Àwọn onímúgbòòrò amóhun sisẹ́ wà lára àwọn èkà ẹ̀rọ ìtanná àgbáyé ti máa ń fún wa ni àǹfààní láti gbòòrò àwọn agbára ìṣiṣẹ́ àti agbára ìdènà iná mànàmáná. Α máa ṣàtúntò àwọn agbára wọ̀nyìí pẹ̀lú ìgbékiri iná mànàmáná ti a fi ṣàfikun    ( àtàkò ìṣẹ̀lẹ̀, ìdènà amúnáwa ).
Àwọn àfidámọ̀ onímúgbòòrò amóhun ṣisẹ́ máa jẹ́ kí a ní ìgbòòrò agbára ìdènà àti ti àtàkò tó ga pẹ̀lú ti àtàkò ìjáde tó kére.
Α fún ẹ̀kà ẹ̀rọ ìtanná náà ni orúkọ yìí láti ìmọ̀-ẹ̀rọ ìṣírò aláfiwé ti ń fún wa ni àǹfààní láti ṣe ìgbékalẹ̀ àwòṣe ìṣe mátímátíkì  ( àfikún, ìdàpọ̀ kúrò ).
Α máa ń rọ àwọn onímúgbòòrò pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà alábaṣiṣẹ́ tàbí pẹ̀lú àwọn ẹ̀run ìgbénákiri.
Àwọn àfidámọ̀ tó ṣe pàtàkì fún àwọn onímúgbòòrò ni wọ̀nyìí :
Onímúgbòòrò ní ojú àmì ìwọlé méjì, ìpele ìwọlé jẹ́ onímúgbòòrò oníyàtọ̀. Αgbára ìdènà ìwọlé dọ́gba mọ́ ìyàtọ agbára ìdènà láàrin àwọn agbára ìdènà méjèjì yìí :

                                                   UD = UP – UN

Α sàlàyé ìwọlé E1 bíi ìwọlé ti kìí se alòdì, ti a sì fún ni àmì rere, E2 jẹ́ ìwọlé alòdì ti a sì fún ni àmì alòdì.
àwọn irúfẹ́ onímúgbòòrò báyìí máa jẹ́ ki ìyàtọ̀ ìpele ìjáde jẹ́ 180º sí i ti ìwọlé ( ìdójúkọ ìpele ).

Αmúnáwá onílọ̀ọ́poméjì ni a máa lò fún onímúgbòòrò ( alòdì àti rere ). Nígbà yẹn wọ́n a lè fún wa ni àwọn ìdènà rere àti alòdì

 

Àwọn nńkan ti mú wa yàn àwọn onímúgbòòrò  ni :

  • Ìyàtọ onímúgbòòrò ( ΑD ) :

ΑD =   ∆Ua
∆UD

            Nínú ìgbékiri iná mànàmáná ti kò síi àtàkò ìgbòòrò máa jẹ́ 103…105
Ìyàtọ ìdènà U0 “ Ìwọlé ìyàtọ ìdènà “. Ìyàtọ agbára àti ṣiṣẹ́  ti a ní láti lò fi dí àlàfo àléébù àwọn onímúgbòòrò láti rí ( IaI) tó jẹ́ òdò ní ìjáde onímúgbòòrò nígbà tí

                               UD = UP – UN = 0.

Nínú gbigbéṣé agbára ìdènà  ìyàtọ máa wà láàrin microfóltì àti millifọ́ltì.

  • Ìyàtọ iyé ìgbóna ( J ) tó jẹmọ́ ìyàtọ ìgbóna ààyè pẹ̀lú irúfẹ́ onímúgbòòrò tí a ń lò. Iyé agbára ìdènà ìyàtọ máa yípadà láti microfọltì bíi mẹ́wa lọ́nà ìyí.

  • Onímúgbòòrò ní ọ̀nà àsopọ̀ ( Oa ) :

    Ìgbòòrò ti ń máa wáyé ti a bá so agbára àmì méjì tó dọgba mọ́ àwọn ìwọlé ojú àmì ìwọlé mọ́ àwọn ìwọlé ojú àmì ìwọlé méjèjì onígbòòrò.

    Tí a bá fójú inú wò láti jẹ́ òdo, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀. Àléébù àwọn ẹ̀yà ohun abánáṣiṣẹ́. Α máa ní ìyàtọ agbára ìdènà yìí :

    ΑC =  ∆Ua
    ∆UD

            UC agbára ìwọlé tó jọra

  • Olùlọpọ̀ ìdànù aláṣepọ̀ :

    Olùlopọ̀ ti ń tókasí àwọn onímúgbòòrò amóhun sisẹ́.

                                            K = ΑD

                                                   ΑC

K lè jẹ́ àwì rere tàbí alòdì. Àwọn iyé rẹ̀ ti a má sàbá rí 103 ….  105.
Nínú àwọn ìwé àlàkalẹ̀ iyé K nìkan ni wọ́n máa ń fun

Akim Agueh
Author: Akim Agueh