Ẹ̀kọ́ Αlúgórídímù
Αlúgórídímù
Nígbà tí a bá fẹ́ kọ alúgórídímù, ìgbésẹ̀ mẹ́ta ni a máa ń gbé.
I Àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́ta náà ni
1.1 ) Ìgbésẹ̀ kìíní
Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni kí a ṣàlàyé àwọn ohun ti a fẹ́ lò ( Àwọn oníyípadà, ìró , nọ́ḿbà..)
1.2 ) Ìgbésẹ̀ kejì
A máa tú ìṣòro wa sí wẹ́wẹ́ ni ọ̀nà ìpele mélòó kan. Èyí ni a máa fún wa ni ìrọ̀rùn láti yanjú ìṣòro yìí.
Àpẹẹrẹ
Α fẹ́ ṣírò ( a + b ) oníyípadà a, oníyípadà b
tẹ a;
tẹ b;
d <– a+b
ìfihàn “d”; / ni orí ìbòjú
1.3 ) Ìgbésẹ̀ Kẹta
Ìtẹ̀jáde àbáyọ́ ìṣòro wa, kí olùmúlò lè rí í kà.
II Kí ni alúgórídímù
2.1 Ọ̀nà ti a fi ń lò alúgórídímù
Αlúgórídímù fẹ́ fi ara jọ ètò, àmọ́ kìí ṣe é ètò nítorí àwọn ètò ní àwọn ìtọ́sọ́nà ( kóòdù ) ti a ń lò fi kọ wọn.
Αlúgórídímù kò níí àwọn ìtọ́sọ́nà ( kóòdù ) kan pàtó. Olùmúlò gan-an ni a á kọ àwọn ìtọ́sọ́nà ( kóòdù ) láti fi ètò sí èrò rẹ, àti fi rí ọ̀nà àbáyọ fún ìṣòro rẹ.
2.2 Báwo ni a ń kọ alúgórídímù ?
Ètò : orúkọ ètò náà
Oníyí: oníyípada1, oníyípada2 … : ohun ìṣẹ̀dá
Ìbẹ̀rẹ̀
| Ìtọ́sọ́nà 1
| Ìtọ́sọ́nà 2
| Ìtọ́sọ́nà 3
| …………….
òpin
2.3 Àlàyé àwọn ohun èelò
2.3.1 Àwọn ohun èelò ìpìnlẹ̀
Àwọn èyí ti a ń lò fún àwọn ètò ìkójọpọ̀ ( C, C++, cobol, java…).
Àwọn ìwọ̀nyìí ni : ìró, àsòpọ̀-iró, nọ́ńbà rere, nọ́ńbà òdì, alákómejì, àtẹ.
2.3.2 ìró
Àwọn wọ́nyìí ni àwọn ìró fáwẹ́ẹ̀lì, kọ́ńsónáńtì, nọ́ńbà, àti àwọn omìíran… Báítì ni àṣojú wọ́n, báítì kan jẹ́ ìró kan.
2.3.3 Àsópọ̀-ìró
Àwọn àsópọ́ ìró yìí ni máa ń ṣàpèjúwé ohun ti a fẹ́ sọ.
Àpẹrẹ ilé, ìlú, ìyá …
2.3.4 Alákóméjì
Àwọn oníyípàdà tí máa ń ní ojú méjì (“ojú” , “òdì” ) tàbí (“òdo”, “òótọ́”) tàbí pẹ̀lú àwọn nọ́ńbà (“0”, “1”).
2.3.5 Nọ́ńbà
Àwọn wọ̀nyìí ni odò, nọ́ńbà òdì, nọ́ńbà rere ;
Àpẹrẹ :
Nọ́ńbà òdì : -1, -2, -3, -4, -5, ………
Nọ́ńbà rere : 0, 1, 2, 3, 4, 5, …………
2.3.6 Nọ́ńbà gidi rere
Αpẹrẹ 1.2, 25.412, 452.478 …..
2.3.7 Nọ́ńbà gidi òdì
Αpẹrẹ -1.2, -25.412, -452.478 …..
2.3.8 Àtẹ
Inú àtẹ yìí ni a máa ń kó àwọn ohun èelò ti ó jọ́ra wọn sí, ti a sì fún ni orúkọ tó jẹ́ orúkọ àtẹ, tí á so mọ́ orúkọ àwọn atọ́ka nọ́mba.
oníyí orúkọ(b1 ,b2): nọ́ńbà
Àpẹẹre
TA
1 | 2 | 3 | 0 | 4 | -1 |
2.3.9 Ohun ọ̀wọ́
Àwọn ohun ọ̀wọ́ ni àwọn ohun ìpìnlẹ̀ tí a sopọ̀ fi ṣẹ̀dá ẹ.
Ohun ọ̀wọ́ orúkọ= (…….., …….., …….. )
Àpẹẹrẹ
Ohun ọ̀wọ́ ọlùkọ= ( nomba : nọ́mbà, orukoakoko : àsopọ̀ iró, orukoidile: àsopọ̀ iró )
3 Àwọn ìtọ́sọ́nà ìpìnlẹ̀
3.1 Ìtọ́sọ́nà fi sí
Ìtọ́sọ́nà yìí ni a máa ń lo fi fi ohun èelò sínú oníyípadà. Àmì ọ̀fà ni a mán ń lo fi kọ ìtọ́sọ́nà náà.
< oníyípadà > <– < ohun èelò >
Àpẹẹrẹ
a <– 3;
Oruko <– “Αde”;
3.2 Àwọn ìtọ́sọ́nà ìwọlé àti ti ìjáde
3.2.1 Ìtọ́sọ́nà Ìwọlé
Ìtọ́sọ́nà Ìwọlé ohun èelò ni a máa ń lò fi fi ohun èelò yìí sínú ìranti ẹ̀rọ kọ́ńpútà ( ẹ̀rọ ìtẹwé kọ́ńpútà ) ni tẹ. Α á lò oníyípadà fi gbé ohun èelò ti a tẹ̀ pamọ.
tẹ < ohun èelò >
Àpẹẹrẹ
tẹ a.
3.2.2 Ìtọ́sọ́nà Ìjáde
Ìtọ́sọ́nà Ìjáde ohun èelò máa jẹ́ kí a kọ ọ́ sórí ìbòjú kọ́ńpúta kí olùmúlò lè rí í kà.
Ìtọ́sọ́nà náà ni ìfihàn
ìfihàn < ohun èelò >
Àlàyé àwọn oníyípadà
Kí a tó lò àwọn oníyípadà a ni láti ṣàlàyé wọn , báyìí ni a ń ṣe é.
oníyí orúkọ-oníyípadà : ohun èelò
Α lè kó àwọn oníyípadà kannáà pọ̀ sínú ìkójọ kan.
Àpẹẹrẹ
oníyí i, j, k : Nọ́mba
4 Àwọn ìtọ́sọ́nà ìṣiṣẹ́
Àwọn ìtọ́sọ́nà ìṣàkóso alúgórídímù ètò ni a ń lo fi ṣé wọn.
4.1 Àwọn ìtọ́sọ́nà ìṣàkosó
Ìwádìí àwọn ọjọ́gbọ̀n fi yé wa wí pé a lè kọ alúgórídímù ètò pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà ìṣákóso mẹ́ta, a máa ń pè àwọn wọ̀nyìí ni ìtọ́sọ́nà ìpìnlẹ̀ .
Àwọn mẹ́tẹ̀ta ni :
-
lẹ́sẹẹsẹ
-
Àtúnṣe
-
Omìíran
4.1.1 Ìtọ́sọ́nà ìṣàkóso lẹ́sẹẹsẹ
Ìtọ́sọ́nà 1
Ìtọ́sọ́nà 2
Ìtọ́sọ́nà 3
…………….
Àwọn ìtọ́sọ́nà ìṣàkóso wọ̀nyìí máa ń fún wa ni àǹfààní láti kọ àwọn ìtọ́sọ́nà sínú ìkójọ kannáà, a kọ àkọ́kọ́ sẹ́yin èkejì, èkejì sẹ́yin ẹ̀kẹ́ta… bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ́ lọ.
4.1.2 Ìtọ́sọ́nà ìṣàkóso omìíran
Àwọn ìtọ́sọnà ìṣàkóso wọ̀nyìí ni a máa ń lò tí a bá fẹ́ lò ìtọ́sọ́nà kan tàbí omìíran. Májẹ̀mu ni máa tọ́ wa sọ́nà.
Báyìí ni a ń kọ wọn.
Nígbà tí ( májẹ̀mu = “òótọ” )
| Ìtọ́sọ́nà 1
bkbrb
| Ìtọ́sọ́nà 2
ÒpinNígbà
bkbrb : bí kò bá rí bẹ́ẹ̀.
Àwọn ìtọ́sọnà ìṣàkóso mì ín
4.1.2.1 Kúkúru
Ìtọ́sọ́nà ìṣàkóso yìí máa wò ó tí màjẹ̀mú bá jẹ́ “òótọ” tàbí “òdo”.
Α máa ń kọ ọ́ báyìí
Nígbà tí ( májẹ̀mu = “òótọ́” )
|
4.1.2.2 Gbọọ́rọ
Pínnu nínú
|
4.2 Ìtọ́sọ́nà ìṣàkosó àtúnṣe
Ìtọ́sọ́nà ìṣàkóso ètò yìí ni a máa lò fi tún àwọn ìṣe ṣe.
Májẹ̀mu ni ìtọ́sọ́nà àtúnṣe yìí máa ń lò fi mọ́ ti a bá dá ìṣe dúro tàbí ti a bá máa ba ìṣe lọ. Nígbà ti ẹ bá máa kọ alúgórídímù yín, ẹ ro májẹ̀mu ti ẹ máa lò, bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ìṣe yín kò níí dúró títí ayérayé.
Àwọn ìṣàkóso àtúnṣe méjì ló wà:
-
Àtúnṣe “ìjáde òkè”
-
Àtúnṣe “ìjáde ìsàlẹ̀”
4.2.1 Ìtọ́sọ́nà ìṣàkóso àtúnṣe “ìjáde òkè”
Báyìí ni a ń kọ wọn
Nígbà Tí ( májẹ̀mu àtúnṣe ) = “òótọ́”| Ìtọ́sọ́nà 1| Ìtọ́sọ́nà 2| ………..| Oníyípadà “ ìtọ́sọ́nà ìṣákóso “Òpin Nígbà Tí |
4.3 Àtúnṣe “ìjáde ìsàlẹ̀”
Báyìí ni a ń kọ wọn
Túnṣe
|
4.4 Ìtọ́sọ́nà ìṣàkóso Fún
A máa ń lò ìṣàkóso Fún nígbà ti a kò bá fẹ́ lò ìṣàkóso àtúntúnṣe.
Báyìí ni a ń kọ.
Fún I kúrò ni d dé f ẹ̀sẹ̀ p Túnṣé| Ìtọ́sọ́nà
|