Àmójútó àwọn akẹ́kọ́

Ìkọ́ṣẹ́ àwọn akẹ́kọ́ wa nínú àwọn ilé-isẹ́ ṣe pàtàkì fún àwọn ètò ẹ̀kọ́ wa. Ìkọ́ṣẹ́ máa fún àwọn akẹ́kọ́  ni àǹfààní láti lò àwọn ìmọ̀ wọn nínú àwọn ilé-iṣẹ́ wọ̀nyìí. Yunifásítì ní ìbáṣepọ́ pẹ́lú àwọn ilé iṣẹ́ púpọ̀ láti ìgbà tó ti pẹ́. Àǹfààní pọ̀ ti àwọn akẹkọ́ ba ṣẹ ìkọ́ṣẹ́ wọn ní ìlú wọn, wọ́n á mọ̀ bí tí ọrọ̀ isẹ́ ṣe ń lọ, wọn á tún kọ́ ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ìmọ̀. Nígnà tí àwọn ilé-iṣẹ́ kò pọ̀ ní àwọn orí ilẹ̀ èdè Áfíríkà, Yunifásítì omoluwabi gbé ìgbésẹ̀láti ṣètò àwọn iṣẹ́ àkànṣe tí á jẹ́ kí àwọn akẹ́kọ́ tó tí fẹ́ pari ẹ̀kọ́ wọn máa rí bíi èyí tí wọ́n ń kọ́ṣẹ́ nínú àwọn ilé-iṣẹ́. Àwọn isẹ́ àkànṣe wọ̀nyìí  a máa wúlòn fún àwọn ìdálésẹ́ sílẹ̀ lọ́pọ̀lọ̀pọ̀. Yunifásítì Omoluwabi túnṣé ètò ẹ̀kọ́ ti a máa fún àwọn akẹ́kọ́ wa láti mọ̀ bíi ti wọ́n ti dá iléṣẹ́ kalẹ̀ bíi ti wọ́n ti jẹ́ kí ìdàgbàsòkè máa lọ síwájú.

Ẹ̀kọ́ ìdáléṣẹ́ kalẹ̀

Yunifásítì omoluwabi ṣẹ̀tọ ẹ̀kọ́ ìdáléṣẹ́ kalẹ̀ láti jẹ́ kí àwọn akẹ́kọ́ lè kọ́ bíi wọ́n se dá iléṣẹ́ kalẹ̀ tí wọn ṣe dá iléṣẹ́ kalẹ̀ wọ́n sì tún jẹ́ kó máa tẹ̀ síwájú
Àwọn ètò wọ̀nyìí ni :

– Ìsówọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn alábáṣepọ̀ àpótí owó àti àwọn onímọ̀
– Àwọn ìrànlọ́wọ́ ìjọba fún àwọn akẹ́kọ́
– Àwọn ohun ìlò àtiìrànlọ́wọ́ ìjọba àti àwọn ẹgbẹ ìpínlẹ̀

Àwọn ìrànlọ́wọ́ àti ìríṣẹ́

Yunifásítì omoluwabi lè gbà yín ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú àwọn ìsọfúnni, àti àwọn àlábáṣepọ̀, tí á fún yín ní àǹfààní àti tètè ríṣẹ́.
Ibi a fẹ́ dé Yunifásítì wa ni kí ẹ̀kọ́ wa lè wúlò fún wa ní Áfíríkà, ti á tún fún wa ní àǹfààní láti lọ díje ni àgbáyé.
Ìgbésẹ̀ àwọn akẹ́kọ́ wa ni kí wọ́n mọ̀ àwọn oríṣiríṣi iṣẹ́ tó wà pẹ̀lú àwọn iléṣẹ́ ti á gbà wọn sí iṣẹ́.
Nǹkan tó kàn ni kí àwọn akẹ́kọ́ máa ṣàfihàn àwọn iṣẹ́ fún àwọn ilé-iṣẹ́, kí wọ́n sì máa ràn wọn lọ́wọ́ láti máa gbé àwọn ọjà tuntun jáde, àwọn ọjà tí a máa wúlò púpọ̀ fún Áfíríkà ti á sì máa gbé àṣà wa lárugẹ.
Yunifásítì máa ń pé àpèjọ pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ́, láti jíroro sórí ìmọ̀ àwọn iléṣẹ́ lórí orílẹ̀ èdè wọn àti ti àgbáyé. Nígbà tí àwọn akẹ́kọ́ wa ti mọ̀ èdè wọn , tí wọ́n sì kẹ́kọ́ nínú rẹ̀, wọ́n á lè jẹ ẹ́ àǹfààní àwọn ìmọ̀ àti àwọn iṣẹ́ àgbáyé. Àwọn akẹ́kọ́ lè wá rí àǹfààní láti mọ̀ orọ̀ ajé àgbáyé tí wọ́n á rí ọ̀nà láti mọ̀ àwọn ọga iléṣẹ́ àti àwọn alákóso, àwọn oga ojú-iléṣẹ́ ìtajà àwọn iléṣẹ́ ńlá ńlá àti àwọn oga àpótí owó. Àwọn akẹ́kọ́ wọ́n á tún lè lò àwọn ìsọfúnni oríṣiríṣi fi wá iṣẹ́ bíi àwọn ìwé ìròyìn, ìbùdo ayélújara, àwọn ìpologo, àwọn àwùjọ. Tí a bá ń wá iṣẹ́ a ní láti fi àkọsílẹ̀ ohun-a-gbéṣe ránṣẹ́ sí àwọn ilé-iṣẹ́. Àwọn olùkọ́ wa , wọ́n á kọ yín bí tí wọ́n ṣe kọ ọ́. Kí a tó riṣẹ́, àwọn iléṣẹ́ máa ń pè wa fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, àwọn olùkọ wa wọ́n á kọ bí tí wọ́n tí ń ṣe é.