Ẹ̀ńjìnì dísù Diesel engine moteur diesel
Ẹ̀rọ àmóhun ṣiṣẹ́ oní ìgbóná abẹ́nu dísù
-
Ẹ̀rọ àmóhun ṣiṣẹ́ oní ìgbóná abẹ́nu máa ń sọ agbára èròjà àpòpọ̀ àtẹ́gùn àti epo dísù di agbára ìṣiṣẹ́ tí a máa yìí àwọn nǹkan.
-
Ẹ̀rọ yìí ní wúlò fún wa lọ́pọ́lọ̀pọ̀ láti bíi ọgọ́run ọdún, tí kò sì wọ́n jù.
-
Αgbára èròjà àpàpọ̀ atẹ́gùn àti dísù, ní ọ̀nà tó péyé ni á padà dí agbára iṣiṣẹ́ tí a máa yí àwọn ẹ̀yà ẹ̀rọ.
-
Epo dísù ni a máa ń fún sínú ìfúnpọ̀ atẹ́gùn alágbara gbígbóná; èròjà àpàpọ̀ àwọn èlò wọ̀nyìí ni máa padà di agbára ìṣiṣẹ́ tí a máa yí àwọn nǹkan bíi àgba ọkọ̀, àti àwọn nǹkan mì ín.
-
Ọ̀nà ìṣiṣẹ́ ẹ̀ńjìnì yìí ni, kí a máa pèsè ìfúnpọ̀ àtẹ́gùn alágbára gbígbóná gan láìdáwọ́dúró.
Àwòrán 1
Báwo ni a ṣe ń ṣé ?
Àwọn ẹ̀yà ẹ̀rọ yìí ni :
1) Ohun rìbìtì bíi agolo ti a ń pè ni písítíní ( Àwòrán 2 )
Àwòrán 2
2) Αpá alásopọ̀ ( Αlásopọ̀apá ) Àwòrán 3
Àwòrán 3
3) Ohun àfọwọyí ( Αláfọwọ́yí ) Àwòrán 4
Àwòrán 4
4) Ohun rìbìtì bíi agolo tí a pè ni ( sílíndà ) Àwòrán 5
Àwòrán 5
5) Irinṣẹ́ aláfọ́wọ́yí oní ìsúnlọsúnbọ̀.
Irinṣẹ́ aláfọwọ́yí oní ìsúnlọsúnbọ̀
Àwòrán 6
Ìsúnlọsúnbọ̀ písítínì ló di ohun ìyí fún aláfọwọ́yí. Nítorí èyí ni a máa ń fi pè ẹ̀rọ yìí ni ẹ̀ńjìnì aláfọ́wọ́yí oní ìsúnlọsúnbọ̀ ( Àwòrán 7 ).
Ìsúnlọsúnbọ̀ písítínì
Àwòrán 7
Nnú ẹ̀rọ àmóhun ṣiṣẹ́ iná abẹ́nu, a máa gbé irinṣẹ́ yì sínú ẹ̀yà kan tí a ń pè ni ẹ̀kà ẹ́ńjìnì
( Àwòrán 8 ).
.
Ẹ̀kà ẹ̀rọ àmóhun ṣiṣẹ́
Àwòrán 8
Orí sílíndà tí àwọn ẹ̀yà mí ìn jẹ́ abẹ́rẹ́ epo àti àwọn àtọwọ́dá mẹ́rin ni a máa gbé sórí ẹ̀kà ẹ̀ńjìnì yìí ( Àwòrán 9 )
Àwòrán 9
Àwọn ìpele ìṣiṣẹ́ mẹ́rin
Tí písítínì bá lọ sílẹ̀, àwọn àtọwọ́dá ìwọ̀lé atẹ́gùn wọ́n á ṣí, àtẹ́gùn á wọ́lé lọ́pọlọ́pọ̀ tí á tì písítínì yìí lọ sílẹ̀, èyí túmọ́ sí pé ẹ̀ńjìnì yìí á mi wa Àwòrán 10.
Àwòrán 10
Lẹ́yìn náà, àwọn àtọwọdá wọ́n á tì padà, aláfọwọ́yí á tí písítínì lọ sókè tí á sì wà fún atẹ́gùn pọ̀, ìgbóná ẹ á wá lọ sókè, ìwọ̀n ìfúnpọ̀ á lọ sí bar 40, ìgbóná á lọ sí ºC 550 . tó ju ìgbóná tí dísù á lè fi múná lọ ( Àwòrán 11 ).
Àwòrán 11
Nígbà yìí ni a máa wá fún dísù sínú atẹ́gùn tó fún pọ̀, tó sì gbóná.
Dísù tí a fún sínú atẹ́gùn á pòórá tí á sì bùgbàù, níbi tí a ò níí mọ́ ibi tí a máa já sí, nígbá náà ìfúnpọ̀ àti ìgbóná á dé bar 150 àti ºC 2500 ( Àwòrán 12 ).
.
Àwòrán 12
Epo tó gbàgbára ni á tì písítínì lọ sílẹ̀ tí á yí aláfọwọ́yí.
Èyí túmọ́ sí wí pé ìgbóná atẹ́gùn ni á yí padà sí agbára nǹkan tí ń yí, tí á sì wá di ẹ̀rọ. Ìgbà yìí nìkan ni a máa ń lò agbára epo àti àtẹ́gùn ( Àwòrán 13 ).
Àwòrán 13
Àgbàsẹ́yìn agbára á jẹ́ kí písítíní tún lọ sókè, nígbà yìí ni àwọn àtọwọ́dá ìjáde wọ́n a ṣi, tí èéfín á sì wá jáde ( Àwòrán 14 ).
Àwòrán 14
Ìsúnlọsúnbọ̀ oní ìpele mẹ́rin yìí láìdúró ní fún wa ni àǹfààní láti ṣé ẹ̀rọ àmóhun siṣẹ́ dísù.
Αbọ́ kan wà lórí písítínì, nígbà tí písítínì bá ń lọ sókè abọ́ yìí a máa ń fún àtẹ́gùn pẹ̀lú agbára, tí a sí máa jẹ́ kí dísù dàpọ̀ mọ́ àtẹ́gùn dáadáa ( Àwòrán 15 ).
Àwòrán 15
Kò rórùn láti rọ ohun àmóhun ṣiṣẹ́ oní dísù ( epo rọ̀bì ).
Nígbà tí ìbùgbàù epo pẹ̀lú àtẹ́gùn ò ṣé dédé, ẹ̀ńjìnì dísù a máa pariwo, a máa dún a sì tún máa mì lọ́pọlọ́pọ̀ jù ti bẹ́tirọlì lọ. Ẹ̀yí túmọ́ sí wí pé a ní láti ṣàkíyèsí àwọn nǹkan púpọ̀ fi rọ ẹ̀ńjìnì dísù. Nínú àwọn ìpele mẹ́rẹ́rin , ní ìpele ìbùgbàù ni agbára ńlá máa wá sórí písítínì. ẹ̀yí túmọ̀ sí pé ẹ̀ńjìnì oní sílíndà kan máa ń ní
agbára tó lọ sókè, tí kò sí dọ́gba. Àmọ́ tí a bá mú àwọn sílíndà mélòó kan a á lè rí ọ̀nà àbáyọ́ fún ìṣòró yìí ( Àwòrán 15 ).
Àwòrán 15
Tí a bá jíroro sórí ẹ̀ńjìnì oní sílíndà mẹ́rin, a yóò ri pé àwọn ìsúnlọsúnbọ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ nígbá kannáà ( Àwòrán 15 ).
Àwòrán 15
Pẹ̀lú sílíndà mẹ́rin, ìpele ìbùgbàù a máa wà nínú ẹ̀ńjìnì nígbàgbogbo, éyí túmọ̀ sí pé ariwo á díkù, agbára àti agbára ìṣiṣẹ́ wọ́n á dọ́gba. èyí túmọ̀ sí pé bí tí sílíndá bá ṣe pọ̀ sí bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ńjìnì a máa ṣiṣẹ́ bó ṣe tó àti bó ṣe yẹ ní àìpariwo.
Àgbá àtọ́sọ́nà tí ń ṣiṣẹ́ bíi alákòónú agbára ìṣiṣẹ́ máa jẹ́ kí àtúnṣe máa wà níbi díẹ̀ tó kù ká tò ó.
Tí àgbá yìí bá ń ṣiṣẹ́ àìṣedéédé á tún ṣẹlẹ̀ nítorí ìwúwó alásopọ̀apá, a yóò fi òdíwọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀kọ̀ọ́kan wọn. ( Àwòrán 16 ).
Àwòrán 16
Àwọn abràkámù méjì ni máa ń ṣí àwọn àtọwọ́dá, ni máa ń tì wọn, àwọn ni sì tún máa ń tó iṣẹ́ ẹ̀ńjìnì ( Àwòrán 17 )
.
Àwòrán 17
Ìgbànú ìdábòbò ni a ń lọ fi mú ìdábòbò àti ìrọ̀run iṣẹ́ wà fún ẹ̀ńjìnì yìí ( Àwòrán 17 ).
https://www.youtube.com/watch?v=8bdgHNnLTqw
|