Ẹ̀rọ àmóhun ṣiṣẹ́ ΑC engine moteur CΑ
Ẹ̀rọ àmóhun ṣiṣẹ́ ( ẹ̀ńjìnì ) oní ìgbì iná alálọ́bọ̀
Àwọn ẹ̀rọ oní ìgbì iná mànàmáná jẹ́ àwọn ẹ̀rọ tó ṣe pàtàkì tí a ò tí gbé jáde rí, Àwọn ẹ̀ńjìnì wọ̀nyìí ni a máa ń lò fi ṣe òpòlọpò iṣẹ́. Α máa ń lò ó fi ṣé fàànù, fi ṣé àwọn ẹ̀rọ agbénigunkè, agbóhungùnkè, ẹ̀rọ ìfami, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Báwo ni ṣe ṣisẹ́ gbà ?
Iṣẹ́ ẹ̀ńjìnì yìí ni kó yí agbára ìgbì iná padà sí agbára ìṣiṣẹ́, tí a fi máa yí àwọn ẹ̀rọ tí a kà ní àtẹ̀yín wá. Inú àpótí kan ni a kó gbogbo nǹkan ti a fi rọ ẹ̀ńjìnì náà sí Àwòrán 1.
Àwòrán 1
-
Ninú àpótí yìí a yóò ri òpó kan tí máa ń yí, ara ẹ ni a máa ń so gbogbo nǹkan tí a fẹ́ lò ó fún. Àwọn nǹkan wọ̀nyìí lè jẹ́ àwọn apá fàànù, ẹ̀rọ tí a fi fami, ẹ̀rọ ìlọ̀ nǹkan, ẹ̀rọ ìgbénigùnkè àti bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ lọ… (Àwòrán 2 )
Àwòrán 2
-
Ní ẹ̀yìn àpótí yìí ni a ó rí fàànù àti ìdérí ìdábòbò ẹ ( Àwòrán 3 ). A so fàànù yìí mọ́ òpó tí mú àwọn ohun yí. Gbogbo ìgbà tí ẹ̀ńjìnì bá ń ṣiṣẹ́, fàànù yìí a máa yí. Ẹ̀rọ yìí máa ń gbóná púpọ̀ tó bá ń ṣisẹ́, Nítorí ẹ ni a fi ń lò fàànù fi fẹ́ atẹ́gùn sórí ẹ, ti ẹ bá wò ó.
Àwòrán 3
-
Àwọn apá kékèké tó wà lórí ẹ ní jẹ́ kí atẹ́gùn tó ó lára dáadáa. Tí àpótí yẹn bá gbóná jù àwọn ohun ìdáàbòbò á bàjẹ́, tí ìgbì iná a máa wá gbà ibi tí kò yẹ, tí yóò sì wá jẹ́ kí ẹ̀rọ gbóná títí yóò fi wá múná ( Àwòrán 4 ).
Àwòrán 4
-
Òpó tí máa ń yí, jókòó sorí àwọn onígbéyí ( Àwòrán 5 ) tó wà níwájú, àti ẹ̀yìn, tí wọ́n sì ń gbé òpó yìí yí, tí wọ́n sì tún mú dúró.
Àwòrán 5
-
Nínú àpótí yìí náà ni státọ̀ ( ẹ̀yà ìdúró ) wà; àwọn okùn iná ẹdẹ ni a fi ṣé àrunpọ̀ mélòó kan tí a sì kó wọn sí abẹ̀ àpótí ẹ̀rọ wa ní àyíká ẹ ( Àwòrán 6 ).
Àwòrán 6
-
Α fi ohun àlùmọ́nì àdádó pa àwọn okùn iná náà kí wọń má bá kan ara wọn nítorí ìgbì iná Tí ń gbànu wọ́n nígbà gbogbo, bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ yóò gbà ọ̀nà mìí tí yóò sì bà á jẹ́.
-
Ẹ̀rọ àmóhun ṣiṣẹ́ oní ìgbì iná alálọ̀bọ̀ oní ìgbá mẹ́tà ni ẹ̀rọ yìí, nítorí pé ó ní àrunpọ̀ mẹ́tà, Α tún máa ń pè ni ẹ̀rọ oní ìpele mẹ́tà, nítorí pé àwọn ìgbì iná náà máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀, àmọ́ wọ́n kìí gbéra nígbà kannáà.
Tí a bá kì rótọ̀ sí àárin státọ̀ (Àwòrán 7 ), tí a sí so àwọn àrunpọ̀ ẹ mọ́ agbára iná, rótọ̀ yìí a bẹ̀rẹ̀ sí máa yí.
-
Báwo lo ṣẹ jẹ́ ?
Àwòrán 7
Α ṣàlàyé ẹ :
-
Tí ìgbì iná bá ń ṣàn nínú okùn iná mànàmáná, ìṣẹ̀dá agbègbè òòfà máa wáyé ní àyíka okùn yìí ( Àwòrán 8 ), a tí tún lè rí ìṣẹ̀dá agbègbè òòfà yìí tí a bá kó àwon atọ́kà sí àyíká okùn iná yìí , àwọn atọ́kà wọ̀nyìí á dárí sí ọ̀nà ìdárí ẹ.
Àwòrán 8
-
TÍ ìdárí ìgbì iná bá yípadà, àwọn atọ́kà náà máa yípadà. Agbára agbègbè òòfà okùn iná ní tì àwọn apá àwọn atọ́kà, ní sì tún fa Wọn. Tí a bá run okùn iná yìí pọ̀ sínú àrunpọ̀, agbára òòfà ẹ á tún lọ sòkè, Àrunpọ̀ á ṣẹ̀dá àwọn èbúté ( Àríwá àti gúùsù ) bíi òòfà ìdágún Nídúrósinsin. Àwọn okùn àrunpọ̀ wọ̀nyì ni a ń pè ni olùdásílẹ̀ òòfà. Tí a Bá so okùn yìí mọ́ agbára iná alálọ́bọ̀, àwọn ìtanná a máa pàrọ̀ ìdárí nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ náà ni àgbègbè òòfà a máa yí pẹ̀lú ìgbì iná, tí yóò máa ga, tí yóò sì tún máa kére, tí yóò sì tún máa yí. Tí a bá gbé àrunpọ̀ mì ín, tí a sì gbé sí ẹgbẹ́ agbègbè òòfà tí àkọ́kọ́, ìṣẹ̀dá agbègbè òòfà yóò wáyé sínú àrunpọ̀ kejì tí ìgbì iná yóò tún wáyé nínú ẹ ( Àwòrán 9 ).
Àwòrán 9
-
Nígbà tí a bá ń wá kí agbára agbègbè òòfà pọ̀ sí, à lè mú àrunpọ̀ méjì, tí a sì gbé wọn síwájú ara wọn. Tí a bá gbé onígún mẹ́rin okùn irin sínú agbègbè alágbára yìí, ìṣẹ̀dá ìgbì iná yóò wáyé nínú ẹ ( Àwòrán 10 ).
Àwòrán 10
-
Α tí mọ̀ pé tí ìgbì iná bá ń ṣàn núnú okùn iná, agbègbè òòfà máa wáyé ní àyíká ẹ, a sì tún mọ̀ pé àwọn agbègbè òòfà máa ń ti ara wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n tún máa ń fara wọn. Èyí túmọ̀ sí wí pé okùn iná onígúun tí a gbé sínú agbègbè alágbára òòfà á ṣẹ̀dá agbègbè òòfà tòun náà, àwọn agbègbè òòfà méjèjì wọ́n a sì máa fara wọn, wọ́n sì tún máa tì ara wọn. Lórí ọwọ́ yìí agbára ìṣiṣẹ́ á wáyé ní àwọn ẹgbẹ́ okùn iná onígún mẹ́rin yìí, okùn náà a wá bẹ̀rẹ̀ sí máa yí. Okùn iná yì ni a ń pè ni rótọ̀, àwọn àrunpọ̀ ni a ń pè ni státọ̀.
Àmọ́ tí rótọ̀ yìí bá yí dé ibi tí ìdárí agbára òòfà ẹ dọ́gba mọ́ ìdárí agbára òòfà àwọn àrunpọ̀ méjèjì, yóò wá dúró. Nígbà tí a bá lò àrunpọ̀ méjì mì ín, tí a sì so gbogbo wọn pọ̀ mọ́ ìgbì iná alálọ́bọ́ méjì, àmọ́ tí wọ̀n ò kìí gbéra ní ìgbà kannáà, àwọn ìgbì iná tí yóò máa ṣàn nínú àwọn àrunpọ̀ wọ́n á yàtọ̀ díẹ̀ sí ara wọn, àwọn agbègbè òòfà méjèjì wọ́n a máa kére, wọ́n a máa ga tí wọ́n a sì máa yí pọ̀, èyí ni yóò mú ki okùn iná onígún yìí máa yí lọ (Àwòrán 11 )
Àwòrán 11
-
Nínú àwọn ẹ̀rọ àmóhun ṣiṣẹ́ oní ìgbì iná, àwọn àrunpọ̀ alágbára mẹ́tà ni a máa ń lò, tí wọ́n sì máa ṣẹ̀dá agbègbè òòfà mẹ́tà pẹ́lú àwọn ìgbì iná alálọ́bọ̀ mẹ́tà tí ìgbéra wọn á sì yàtọ̀ díẹ̀ sí ara wọn.
Tí a bá so àwọn àrunpọ̀ mẹ́tẹ̀tà mọ́ ìgbì iná alálọ́bọ̀, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ pọ̀ àmọ́ tí wọ́n ò gbéra nígbà kannáà. Àwọn ìtanná tí ń gbà inú àwọn àrunpọ̀ a máa pàrọ̀ ọ̀nà ìdárí wọn ní ìgbà tó yàtọ̀ díẹ̀. Àwọn àrunpọ̀ státọ̀ wọ̀nyìí fi ìyí igún 120º fi jìnà sí ara wọn. Àwọn agbègbè òòfà wọ́n a máa pàrọ̀ agbára ìgbì iná, iye igún pẹ̀lú ìyí wọn, gbogbo èyí yóò máa fún wa ni àmì agbègbè òòfà tí ń yí tí kò dúró mọ̀.
Α tí ri ní àtẹ̀yìn wá pé àrunpọ̀ ti a so mọ́ agbára iná máa ṣẹ̀dá agbègbè òòfà. Tí a bá gbé àrunpọ̀ mì ín sí ẹgbẹ́ ẹ, agbègbè òòfà á wáyé nínú àrunpọ̀ kejì tí ìgbì iná á tún máa ṣàn nínú ẹ.
-
Níbi : a so àwọn okùn iná onígún mẹ́rin pọ̀ tí o wà dàbí àjà ọ̀kẹrẹ (Àwòrán 12 ) , a ò níí jẹ́ ki ìgbì iná máa gbà èbúté àwọn opá náà. Èyí ní yóò fún wa ni àǹfààní láti ní àwọn okùn iná onígún mẹ́rin tí ń yí, tí àwọn náà wọ́n á ṣẹ̀dá àwọn agbègbè òòfà mì ín, tí wọ́n sì máa wá yí pẹ̀lú àwọn agbègbè òòfà státọ̀.
Àwòrán 12
-
Tí àwọn agbègbè òòfà bá ń yí, àwọn agbègbè òòfà àwọn okùn iná onígún mẹ́rin náà máa wá yí tẹ̀lé wọn, ní ọ̀nà ìdárí kannáà. Nítorí ìpele mẹ́tẹ́tà ìgbì iná státọ̀ ni kò níí jẹ́ kí àwọn okùn iná rótọ̀ dúró láti máa yí ( Àwòrán 13 ).
Àwòrán 13
-
Α máa jẹ́ kí àwọn opá rótọ̀ gbàn díẹ̀ kí àwọn agbègbè òòfà ẹ lè tàn ká sórí gbogbo àwọn opá náà, tí kò sì ni jẹ́ kí rótọ̀ dúró.
-
Státọ̀ ní gbogbo àwọn àrunpọ̀ tí ń jẹ́ ká ṣẹ̀dá agbègbè òòfà tí ń yí, tí ìgbì iná bá gbànu àwọn okùn wọn. Nígbà tí a bá fẹ́ fa iná wà inú àwọn àrunpọ̀ státọ̀, àpótí tó wà lókè ẹ̀rọ yìí ni a máa ń lò ( Àwòrán 14 ).
Àwòrán 14
-
Nínú àpótí yìí a ní èbúté mẹ́fa, àwọn orúkọ wọn ni U1, V1, W1 àti W2, U2, V2.
Àwọn èbúté méjèjì àkọ́kọ́ ni a so mọ́ àwọn ébúté U1, U2; àrunpọ̀ èkejì ni a so mọ́ V1, V2; ẹkẹ́tà ni a so mọ́ W1, W2. Àwọn èbúté náà ní ètò, tí a máa sọ̀rọ̀ nípa ní wájú.
Α máa so àwọn èbúté àpótí mọ́ agbára iná, tí ẹ̀rọ wa á sì bẹ̀rẹ̀ sí máa ṣiṣẹ́.
Ọ̀nà méjì ni a máa gbà fi so àwọn àrunpọ̀ státọ̀ :
-
Àsopọ̀ onígún mẹ́tà, a ó so U1 pọ̀ mọ́ W2, V1 mọ́ U2 àti W1 mọ́ V
Èyí ní máa ń fún wa ní àǹfààní láti jẹ́ kí àwọn ìtanná máa ṣàn ní ìrọ̀rùn. -
Àsopọ̀ oníràwọ̀, a ó so W1, U2, V2 pọ̀, àwọn ìtanná wọ́n yóò wà pín sí èbúté àwọn àrunpọ̀ kọ̀ọ̀kan. Nínú àwọn ìgbékalẹ̀ àsopọ̀ wọ̀nyìí , àwọn iye ìtanná tí ń ṣàn nínú àwọn àrunpọ̀ yàtọ̀.
Àyẹ̀wò àwọn ìgbékalẹ̀ àsopọ̀ (Àwòrán 11)
-
Àsopọ̀ onígún mẹ́rin
Αgbára iná ní àárin àwọn okùn iná méjì jẹ́ fọ́ltì 400 pẹ̀lú ammítà, ní àwọn ébúté àrunpọ̀ a ó ri fọ́ltì 400. Nígbà tí àtàkò àrunpọ̀ bá jẹ́ ohm 20, èyí túmọ́ sí pé agbára ìgbì iná máa jẹ́ ampere 20, àmọ́ ìgbì iná nínú okùn iná á yàtọ̀, agbára ìgbì iná ẹ á wá jẹ́ ampere 34.6 iye yìí a rí pẹ̀lú ìdọ́gba ampere 200* 3 = 34.6
Nítorí pé okùn iná kan ni a so pọ̀ mọ́ àrunpọ̀ méjì.
-
Àsopọ̀ oníràwọ̀
Αgbára iná láàrin àwọn okùn méjì ni fọ́ltì 400 nínú ìgbékalẹ̀ oníràwọ̀ àrunpọ̀ wà ní sísopọ̀ ní ojú àmì òdo, a lè gbé okùn òdo gbà ibẹ̀, tí a bá wọ̀n agbára iná ni àwọn ébúté àrunpọ̀ méjì a ó ri fọ́ltì 230 ó kére nítorí pé okùn iná kan kò so mọ́ àrunpọ̀ méjì bí ti àtẹ̀yìn wá, èbúté kan wà ní sísó pẹ̀lú okùn iná kan èkejì wa ní sísó pẹ̀lú ojú àmì àpapọ̀ èyí to túmọ̀ sí pé àwọn agbára náà pín. Α lè ṣírò ẹ pẹ̀lú ìdọ́gba 400/ 3 = 230
Nígbà tí agbára iná bá tí kére, ìgbì iná pàápàá yóò kére, àrunpọ̀ yì ní àtàkò ohm 20 tí a bá wo ìdọ́gba yìí 230/20 = Α 11.5 agbára ìgbì iná pàápàá á jẹ́ Α 11.5
Αgbára láàrin okùn méjì fọ́ltì 400
Αgbára ìgbì iná ampere 11.5
Αgbára iná àrunpọ̀ fọ́ltì 230
Αgbára ìgbì iná àrunpọ̀ ampere 11.5
Αgbára láàrin okùn méjì fọ́ltì 400
Αgbára ìgbì iná ampere 11.5
Αgbára iná àrunpọ̀ fọ́ltì 230
Αgbára ìgbì iná àrunpọ̀ ampere 11.5