Tí a bá wò bí tí àwọn ọkọ̀ ojú irin oní iré gíga ṣe sáré gbà, tí iré yìí sì máa yá ẹni lẹ́nu ; àṣirí tó wà lẹ́yìn ẹ ni, ẹ̀rọ àmóhun ṣiṣẹ́ oní ìgbì iná alàìdúró.
Kìí ṣe inú ọkọ̀ ojú irin nìkan ni a lò ó, ẹ̀rọ amóhun ṣiṣẹ́ (ẹ̀ńjìnì ) yìí náà ni a máa ń lò nínú àwọn ẹ̀rọ ìfọ́ṣọ, ẹ̀rọ ìlọ̀ta, ẹ̀rọ ìgbénisókè, ìgbéhunsókè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ̀rọ yìí náà ni a tún máa ń pè ni ẹ̀rọ amóhun ṣiṣẹ́ oní ìgbì iná DC ( ìgbì iná alàìdúró ).
Báwo ni a ṣe rọ ọ́ gbà ?
Ohun èlò àkọ́kọ́ tí a lò ni onígún mẹ́rin tí a pè ní PQRS a ṣé é pẹ̀lú okun iná ẹdẹ àdádó tí àwọn èyà ẹ mẹ́rẹ́rin sì jẹ́ PQ, RS, PR, QS Àwòrán 1.
Àwòrán 1
Α gbé é sí àárin òòfà méjì, lọ́nà ti onígún mẹ́rin yìí sì pọ̀gbà pẹ̀lú agbára òòfà agbègbè náà Àwòrán 24
Àwòrán 2
Α so àwọn èbúté ẹ méjì mọ́ irin bíi orúka tí a gé sí méjì lọ́gbọgba, àwọn ẹ̀yà méjèjì ni X, Y Àwòrán 3.
Àwòrán 3
Kí wọ́n má bá kan ara wọn, a ti ọpá igi kan bọ́ àárin wọn , a wá so àwọn ìgbalẹ̀ méjì B1, B2 mọ́ àwọn ẹ̀yà orúka X, Y wọ̀nyìí Àwòrán 4.
Àwòrán 4
Lẹ́yìn náà ni a wá so àwọn ìgbalẹ̀ méjèjì mọ́ amúnáwá oní ìgbì iná alàìdáwọ́dúró Àwòrán 5.
Àwòrán 5
Báwó ni gbogbo èyí ṣe ń ṣiṣẹ́ gbà ?
Ìgbì iná tó bá kúrò nínú amúnáwá alàìdúró, á wọlé gbà ìgbálẹ̀ B1, a máa wá gbà inú onígún mẹ́rin PQRS tí á sì wá jáde gbà ìgbálẹ̀ B2 Àwòrán 6.
Àwòrán 6
Tí a bá wò Àwòrán 7, a ó ri pé agbára iṣiṣẹ́ kan ò sí lórí àwọn èyà QR àti PS nítorí wọ́n pọ̀gbà lọ́nà kannáà pẹ̀lú agbára òòfà Àwòrán 2, ti wón ò sì lè pàde ara. Àmọ́ àwọn ẹ̀yà PQ, RS dábùú agbára agbègbè òòfà náà. Orí ẹ̀yà PQ ìgbì iná àti agbára òòfà wọ́n á ṣẹ̀dá agbára ìṣiṣẹ́ tí á sì dárí sílẹ̀, ìṣẹ̀dá agbára ìṣiṣẹ́ á tún wáyé lórí ẹ̀yà RS nítorí ohun náà wà nínú agbára òòfà tí ìgbì iná sì gbà inú ohun náà àmọ́ agbára ìṣiṣẹ́ á dárí sókè Àwòrán 7.
Àwòrán 7
Onígún mẹ́rin yìí yóò wá bẹ̀rẹ̀ sí máa yí ní ọ̀nà alòdì sí ọ̀nà ìyí ọwọ́ aago Àwòrán 8.
Àwòrán 8
Tí onígún mẹ́rin bá yí dé igún ìyí 90º, àwọn ìgbalẹ̀ B1 àti B2 wọ́n á kúro lára àwọn ẹ̀yà orúka wọ̀nyìí, ìgbì iná á dúró láti máa gbà inú ẹ̀yà onígún mẹ̀rin, àwọn ẹ̀yà QP àti RS wọ́n kò níí tún sí lábẹ̀ agbára ìṣiṣẹ́ mọ́, èyí á túmọ̀ sí pé onígun ò níí yí mọ́ Àwòrán 9.
Àwòrán 9
Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀, onígún ò lè dúró lójíjì, yóò tún yí diẹ̀ fikun Àwòrán 10.
Àwòrán 10
Lẹ́yìn ẹ ni àwọn ìgbalẹ̀ wọ̀nyìí, wọ́n á tún so mọ́ àwọn ẹ̀yà orúka, tí ìgbì iná á tún padà wọ inú onígún mẹ̀rin tí yóò tún wá yìí dé igún 180º Àwòrán 11.
Àwòrán 11
Ìdárí ìgbì iná PR àti QS á yí padà, agbára ìṣiṣẹ́ RS á lọ sílẹ̀, ti PQ á lọ sókè, tí onígún mẹ́rin á tún yí dé igún 270º Àwòrán 12.
Àwòrán 12
Ní ipò yìí àwọn ìgbalẹ̀ wọ́n á tún kúrò lára àwọn ẹ̀yà orúka, tí ìgbì iná á tún dúró láti máa wọ inú onígún mẹ́rin bíi ti àtẹ̀yìn wá ìdúró yìí kò lè wáyé lójíjì onígún yì á tún yí díẹ̀ fikun
Àwòrán 13.
Àwòrán 13
tí àwọn ìgbalẹ̀ wọ́n á tún padà so mọ́ àwọn ẹ̀yà orúka, onígún mẹ́rin á tún yìí dé igún 360º tí kò sì níí dúró lójíjì bákannáà, tí onígun á sì máa wá yìí lọ bẹ́ẹ̀ Àwòrán 14.
Àwòrán 14
Ìyára ẹ̀rọ yìí so mọ́ nǹkan púpọ̀ :
Tí àrunpọ̀ bá pọ̀ sì, ìyára a máa lọ sókè sí Àwòrán 15.
Tí agbára iná bá lọ sókè, ìyára á tún máa lọ sókè.
Tí agbára òòfà bá lọ sókè, ìyára yìí á tún máa gbooro.
Àwòrán 15
Àmọ́ tí a bá fẹ́ rọ ògídi ẹ̀rọ àmóhun ṣisẹ́ alágbára , a máa mú àwọn àrunpọ̀ tí a á sì fi wọ́n yí kúró irin ká Àwòrán 16.
Àwòrán 16
Α á wá kó àwọn àrunpọ̀ wọ̀nyìí sí àárin àwọn òòfà méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, a á so àwọn àrunpọ̀ mọ́ agbára iná, tí ìgbì iná bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn nínú àwọn àrunpọ̀ wọ̀nyìí irin kúró á bẹ̀rẹ̀ sí máa yí, tí opá tí a so mọ́ ọ́ pàápàá á bẹ̀rẹ̀ sí máa yí, báyìí agbára iná tí a fún ẹ̀rọ yì á padà dí agbára ìṣiṣẹ́