A máa ń lò àwọn àfidámọ̀ àwọn trànsitọ fi mọ̀ ojú àmì ìsiṣẹ́ wọn. Èyí máa jẹ́ ká mọ̀ àwọn agbára iná mànàmáná tí a ń lò.
Àwọn àfidámọ̀ tí a máa sábà lò ni àwọn èyí tó jẹ mọ́ ìgbékiri iná mànàmáná ti ìjáde.
Nígbà tí a bá wo àsopọ̀ àwọn àfidámọ̀: àwòrán 1
VCE bá jẹ́ folt 10, bí ìwọ́ ìtanná bá jẹ́ µΑ 70,
Láti fi mọ ìwọ́ ìtanná tó jẹ mọ́ àwọn ààtò wọ̀nyìí, a kàn máa la ìlà olóòró ni
VCE = 10 tó gé àwọn àfidámọ̀ tó jẹ mọ́ IB= µΑ 70 ní ojú àmì Α. Lẹ́yìn náà a máa la ìlà oníbùú tí á gé ìlà olóòró atọ́nà, ibi oǹkaye yẹn jẹ́ : IC = mΑ 20 ojú àmì Α jẹ́ ojú àmì ìṣiṣẹ́ transitọ yìí. Ojú àmì máa ń jẹ́ ká mọ̀ àwọn ààtò ìsiṣẹ́ transitọ. Nígbà tí a bá mọ̀ ààtò méjì, ẹ̀kẹ́ta máa jẹ́ mímọ̀. Ẹ jẹ́ ká tún mú IC = mΑ 14, IB = µΑ 50 Α máa la ìlà oníbùú tó gé ìlà olóòrò atọ́nà ní IC = mΑ 14 èyí máa pàde àfidámọ̀ IB = µΑ 50 ní ojú àmì B, a yóò wá la ìlà olóòrò tó kúrò ní ojú àmì B, èyí máa fún wa VCE = folt 9 lórí ìlà oníbùú.
Ìṣàyẹ̀wò àwòrán 2 :
Àwòrán 2
Ìgbékalẹ̀ ìyíka iná mànàmáná alásopọ̀ pẹ̀lú alátagbà iná mànàmáná tí ń lò agbára iná folt 24, àtakò RB máa fún wa ni àǹfààní láti ní ìwọ́ ìtanná ìpìlẹ̀ IB. RC jẹ́ àtakò àdìjọ ìtanná tó sì wà nínú àkójọpọ̀ ìṣipòtákò ( transitọ ), agbára iná èbúté RC ni VR. àfikún VR pẹ̀lú VCE jẹ́ folt 24. Α fẹ́ mọ̀ ìdíwọ̀n àsopọ̀ tó wà láàrin àwọn ìwọ̀n VCE, IC pẹ̀lú IB. A mọ́ àsopọ̀ àwọn àfidámọ̀ ìjáde pẹ̀lú àwọn ààtò IB.
Nígbà tí a bá mú oǹkaye mélòó kan fún ìwọ́ ìtanná IC, tí a á ṣírò agbára iná VCE fún àwọn oǹkaye kọ̀ọ̀kan, èyí máa fún wa ni àǹfààní láti fi àwọn ojú àmì sórí àsopọ̀ àwọn àfidámọ̀.
Bí IC = mΑ 5
VR = RC * IC = 800 * IC = 800*5*10-3= folt 4
VCE = 24 -4 = folt 20
Àwòrán 3
Gbogbo àwọn ìṣirò wọ̀nyìí máa fún wa ni àwọn ojú àmì Α
Fún IC = mΑ 10, VR = folt 8 VC = folt 16 ( ojú àmì B )
Fún IC = mΑ 20 VCE = folt 12 ( ojú àmì C )
Fún IC = mΑ 20 VCE = folt 8 ( ojú àmì D )
Fún IC = mΑ 25 VCE = folt 4 ( ojú àmì E )
Àwọn ojú àmì márà-rún wà lórí ìlà kan, a lè la ìlà yìí, tí á gbà gbogbo àwọn ojú àmì wọ̀nyìí. Ìlà yìí ni a ń pè ni ìlà àdìjọ ìtanná.
Gbogbo àwọn ojú àmì wọ̀nyìí ṣàfihàn àwọn ojú àmì ìsiṣẹ́ ìṣípòtakò ( transitọ ). Fún gbogbo àwọn ojú àmì a lè mọ̀ àwọn ìwọ̀n VCE, IC, àti IB tó jẹ mọ́ wọn.
Ìlà yìí gé àwọn ìlà atọ́nà ní ojú àmì méjì P àti Q.
ojú àmì Q jẹ mọ́ VCE = folt 0, nígbà yẹn VR dọ́gba mọ́ VCC.
Nígbà tí a bá ri ojú àmì méjì a lè la ìlà tó gba ojú àmì méjèjì fi mọ̀ ìlà àdìjọ ìtanná.
Bíi àpẹẹrẹ
Nígbà tí a bá mú RC = KΩ 1,3 agbára VCC = folt 16, bí IC = 0 VR = 0
VCE = VCC = folt 16, a máa mọ Q’ lórí ìlà oníbùú ( àwòrán 4 )
Láti mọ̀ ojú àmì kejì VCE = folt 0 ìgbàyẹn VR = folt 16 tí IC = VR / RC = 16/13 = mΑ 12,3.
Nígbà náà a máa so àwọn ojú àmì P’ àti Q’ pọ̀. Nígbà yìí a lè la ìlà àdìjọ ìtanná. Nígbà tí RC = KΩ 1,3 tí VCC = folt 16, ààyè ẹ yàtọ̀ gedegbe sí ti wájú.
Àwọn àpẹẹrẹ méjèjì fihàn wa; ààyè ìlà jẹ mọ́ VCC àti RC, àmọ́ kìí rọrùn nígbà gbogbo ká lè mọ̀ àwọn ojú àmì méjèjì tó wà lórí àwọn ìlà atọ́nà.
Àpẹẹrẹ
Nígbà tí VCC = folt 24 àti RC = KΩ 0,3.
Bí IC = mΑ 0 VCE = VCC = folt 2 a mọ̀ Q lórí ìlà oníbùú.
Nígbà ti VCE = folt 0, IC = 0 folt, IC = VR / RC IC = 24/300 = 80 mΑ, àmọ́
IC = mΑ 80 kò sí nínú àtẹ ó yẹ kí a ṣàwàrí ojú àmì mì ín, Α á mú IC = mΑ 50 VR = RC * IC = 300*50*10-3= folt 15.
VCE = VCC – VR = 24 -15 = folt 9.
Nígbà yẹn ojú àmì kèjì ni VCE = folt 9, IC = 50 mΑ, ìlà ìdìjọ ìtanná máa gba S àti Q. Nígbà yẹn ó rọrùn láti mọ̀ VCE àti IC tí a bá mọ̀ VC àti IC tí a bá mú
IB = µΑ 110.
Bíi àpẹẹrẹ àwọn àfidámọ̀ tí IB = µΑ 110 pàde ìlà ìdìjọ ìtanná ní T tí a fún wa ni àǹfààní
VCE = folt 14 àti IC = mΑ 33,5
2.2 Àwọn ààlà oǹkaye fún ìṣipòpadà
Bíi gbogbo àwọn ẹ̀yà ohun abánáṣiṣẹ́ Ìṣípòtakò ( transitọ ) máa ṣiṣẹ́ láàrin àwọn ààlà agbára iná tó wà lásopọ̀. Àwọn ààlà wọ̀nyẹn jẹ mọ́ irúfẹ́ Ìṣípòtakò, títóbi, àti àwọn ohun èlò rẹ̀.
Fún gbogbo transitọ, àwọn iléṣẹ́ tó rọ wọn máa fún àwọn oǹkaye ààlà tí a ò gbọdọ̀ dá kọjá nígbà tí a bá ń lò ó, bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ a máa ba transitọ yẹn jẹ́, tàbí kò níí ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Àwọn iléṣẹ́ máa fún wa ni :
Iyé ìwọ̀ ìtanná alákojọpọ̀ IC tó ga jù
Αgbára tó ga jù ti alákojọpọ̀ VCE
Αgbára ìṣiṣẹ́ tó ga jù alákojọpọ̀, PC ògó
Gbígbóná àsopọ̀ tó ga jù Tj ògó
Wọ́n tún lè fún wa ni àwọn iye ààlà mì ín tó jẹ mọ́ ìpìlẹ̀ àti alátagbà
Iyé ìwọ́ ìtanná alákojọpọ̀ tó ga jù :
Α máa ri iyé yẹn lọ́nà ti transitọ máa ṣiṣẹ́ dáadáa, tí àsopọ̀ ẹ̀yà rẹ̀ kò níí bàjẹ, a ṣàfihàn iyé yìí lórí : àwòrán 5
Àwòrán 4
a ṣàfihàn iyé yẹn pẹ̀lú ìlà gígùn tótòtó.
Ojú àmì ìṣiṣẹ́ láti wà ni ìsàlẹ̀ ìlà yìí, ọ̀nà méjì ló pin sí yálà :
Kí gbogbo àwọn ojú àmì ìṣiṣẹ́ wà nísàlẹ̀ ìlà tótòtó
NÍ ìdà kèjì ( RC = Ω 800 ), ìlà àwọn àdìjọ ìtanná gé ìlà gígùn tótòtó ní ojú àmì A ti àpẹẹrẹ àwòràn 5.
Nígbà yẹn a ní láti sèdínkù ìwọ́ ìtanná IB dé mΑ 180, àwọn àfidámọ̀ tó jẹ mọ́ IB = µΑ 180, gba ojú àmì Α tí gbogbo ojú àmì ìṣiṣẹ́ transitọ kò lè wà lókè Α, a lè sọ pé Α jẹ́ ojú àmì tó ga jù fún iṣiṣẹ́ transitọ.
Αgbára iná mànàmáná tó ga jù fún alákojọpọ̀ Nígbà tí a ṣàlàyé diọ́dì alásopọ̀, a rí pé agbára àlòdì “agbára iná ìfọ́ túútúú” kò láti ga ju iyé kan lọ, bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, díọdì yìí máa bàjẹ́, nínú transitọ, a ri pé àsopọ̀ alákojọpọ̀-ìpìlẹ̀ dọgba mọ́ diọdì alágbara iná alòdì. Agbára iná kan wà ti a gbọdọ̀ dákọjá : agbára iná ògóróró.
VCE ògó ni ìlà gígùn ti àwòrán 6.
Nígbà tí VCE bá ju VCE ògó lọ, Ìṣípòtakò yẹn máa bàjẹ.
Àwòrán 6
Ojú àmì ìṣisẹ́ wà ni apá òsì ìlà gígùn tótòtó. Nígbà tí agbára VCE bá ju VCE ògóróró lọ IC máa ga ju èyí tí a mú ki transitọ bàjẹ́.
Αgbára ìṣiṣẹ́ ògóróró àgbàsara àkójọpọ̀ Àgbásara agbára ìsiṣẹ́ ìṣipòpadà ni VCE ìlọ́po IC
PC = VCE * IC ( VCE folt, IC mΑ )
Αgbára ìṣiṣẹ́ àgbàsara transitọ jẹ́ agbára ìmúlò iná mànàmáná.
Αgbára iná máa yípadà sí agbára ìgbóná, èyí tó túmọ̀ sí pé transitọ máa gbóná, ìgbóná ojú àsopọ̀ máa lọ sókè, àmọ́ ìgbóná ò lè ju iyé kan lọ, a ní láti ṣèdikù agbára ìsiṣẹ́ yẹn, a lè ṣàfihàn ìlọsókè ìgbóná pẹ̀lú ìdọgba
Tj = Rth * PC (1)
Tj jẹ́ ìlọsókè ni ºc, Rth olùlọ́po ti a pè ni àtakò ìgboná transitọ, PC agbára ìṣiṣẹ́ iná.
Olùlọpo Rth ti a ṣàlàyé ni ºc/w tí a sì tókasí ìlọsókè ìgbóná àsopọ̀ tí a ṣàlàyé sí ºc fún àgbàsara agbára ìṣiṣẹ́ watt kan.
Rth = 400 ºc / w, VCE = 5 volts, IC= mΑ 3.
PC = 5*3 = mW 15
Tj = 400*0,015 = º6
Α máa lò ìdọgba yìí fi ṣírò ìgbóná àsopọ̀ :
T’j = Ta + Tj
Tj jẹ́ ìgbóná àsopọ̀
Ta jẹ́ ìgbóná agbègbè
Nígbà tí a bá mú bíi àpẹẹrẹ Ta = º25
Tj = 25 + 6 = ºc 31
Ìgbóná ògóróró ti àsopọ̀ wà láàrin ºc 150 àti ºc 200 fún transitọ oní sílíkíọ́mù.
Ìgbóná àsopọ̀ Tj jẹ mọ́ Ta pẹ̀lú ìlọsókè Tj tí òun náà jẹ mọ́ Ta pẹ̀lú ìlọsókè Tj tó jẹ mọ́ PC ògóróró, irúfẹ́ transitọ àti Ta.
Àwọn ilésẹ́ ti rọ ẹ̀rọ máa ń fún iyé PC ògóróró, nígbà tí ìgbóná bá jẹ́ iyé kan. Wọ́n máa sàbá fún wa ni Rth àti Tj ògó, àti ibẹ̀ a lè sírò PC ògó láti (1)
PC ògó = T’j ògó/Rth = Tjògó-Ta/Rth.
Nígbà tí a bá mọ̀ Tj ògó, Ta àti Rth alè mọ́ PC ògó.
ó yẹ ká wò bí tí ìmọ̀ PC ògó máa ń ṣèdínkù agbègbè ìmúlò ti àsopọ̀ àfidámọ̀. Nígbà tí a mọ̀ PC ògó o rọrùn kí a la ìlà tí ìdọ́gba jẹ́
VCE * IC = PC ògó Àwóràn 7
Àwòrán 7
Àwòrán 7 máa ṣàfihàn 3 PC max ( 400 mV, 200mW àti 100 mW ).
Α máa pe àwọn ìlà ìyípo wọ̀nyìí ni ìlà ìyípo “ ìdọ́gba agbára ìsiṣẹ́ iná”, nítorí pé gbogbo àwọn ojú àmì ìsisẹ́ wà lórí ìlà yìí ti agbàsara transitọ sì jẹ́ ọ̀kan náa, a ṣàfihàn ìlà ìyípo IC ògó àti VCE sórí àwòrán 8.
Àwòrán 8
Èyíkéyì ojú àmì ìsiṣẹ́ láti lè wà ni agbègbè : àwọn ìlà atọ́nà méjèjì, àwọn apá kan ìlà tí ṣàfihàn IC ògó àti VCE ògó pẹ́lú ìlà ìyípo ( ìdọ́gba agbára ìṣiṣẹ́ iná ).
Àwòrán 9
Nígbà tí ìgbóná agbègbè bá jẹ́ ºC 25 PCògó mW 125 àwọn agbègbè tó wà nínú àyíká àwọn ojú àmì O Α B C àti D.
Agbègbè yìí máa kére tí ìgbóná bá lọ sókè.
Nígbà tí Ta = ºC 550 PC ògó = mW 50, nígbà yẹn àgbègbè máa jẹ́ O Α B’ C’ D.