Yunifásítì Omoluwabi pínnu láti ní ìbáṣepọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú àwọn yunifásítì Fránsì, Ámẹ́ríkà, kánádà…, jù bẹ́ẹ̀ lọ àwọn yunifásítì tí wọ́n ní ètò ẹ̀kọ́ èdè Αfíríkà. Àǹfààní tó wà nínú ìbáṣepọ̀ yìí ni kí àwọn akẹ́kọ́ tún ní ìrírí ẹ̀kọ́ ilẹ̀ òkèrè tí á jẹ́ kí wọ́n lè ríṣẹ́ ìgbàlódé. Α tún ní ètò àti ràn àwọn akẹ́kọ́ wa lọ́wọ́ láti rí àwọn ilé-isẹ́ tí á gbà wọn sí isẹ́ nínú àwọn ìlú òkèrè wọ̀nyìí, bẹ́ẹ̀ náà ni a máa rí àwọn ilé-iṣẹ́ tí á gbà wọ́n fún ìkọ́ṣẹ́. nígbà tí àwọn olùkọ wa ti jẹ́ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè oíṣiríṣi bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn akẹ́kọ́ wa máa fi ní àwọn ìrírí oríṣiríṣi tí wọ́n sì mọ̀ àṣà orííṣiríṣi, èyí tún fún wọn ni àǹfààní láti máa ṣe àwọn àkànṣe tó lárinrin. èdè yorùbá tó dágíá tí àwọn akẹ́kọ́ wa kọ́ pẹ̀lú ìmọ̀ àṣà yorùbá á jẹ́ ki àwọn àkànse tí wọ́n bá se lè lárinrin ní ilé àti ní ìlú òkèrè.