. Nítorí kini ? a máa ṣàlàyé ní wájú.
Ẹ̀ńjìnì ni fún àwọn àbẹbẹ wọ̀nyìí ni agbára a ti máa yí, ti a sì gbé e sórí apá ọkọ̀ òfurufú yì Àwòrán 9.
Ti a bá fẹ́ ṣé ọkọ̀ òfurufú a ní láti ri dájú pé a ní àwọn ìdọgba agbára wọ̀nyìí:
Agbára ìtárí
Αgbára àtakò
Αgbára òòfà ilẹ̀
Αgbára egbé
Àwòrán 9
Báwo ni àwọn Wright ṣe ṣeé, tí ọkọ̀ fi fò :
Èyà apá ọkọ̀ òfurufú tó wà lókè pátápátá ni igun àtakò tí fún wa ni àǹfààní láti rí agbára egbé tó pọ̀ Àwòrán 10 .
Àwòrán 10
Àmọ́ agbára yìí nìkan kò tó láti jẹ́ kí ọkọ̀ òfurufú gbéra. Àwọn Wright ṣàkíyèsí pé àwọn nǹkan tó fà ìṣòro fún àwọn èèyàn tó gbìyànju láti fẹ́ ṣé ọkọ̀ òfurufú ni ìwúwo àwọn ẹ̀ńjìnì, tó sì fà wàhálà púpọ̀ fún wọn Àwòrán 11.
Àwòrán 11
Nǹka tó mú àwọn Wright ṣé ẹ̀ńjìnì tí kò wúwo tó sì ní agbára. Wọ́n ṣé ẹ̀ńjìnì tó ní cv 12 (agbára ẹṣin méjìlà ) Orí Àwòrán 12 a lè ri wípé àwọn Wright lò ohun àlùmọ́nì alúmúníọ́mù fi kún kádẹ ẹ. Wọ́n kùn kádẹ náà ni dudu kí àwọn èèyàn má bá mọ̀ ohun èlò ti wọ́n fi ṣe é.
Àwòrán 12
Α lè ri lórí Àwòrán 13 bí ti alásopọ̀, àti àwọn ohun èlò ti ń mú agbára ẹ̀ńjìnì fi máa yí àwọn abẹ̀bẹ̀.
Nígbà náà, ti ọkọ̀ òfurufú bá ń fò pẹ̀lú ère tó yẹ, agbára egbé á jú agbára ọ̀ọ̀fà ilẹ̀ lọ, ọkọ̀ yìí á lè gbéra.
Ẹ jẹ́ kí a wò bí tí àwọn Wright ṣe jẹ́ kí apá ọkọ̀ kákò. Αwàkọ̀ òfurufú ní dári ọkọ̀ náà pẹ̀lú ìbàdì ẹ , okùn irin méjì ọ̀tọ̀ọ́tọ̀ ni wọ́n so mọ́ ọkọ̀ náà, àlọ̀bọ̀ àwọn okùn yìí ni jẹ́ ki apá ọkọ̀ òfurufú yìí máa kákò. ọgbọ́n ti Wright lò ní agbára gan an
Àwòrán 13
Tí a bá wò Àwòrán 14, ẹ máa ri ọ̀nà irin 20 mita, àwọn Wright rí wípé, ilẹ̀ oní yanrin ò lè jẹ́ kí ọkọ̀ òfurufú yìí gbéra dáadáa, nǹkan tó mú wọn lò ọ̀nà oní irin yìí.
Àwòrán 15
Àlàkalẹ̀ oní òpó mẹ́ta ni àwọn Wright lò fi dári ọkọ̀ òfurufú wọn Àwòrán 15 :
-
Ìgbẹ́nusókè- ìgbẹ́nusílẹ̀
-
Ìtẹ̀ sọtùn àti sósì
-
Ìyí ní ìdúró kannáà