Àwọn ọ̀wọ́

Àwọn ọ̀wọ́ ní àwọn àfidámọ̀ àti àwọn àlàkalẹ̀. Àwọn àfidámọ̀ jẹ́ àwọn oníyípadà àwọn ohun ọ̀wọ́ ( ìsọ̀wọ́ ), nínú ọ̀wọ́ a tún máa ri àwọn ètòlẹ́sẹẹsẹ tí wọn sì jẹ́ àwọn àlàkalẹ̀ ìṣe. Fún àwọn ohun ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan àwọn àlàkalẹ̀ jẹ́ ọ̀kan náà, àmọ́ àwọn ìsọfúnni tó jẹ́ àwọn oníyípadà ló yàtọ̀.

Ìṣẹ̀dá ohun ọ̀wọ́

Láti lò ohun ọ̀wọ́ a máa ṣàlàyé oníyípadà rẹ̀.

Àpẹẹrẹ

OwoMi owo ;

Oníṣe new ni máa ń fún wa ni àǹfààní láti  ṣẹ̀dá ohun ọ̀wọ́ ( ìsọ̀wọ́ ) tí á sì so mọ́ oníyípadà kan. Α lè ṣàlàyé ìṣẹ̀dá ohun ọ̀wọ́ pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà kan.

Àpẹẹrẹ

 Ohun ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan ní oníyípadà ẹ, àmọ́ oníyípadà púpọ̀ lè tọ́ka sí ohun ọ̀wọ́ kannáà.

Àpẹẹrẹ
OwoMi owo = new  OwoMi() ;
Oníyípadà owo máa tọ́ka sí ààyè ( adírẹ́sì ) nínú ẹ̀rọ ìranti ohun ọ̀wọ́ ti a ṣẹ̀dá ẹ, àmọ́ a ò lè lò adírẹ́sì yìí fi ṣe ìṣírò bíi ti a ṣe máa ń pẹ̀lú àkójọpọ̀ C++.
Nígbà tí m2 bá jẹ́ ohun ọ̀wọ́ ỌwoMi, ìtọ́sọ́nà m2=m1 ò ṣẹ̀dá ohun ọ̀wọ́ mì-ín, ohun ọ̀wọ́ kannáà ni àwọn méjèjì ń tọ́ka sí.

Oníṣe new ni máa ń fún wa ni àǹfààní láti ṣẹ́dá ohun ọ̀wọ́ pẹ́lú àlàkalẹ olùṣẹ̀dá ohun ọ̀wọ́. New yìí ni tún máa ń pe ẹ̀rọ àfiyèmọ̀ fi ri ààyè nínú ẹ̀rọ ìranti, tí á sì pe olùṣẹ̀dá fún ìpìnlẹ̀ṣẹ̀ ohun ọ̀wọ́ yìí ní ààyè tó rí gbà, ti á sì wáa dá adírẹ́sì ààyè yìí padà.
Nígbà tí new ò bá rí ààyè nínú ẹ̀rọ ìranti, a á fi ọ̀rọ̀ àṣìṣe OutofMemmory ránṣẹ́.

Àkiyèsí
Àwọn ohun ọ̀wọ́ String :
Ìsẹ̀dá ohun ọ̀wọ́ String  máa ń wáyé ni gbogbo ìgbà tí a bá lò àsopọ̀-ìró aláìṣeyípadà, tí a ò bá ti lò ó láti ẹ̀yìn. Èyí ni máa ń sọ ìkọ ètèlẹ́sẹẹsẹ di ìrọ̀rùn.

Àpẹẹrẹ
               String isoiro = “ káàrọ̀” dọ́gba pẹ̀lú
String isoiro = new String( “káàrọ̀”)

Ìgbésí-ayé ohun ọ̀wọ́
Ohun ọ̀wọ́  kìí dágun, ìgbésí-ayé kò ní í ìbátan pẹ̀lú ìgbà ìṣiṣẹ́ ètòlẹ́sẹẹsẹ.
Ọ̀nà mẹ́ta ni ìgbésí–ayé náà pin sí :

  • Àlàyé ohun ọ̀wọ́ pẹ̀lú oníṣe new

    Àpẹẹrẹ

    orúkọ-ọ̀wọ́  orúkọ-ìsọ̀wọ́ = new orúkọ-ọ̀wọ́();

  • Ìmúlò ohun ọ̀wọ́ pẹ̀lú ìpè àwọn àlàkalẹ̀

  • Ìparẹ́ ohun ọ̀wọ́ :

    Ẹ̀rọ ìfiyèwò aládáṣiṣẹ́ ( garbage collector ) ni máa ń ṣe ìparẹ́ ẹ. Kò nídìí ki olùkọ ètò ṣe é bíi tíì C++.

Ìṣẹ̀dá àwọn ohun ọ̀wọ́ tó dọ́gba

Àpẹẹrẹ

OwoMi  m1 = new  OwoMi();
OwoMi  m2 = m1 ;

m2 àti m1, wọn kìí ṣe ohun ọ̀wọ́ méjì, orí ohun ọ̀wọ́ kannáà ni wọ́n ń tọ́ka sí.
Nígbà tí a bá fẹ́ ṣẹ̀dá ohun ọ̀wọ́ a máa lò àlàkalẹ̀ clone() ti á ṣẹ̀dá ohun ọ̀wọ́ méjì tó dọ́gba.
Àlàkalẹ̀ yìí ni a jógun láti ọ̀dọ baba ọ̀wọ́ àwọn ọ̀wọ́ gbogbo ti a ń pè ni Ọbject.

Àpẹẹrẹ

            OwoMi   m1  =  new  OwoMi( );
OwoMi  m2   =  m1.clone();

m1 àti m2 ò tọ́ka sórí ohun ọ̀wọ́ kan mọ́ tí wọ́n sì jẹ́ ohun ọ̀wọ́ méjì tó yàtọ̀.

Àwọn ìtọ́kasí àti àfiwé àwọn ohun ọ̀wọ́

Oníyípadà àfidámọ̀ ohun ọ̀wọ́, kìí ṣé ohun ọ̀wọ́, àmọ́ n tọ́ka sí í ni.
Nígbà ti a bá kọ m1=m2 ( m1 àti m2 jẹ́ ohun ọ̀wọ́ méjì ) a máa fi ìtọ́ka m2 sínú ìtọ́ka m1, àwọn méjèjì máa wáá tọ́ka sí ohun ọ̀wọ́ kannáà.
Oníṣe == ni máa ń fún wa ni àǹfààní láti ṣàfiwé àwọn ìtọ́kasí àwọn ohun ọ̀wọ́ méjì.
Àwọn ohun méjì pẹ̀lú àfidámọ̀ kannáà lè àwọn ohun ọ̀wọ́ tó yàtọ̀ sí ara wọn.

Àpẹẹrẹ

Onigun o1 = new Onigun(100,50) ;
Onigun o2 = new Onigun(100,50);

If ( r1 == r1 ) { …   } // dọ́gba
if ( r1 == r2 ) { ….   }    // àṣiṣe

Nígbà ti a bá fẹ́ ṣe àfiwé ìdọ́gba ohun ọ̀wọ̀ méjì, àlàkalẹ̀  equals tí a jó láti ọ̀dọ baba ọ̀wọ́ Objet, ni a máa lò, bẹ́ẹ́ náà ni tí a bá fẹ́ mọ̀ ohun ọ̀wọ́ Ọ̀wọ́ kan a máa lò àlàkalẹ̀ ti a jógun láti ọ̀dọ  baba ọ̀wọ́ Ọbjet getClass().

Àpẹẹrẹ

 owo1.getClass().equals(owo2.getClass()).

Ohun ọ̀wọ́ null

Α lè lò ohun ọ̀wọ́ yìí níbi gbogbo.
Ohun ọ̀wọ́ null ò jẹmọ́ ọ̀wọ́ kan, kò lè pè àlàkalẹ̀ kan, a lè lò ní ààyè ohun ọ̀wọ́ mì-ín, ọ̀wọ́ kan kò lè jógun ẹ.
Nígbà tí a bá ṣàlàyé oníyípadà tí ń tọ́ka sí ohun ọ̀wọ́ null, èyí máa jẹ́ kí “collector garbage” parẹ́ ẹ.

Àwọn oníyípadà ọ̀wọ́
Lẹ́ẹ̀kan ni a máa ṣàlàyé yàla iyé ohun ọ̀wọ́ tí a lè ṣẹ̀dá ẹ, ànìkànṣe static ni a máa lò.

Àpẹẹrẹ

Public class OwoMi() {
static int onka=0;
}

Nígbà tí oníyípadà kan, ti jẹ́ ti gbogbo ọ̀wọ́, a lè fi orúkọ ọ̀wọ́ fi parọ orúkọ ohun ọ̀wọ́.

Àpẹẹrẹ

OwoMi  o = new OwoMi();
int  t1  =  o.onka ;
int  t1  =  OwoMi.onka;

T1 àti t2 dọ́gba

Α máa ń lò àwọn oníyípadà wọ̀nyìí fi ka iyé ohun ọ̀wọ́ ti a ṣẹ̀dá wọn.

Oníyípadà this
Α máa ń lò oníyípadà yìí (this ) nínú àlàkalẹ̀ fi tọ́ka sí  ohun ọ̀wọ́ ti a bá ń lò lọ́wọ́

Àpẹẹrẹ

private int onka ;
public OwoMi ( int onka ) {
onka = onka      // oníyípadà ọ̀wọ́ jẹ́ ọ̀kannáà pẹ̀lú ààtò tí olùṣẹ̀dá fi ṣọ́wọ́ sí ètòlẹ́sẹẹsẹ.
Báyìí ni a máa kọ :
this.onka = onka ;

Αládéṣe ni ìtọ́ka sí yìí :

Àpẹẹrẹ
class OwoMi() {
String  asoporo = “oro”;
public String getΑsopo() { return asoporo }; // dọ́gba mọ́ public
getΑsopo(this.asoporo)

Α máa lò this nígbà tí ohun ọ̀wọ́ bá fẹ́ pè àlàkalẹ̀ tí á sì wá tọ́ka sí ara ẹ.

Oníṣe instanceof
Oníṣe yìí máa ń fún wa ní àǹfààní láti mọ́ ọ̀wọ́ ohun ọ̀wọ́ ti wọn fi ṣọwọ́ sí.
Báyìí ni a máa kọ :
                 ìsọwọ́ instanceof  ọ̀wọ́

void woowo ( Ọbjet o ) {
if ( o instanceof OwoMi )
System.out.println(“ o jẹ́ ìsọ̀wọ́ ọ̀wọ́  OwoMi “);

else System.out.println(“ o kìí ṣe ìsọ̀wọ́ ọ̀wọ́ OwoMi “);

}

Àmọ́ a ò lè pè àlàkalẹ̀ ọ̀wọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀wọ́ yìí nítorí pé baba ọ̀wọ̀ Objet ló fi ṣọwọ́ fun ọ̀wọ́ yìí

Àpẹẹrẹ


void  fihan(Object o) {

if (o instanceof OwoMi)

System.out.println(o.getΑsoporo());

// aṣiṣe ìkojọpọ̀ nítorí a ṣàlàyé getΑsoporo()

//nínú ọ̀wọ́ Object.

}

Fún ọ̀nà àbáyọ a máa lò ìyípadà ( casting ).

Àpẹẹrẹ

Void  fihan( Objet o ){
if (o instanceof OwoMi)

OwoMi  m = ( OwoMi ) o;

System.out.println(m.getΑsoporo());

// tàbí System.out.println( ((OwoMi) o).getΑsoporo() );

}

}

Àwọn aṣàtúntò ìlò

Wájú tàbí ẹ̀yìn àwọn ohun ọ̀wọ́ ni a máa fi sí  àmọ́ ìfẹ́nukò ń wáa kí a fi sí wáju. Α máa ń lò wọn fún àwọn ọ̀wọ́, àwọn àlàkalẹ̀, àti fún àwọn àfidámọ̀ ( oníyípadà ).

Α máa lò wọn fún ìdáàbòbò ìlò àti ìyípadà àwọn ìsọfúnni, àti fún ìjógun.
Àwọn ọ̀rọ̀ ànìkaǹṣe àláṣàtúntò mẹ́ta ni a máa fi ṣàlàyé ìrí àwọn ohun èlò ( ọ̀wọ́, àlàkalẹ̀, tàbí àfidámọ̀ ) : public, private àti protected. Α máa lò wọn fi ṣàlàyé àwọn ìdáàbòbò oríṣiríṣi.

 

Àṣàtúntò ìrí

ìwúlò

Public

( Ogunlọ́gọ̀ )

Àwọn ohun ọ̀wọ́ gbogbo lè rí àwọn oníyípadà, àwọn ọ̀wọ́ àti àwọn àlàkalẹ̀.
Inú fáìlì kan ọ̀wọ́ public kan ni a gbà làyé. Nínú ìmọ̀ye Java àfidámọ̀ kan kò níí láti jẹ́ public, àwọn àlàkalẹ̀ ni a máa lò kà wọn tàbí ṣàyìpadà wọn.

Defaut

( àkùnàyàn )

Kò sí ọ̀rọ̀ ànìkànṣe fi ṣàlàyé ìpele yìí, àwọn ọ̀wọ́ tí a kó sínú  akópọ̀ lè rí àwọn ( ọ̀wọ́, àlàkalẹ̀ àti àfidámọ̀ ).

Protected

( ìdáàbòbò )

Nígbà tí a bá ṣàlàyé ọ̀wọ́, àlàkalẹ̀ tàbí oníyípadà ní protected, àwọn àlàkalẹ̀ tó wà nínú àkópọ̀ kannáà pẹ̀lú ọ̀wọ́ náà, tàbí àwọn ọmọ rẹ̀ lè ní àǹfààní láti lò ó.
Α ò lè ṣàlàyé ọ̀wọ́ bíi protected.

private

( Ìkọ̀kọ̀ )

Ìpele ìdáàbòbò tó ga jù ni. Àwọn ohun èlò ọ̀wọ́ inú ọ̀wọ́ náà nìkan ló ní àǹfààní láti mrí ara wọn. Àwọn àlàkalẹ̀ ọ̀wọ́ náà nìkan ni a máa lò fi ṣàyípadà. Nígbà tí a bá ṣàlàyé àlàkalẹ̀ kan ni private kò lè jẹ́ private mọ́ nítorí a kò lè ṣàtúnkọ nínú àwọn ọmọ ọ̀wọ́ yìí mọ́.

Ọ̀rọ̀ ànìkànṣe static
Α máa ń lò ọ̀rọ̀ static fún àwọn àlàkalẹ̀ àti àfidámọ̀. Àwọn àfidámọ́ ohun ọ̀wọ́ jẹ́ ti rẹ̀ nìkan, Àmọ́ a lè ṣàlàyé oníyípadà tó jẹ́ ti gbogbo àwọn ohun ọ̀wọ́, gbogbo àwọn ohun ọ̀wọ́ lè lò. Inú oníyípadà yìí ni a máa ń fi ìsọfúnni adágún tàbí oníyípadà tí a fi kà iyé ohun ọ̀wọ́ ti a ṣẹ̀dá.

Àpẹẹrẹ
public class Obirikiti {
static  float pi=3.1416
float rediosi;
public Obirikiti( float rediosi ) {
this.rediosi=rediosi;
}
public agbegbe() { return rediosi*rediosi*pi; }
}

  • Àlàkalẹ̀ static ni èyí tí kìí ṣàyìpadà àwọn ohun ọ̀wọ́ àmọ́ àwọn oníyípadà ọ̀wọ́.

  • Àlàkalẹ̀ static jẹ́ èyí ti máa ṣisẹ́ sórí oníyípadà ọ̀wọ́, àmọ́ kìí sisẹ́ sórí ohun ọ̀wọ́. A lè pè wọn pẹ̀lú Ọ̀WỌ́.iṣé èyí tó jẹ́ pé ÌSỌ̀WỌ́.iṣé ni a máa lò. A lè lò àlàkalẹ̀ yìí nígbà ti a ò ṣẹ̀dá ohun ọ̀wọ́ kankan.

    Àlàkalẹ̀ ọ̀wọ̀ static ò lè pe àfidámọ̀ ohun ọ̀wọ́ tàbí kó lò ohun ọ̀wọ̀ kan.

Ọ̀rọ̀ ànìkànṣe final
Α máa ń lò ó fún àwọn oníyípadà, àlàkalẹ̀ àti ọ̀wọ́. Oníyípadà adágún  ni a ń pè ni final ètò àkójọpọ̀ kìí fiyésí bẹ́ẹ̀ sì ni kìí kọ ìyípadà rẹ̀.
Α lè ṣàlàyé oníyípadà final nínú àlàkalẹ̀. A máa ń pè àwọn adágun ni static àti final.

Àpẹẹrẹ
public static final float PI = 3.1416 ;
Α ò lè ṣàtúnkọ àlàkalẹ̀ final nínú ọmọ ọ̀wọ́.
Ètò àkójọpọ̀ máa lò àlàkalẹ̀ final bó ṣẹ yẹ nítorí ó dájú pé kò lè ní ìṣàtúnkọ.
Nígbà ti a bá lò final fún ọ̀wọ́ kan a ò tún lè ṣẹ̀dá ọmọ ọ̀wọ́ yẹn.
Fún àwọn àlàkalẹ̀ tàbí àwọn ọ̀wọ́ ìjogún ti a lò final fún, ìdáàbòbò àti ìṣiṣẹ́ tó peyé lè jáde láti ibẹ̀. Àwọn àlàkalẹ̀ tí kìí ṣe final máa ń bẹ̀rẹ̀ fún àyẹ̀wò ìtúnkọ nínú ọmọ ọ̀wọ́ nígbà ti a bá máa lò ( polymorphism ), kìí jẹ́ kí àkójọpọ̀ ètò yá.

Ọ̀rọ̀ ànìkànṣe abstract
Α máa ń lò abstract fún àwọn àlàkalẹ̀ àti àwọn ọ̀wọ́.
Αbstract ìí gbà wa láyè láti ṣẹ̀dá ohun ọ̀wọ́ ọ̀wọ́. Nínú ọ́wọ́ abstract a kìí ṣàlàyé àwọn àlàkalẹ̀ abṣtract dénú, inú ọmọ ọ̀wọ́ ni a máa ṣàlàyé ẹ tan.
Àpẹẹrẹ
Αbstract class ClassΑbstract {

             ClassΑbstractù) {  …..//kóòdù olùṣẹ̀dá }
void() { …….. // kóòdù }

abstract class OwoAbstraite {

OwoBastraite() { … //code du constructeur }

void méthode() { … // code partagé par tous les descendants}

abstract void alakaleAbstraite();

}

class OwoGbogbo extends OwoAbstraite {

OwoGbogbo() { super(); … }

void alakaleeAbstraite() { … // kóòdù }

}

Àlàkalẹ̀ àfoyèmọ̀ jẹ́ àlàkalẹ̀ àṣetúnkọ tí ń jẹ́ abstract.
Àlàkalẹ̀ yìí jẹ́ èyí ti a máa ṣàtúnkọ rẹ̀ nínú ọ̀wọ́ ọmọ. Ọmọ òwọ́ tí kò ní àlàkalẹ̀ abstract tí a ò sì ṣàlàyé àwọn àlàkalẹ̀ abstact délẹ̀ máa fún àṣiṣé ní àkópọ̀. Ọ̀wọ́ ti àlàkalẹ̀ kan jẹ́́ abstract ti jẹ́ abstract lẹ́sẹ̀kẹ́sẹ̀.

Ọ̀rọ̀ ànìkànṣe Synchronized
Α máa ń lò fún àwọn oníyípadà àti àwọn àlàkalẹ̀ ti àwon ètòlẹ́sẹẹsẹ tí ń ṣiṣẹ́ dọ́gba, àwọn Thread ( àwọn ètòlẹ́sẹẹsẹ alátòtẹ́le ).

Ọ̀rọ̀ ànìkànṣe Volatile
Àwọn oníyípadà ni a máa lò ó fún, ẹ̀rọ agbègbè mìí lè mú oníyípadà yìí lò, nínú ìdọ́gba iṣẹ́ tàbí nígbà díẹ̀. Èyí túmọ̀ sí wípé Java ò níí láti gbé pamọ sínú ẹ̀rọ ìṣiṣẹ́. Nígbà tí a bá ń lò ó a máa ń kà á, a sì tún máa ń túnkọ lẹ́sẹ̀kẹ́sẹ̀ tí ìyípadà bá dé bà á.

Ọ̀rọ̀ ànìkànṣe native
Àlàkalẹ̀ native ni èyí tó wáa láti inú ètòlẹ́sẹẹsẹ mìí. Ìlò ẹ máa ń mú ìyara bá ìṣiṣẹ́ ètò, àmọ́ ìgbòrò ètò yìí máa ń dí kù.

Àwọn ìdánimọ́ tàbí ànímọ́
Inú ànímọ́ ni àwọn ìsọfúnni ọ̀wọ́ wà, àwọn oníyípadà lè jẹ́ ohun ọ̀wọ́, oníyípadà ọ̀wọ́, tàbí adágun.
Oníyipadà ohun ọ̀wọ́
Àwọn oníyípadà ohun ọ̀wọ́ ni a máa ń ṣàlàyé nínú ọ̀wọ́.

Àpẹẹrẹ

public class OwoMi {
public int onka1;
int onka2;
protected int onka3;
private int onka4;
}

Ọmọ ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan lè lò àwọn oníyípadà rẹ̀.

Oníyípadà ọ̀wọ́
Ọ̀rọ̀ ànìkànṣe static ni a ṣàlàyé àwọn oníyípadà  wọ́nyẹn.

Àpẹẹrẹ
public class OwoMi  {
static int ounka ;
}
Gbogbo àwọn ọmọ ọ̀wọ́ ní àǹfààní láti lò oníyípadà

Àwọn àlàkalẹ̀ ọ̀wọ́
Àwọn àlàkalẹ̀ ni àwọn ìṣe tí àwọn ọmọ ọ̀wọ́ ń lò. Ọ̀nà ìṣàlàyé àwọn àlàkalẹ̀ ni :

Àṣetúntò irúfẹ́-ìyípadà orúkọ-àlàkalẹ̀ ( aato 1, aato 2, ………) { ….. }
//  àlàyé àwọn oníyípadà àti àwọn ìtọ́sọ́nà
}

Irúfẹ́-ìyípadà lè jẹ́ àwọn oníyípadà ìpìlẹ̀, tàbí ohun ọ̀wọ́, nígbà tí a ò bá dá nǹkankan padà a máa lò void.
àwọn àfidámọ̀ àti iyé ààtò tí a bá fi ṣọwọ́ láti dọ́gba pẹ̀lú èyí ti a ṣàlàyé.
kò ṣe é ṣe kí a lò àwọn ìsọfúnni àkùnà nínú àwọn ààtò. Àwọn ìsọfúnni pàápàá ni a máa fi ṣọwọ̀. Àlàkalẹ̀ mmáa dá àwọn ààtò sínú àwọn àyípadà ti rẹ̀. Nígbà tí a bá fi ohun ọ̀wọ́ fi ṣọwọ́ bíi ààtò, atọ́ka wọn ni àwọn àlàkalẹ̀ máa ń gbà, èyí tó jẹ́ àwọn ààyè wọn nínú ẹ̀rọ ìrantí tó sì jẹ́ ìdà oníyípadà. Ó ṣe é ṣe kí a ṣe ìyípadà ohun ọ̀wọ́ yìí pẹ̀lú àwọn àlàkalẹ̀ àmọ́ a lè paro atọ́ka oníyípadà tí a fi ṣọwọ́.Àwọn ìyípadà tó bá ṣẹ́lẹ̀ á jẹ́ tí iú àlàkalẹ̀ nìkan.

Àwọn ìṣàtúnṣe àwọn àlàkalẹ̀.

Àṣàtúnṣe

 

Ìwúlò

public

( Ogúnlọ́gọ̀ )

Àwọn àlàkalẹ̀ gbogbo lè lò ó

private

( Ìkọ̀kọ̀ )

Àwọn àlàkalẹ̀ ti ẹẹ̀ nìka lè lò ó

Protected

( ìdáàbòbò )

 

Àlàkalà ọ̀wọ́ àti ti àwọn ọmọ rẹ̀ lè lò ó

static

(Adágun)

 

Àlàkalẹ̀ yìí jẹ́ ti gbogbo àwọn ohun ọ̀wọ́ yìí tàbí àwọn oníyípadà adágun.a ní láti ṣẹ̀dá ohun ọ̀wọ́ ká tó lò ó. Àlàkalẹ̀ yìí ò lè lò àwọn oníyípadà ohun ọ̀wọ́ àfi àwọn oníyípadà ọ̀wọ́

synchronized
( ìṣisẹ́ pàpọ̀ )

Àlàkalẹ̀ tí inú thread ( àtòtẹ̀lé ). Nígbà tí a bá pè àlàkalẹ̀ yìí, a á dènà fún lílò ohun ọ̀wọ́, lẹ́yin ìparí iṣẹ́ rẹ̀ ohun ọ̀wọ́ lè j́ẹ́ lílò.

native

Inú ètòlẹ́sẹẹsẹ mì ín ni a tí ń kọ àwọn ìtọ́sọ́nà rẹ̀.

 

Nígbà tí a bá lò ọ̀rọ̀ àṣàtúnṣe kankan gbogbo àlàkalẹ̀ ìkójọpọ̀ ( package ) ló ní àǹfààní láti lò ó.

Ọ̀rọ̀ ànìkànṣe return ni a máa lò fi dá ìsọfúnni àbájade padà, tí sì máa ń pari ètò náà. A kìí ka àwọn ìtọ́sọ́nà tó bá tẹ̀lé kún.

Àpẹẹrẹ
int  add( int a, int b ) {
return a+b;
}

À lè lò return pẹ̀lú void, èyí tí á túmọ́ sí wípé àwọn ìtọ́sọ́nà ti dópi.

Àlàyé àlàkalẹ̀ main()
olùdári ọ̀wọ́ ni àlàkalẹ̀ yìí :
public static void main( String aaato[]) {

                                              ……………
}

Nígbà tí àlàkalẹ̀ bá dá àtẹ padà a lè lò [ ] fi kọ ọ́ báyìí :

Àpẹẹrẹ
                              int [ ] isofunni( ) { …… };
tàbí      int isofunni() { ……. };

Ìfiṣọwọ́ àwọn ààtò
Nígbà tí ìfiṣọwọ́ bá jẹ́ ohun ọ̀wọ́, kìí ṣe ohun ọ̀wọ́ ni a máa ń fi ránṣẹ́ àmọ́ ìtọ́kasí rẹ̀ ni, ti àlàkalẹ̀ ò lè yí padà, àmọ́ o lè yí ohun ọ̀wọ́ padà pẹ̀lú àlàkalẹ̀.
Nígbà tí a bá fẹ́ ṣọwọ́ àwọn ààtò sí àlàkalẹ̀ a ní láti kó wọn sínú ohun ọ̀wọ́ tó ní àwọn àlàkalẹ̀ ìyí padà wọn.
nígbà tí ohun ọ̀wọ́ kan o bá fi oníyípadà rẹ̀ kan  s fi ṣọwọ́ sí àlàkalẹ̀ kan m, nǹkan méjì ló lè ṣẹlẹ̀ :

  • Nígbà tí s bá jẹ́ àfidámọ̀ ìpìlẹ̀ ìsọfúnni ẹ ni a máa fi ránṣẹ́, kò sì ṣe é ṣe ká yípadà nínú m

  • Nígbà tí s bá jẹ́ ohun ọ̀wọ́, m lè lò àlàkalẹ̀ ohun ọ̀wọ́ tí a fi ṣọwọ́ fi ṣàyípadà ẹ.

Ìfiránṣẹ́ iṣẹ́

Ìbéèrè fún iṣẹ́
Ìbéèrè fún iṣẹ́ ni kí a béèrè kí ohun ọ̀wọ́ pè àlàkalẹ̀ fi ṣiṣẹ́, Bàyìí ni a ṣe kọ ọ́:

                            Orúkọ-ohun-ọ̀wọ́.orúkọ-àlàkalẹ̀( ààtò….. )

 

Nígbà tí àwọn àlàkalẹ̀ ò bá ní ààtò a máa fi àkamọ́ sílẹ̀ láì ní nǹkankan.

Àsopọ̀ àwọn atọ́kasí onípadà àti àlàkalẹ̀
Àpẹẹrẹ

                   System.out.println( “ Káàrọ̀ “) ;

 

Àwọn ọ̀wọ́ méjì ni a lò nínú ìtọ́sọ́nà yìí :   System àti PrintStream
Ọ̀wọ́ System ní oníyípadà out, out sì jẹ́ ohun ọ̀wọ́ PrintStream tó ní àlàkalẹ̀ println().

Àfikún àwọn àlàkalẹ̀
Àfikún àwọn àlàkalẹ̀ máa ń fún wa ni àǹfààní láti ṣàlàyé àlàkalẹ̀ tó ní orúkọ kan lọ́nà púpọ̀ pẹ̀lú iyé àti ìyàtọ̀ àwọn ààtò. Ètòlẹ́sẹẹsẹ àkójọ́pọ̀ ní máa ń lò èyí tó yẹ tí èyí sì máa mú ìrọ̀run bá àṣepọ̀ àwọn ọ̀wọ́ àti àwọn atọ́kun.

Class Igbẹjade {
public void onkaigbejade( int i ){
System.out.println( “ oùka gidi “ + i )

                        Public void onkaigbejade( float f ) {
System.out.pẹintln( “ òùnkà rere” + f);

                    }

Kò se é ṣe ká ní àlàkalẹ̀ méjì ti àwọn ààtò wọn.

Àmì àwọn àlàkalẹ̀ àti ìpàṣedà (  polymorphism )
 Ó ṣe é ṣe ká fún àwọn àlàkalẹ̀ méjì ni orúkọ kannáà àmọ́ wọn ni a máa yàtọ̀ :
àmì àlàkalẹ̀ ni orúkọ ọ̀wọ, orúkọ àlàkalẹ̀ àti irúfẹ́ àti iyé ààtò wọn.
Ìpaṣedà ( polymorphism ) ni tí ohun ọ̀wọ́ bá béèrè fún iṣẹ́ kí a lè lò àlàkalẹ̀ tó jẹmọ́ iṣẹ́ yẹn.
Ẹ̀rọ àfoyemọ̀ JVM ni máa ń ṣàkósó àwọn iṣé wọ̀nyìí.

Àwọn olùṣẹ̀dá
Lẹ́yìn àlàyé àwọn àfidámọ̀ ohun ọ̀wọ́ a máa ń lò ìṣe tí a ń pè ni olùṣẹ̀dá fi fi àwọn ìsọfúnni ìpìlẹ̀ṣẹ̀ sínú àwọn oníyípadà ohun ọ̀wọ́. A máa ń pè ìṣe yìí nígbà ti a bá máa ṣẹ́dá ohun ọ̀wọ́ kan.
àlàkalẹ̀ yìí máa ń ṣiṣẹ́ bíi àwọn èyí tó kù ṣùgbọ́n kò ní àfidámọ̀ ìyípadà bẹ́ẹ́ náà ni kò sì tún ní ọ̀rọ̀ ànìkànṣe return, a lè ṣàlàyé olùṣẹ̀dé méjì tàbí jù bẹ́ẹ́ lọ. Α lè má ṣàlàyé olùṣẹ̀dá, nígbà yẹn JVM a lò olùṣẹ̀dá àkùnàyàn tí kò níí nǹkakan nínú. Èyí ò níí wáyé tí olùkétò bá ti ṣàlàyé olùṣẹ̀dá.

  • Olùṣẹ̀dá ìrọ̀rùn
    Orúkọ olùṣẹ̀dá yìí máa ń jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú orúkọ ọ̀wọ́.

Àpẹẹrẹ
public OwoMi() { …};

  • Àlàyé pẹ̀lú ìsọfúnni adágún

Àpẹẹrẹ
public OwoMi( int iye ) {
onka = 5;
}

  • Àlàyé pẹ̀lú àwon ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ìsọfúnni a máa lè fi àwọn ìsọfúnni ṣọwọ́ sí olùṣẹ̀dá.

Àpẹẹrẹ
public OwoMi( int iye ) {
onka = iye;
}

Olùmúkúrò
Α kìí lò nínú Java

Àwọn alásopọ̀
Àkójọpọ̀ àwọn ìsọfúnni àti àwọn àlakalẹ̀ máa ń jẹ́ ká dáàbò bó àwọn ohun èlò ọ̀wọ́. Èyí ni a ń pè ni ìdè ( encapsulation ). Àlàkalẹ̀ tí kò sí nínú ọ̀wọ́ ò lè lò àwọn ìsọfúnni wọ̀nyìí láláì lò àwọn àlàkalẹ̀ abẹ́nu ti a ń pè ni alásopọ̀. Àfẹ́nukò máa jẹ́ kí àwọn alásopọ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú get fún kíkà àti set fun kíkọ.
Àpẹẹrẹ
private int onka = 13;
public int  getOnka() {
return(onka);
}

                             Public  void SetOnka( int onk ) {
onka = onk;
}

Ìjógún

Ìjógun máa ń fún wa ni àǹfààní láti tún àwọn ìsọfúnni àti àwọn àĺàkalẹ̀ ọ̀wọ́ lò pẹ̀lú ìdàgbasókè ẹ.
Pẹ́lú ìjógún àwọn ohun ọ̀wọ́ kan lè lò àwọn ìsọfúnni àti àwọn àlàkalẹ̀ baba ọ̀wọ́. ọmọ ọ̀wọ́ lè ṣe ìdàgbàsókè baba ọ̀wọ́. ọmọ ọ̀wọ́ lè ṣàtúnkọ àwọn àlàkalẹ̀ baba ọ̀wọ́, a kìí parọ orúkọ àwọn àlàkalẹ̀, àwọn àfidámọ̀ àti àwọn ààtò baba ọ̀wọ́.
Àwọn ọ̀wọ́ lè máa jógún ara wọn láti okè dé ilẹ̀. Nọ̀wọ́ tyí wọ́n jógún ni baba ọ̀wọ́, ọ̀wọ́ tó jógún ni ọ̀wọ́ abẹ́. Ọ́wọ́ kan lè ní àwọn ọ̀wọ́ abẹ́ púpọ̀, àmọ́ baba ọ̀wọ́ kan ni ó lè ní. Kò síí ìjógún lọ́nà púpọ̀ nínú Java.
Ọ̀wọ́ Objet ni baba ọ̀wọ́ ti gbogbo ọ̀wọ́ Java. Àwọn ìsọfúnni àti àwọn àlàkalẹ̀ Object ni gbogbo àwọn ọ̀wọ́ Java lò.

Ìlò Ìjógún
Ọ̀rọ ànìkànṣe extends ni a máa lò fún ìjógún. Nígbà tí extends kò bá sí nínú ọ̀wọ́, ọ̀wọ́ Object ni á jẹ́ baba ọ̀wọ́ náà fún ètò àkójọpọ̀.
Nígbà tí a bá fẹ́ lò àlàkalẹ̀ ọ̀wọ́ baba a máa fi super síwájú ẹ, nígbà tí a bá lò olùṣẹ̀dá  ọ̀wọ́ baba ọ̀wọ́ a máa kọ super( ààtò ) pẹ̀lú àwọn ààtò tó yẹ.
Java ni máa ń ṣàkósó ìbàtan tó wà láàrin ọ̀wọ́ ọmọ àti ti baba rẹ̀.

Àpẹẹrẹ
class Omo extends Baba { …. };
Pẹ̀lú Java ọmọ ọ̀wọ́ ní láti lò olùṣẹ̀dá baba.

Ìlò àwọn ohun ìjógún
Àwọn oníyípadà àti àwọn àlàkalẹ̀ public ( ogúnlọ́gọ̀ ) máa wà bẹ́ẹ̀, àmọ́ a ní láti lò àwọn àlàkalẹ̀ tí a jogún fi lò ó.
Tí a bá fẹ́ ní ìdábòbò àwọn oníyípadà tí a ṣàlàyé ni private ( ìkọ̀kọ̀ ) nínú àwọn ọmọ ọ̀wọ́ a máa yí àlàyé pẹivate sí protected ( àábò ).
Ìyípadà.

Ìpàpòdà láti ara ìjogún  máa sọ ìdáṣepadà ( polymorphism ) di ìrọ̀rùn

 

Ìjógun máa ń ṣàlàyé àdáṣé ìyípadà àfidámọ̀tí ọmọ di tí baba:
Α lè fi ìtọ́kasí ohun ọ̀wọ́ ọmọ sínú ìtọ́kasí ohun ọ̀wọ́ baba.

Àpẹẹrẹ : Ọ̀wọ́ Omose jogún ọ̀wọ́ Eeyan

Eeyan e = new Eeyan( “Yemi”, “Αde”);

Omose o =  new Omose( “Αbiodun”, “Tope”);

e = o ;
Objet obj;
obj = o;

Ó ṣe é ṣe kí a kọ ìtọ́sọ́nà yìí tí Omose bá jogún Eeyan.

Àpẹẹrẹ
Personne[]  tab = new Personne[10]
tab[0] = new Personne ( <Dupond>, < Jean> )
tab[1] = new Employe (<Durant>, <Julien>, <1000> )

Α lè ṣe àfikún àlàkalẹ̀ tí a jogún àwọn ààtò ni á fun wa àǹfààní láti mọ̀ èyí ti a máa lò.

Àtúnkọ àlàyé àlàkalẹ̀ tí a jogún
Ọ̀wọ́ lè jógún àwọn ọ̀wọ́ púpọ̀, àmọ́ Java ò fààyè gbà á, àwọn atọ́kun ni a máa lò.
Αtókun
( interface ) ní àwọn oníyípadà adágun àti àwọn àlàkalẹ̀ tó dàbí ti ọ̀wọ́ àfiyèmọ̀.
Αtọ́kun dàbí àwòṣe ti ọ̀wọ́ lè múlò.
Gbogbo ọ̀wọ́ tó bá gbà láti múlò láti ní àwọn àlàkalẹ̀ àti àwọn oníyípadà tí a ṣàlàyé sínú atọ́kun ( interface ) àwọn ọ̀wọ́ lè lò atọ́kun púpọ̀.
Àlàyé àwọn atọ́kun máa ń lò ọ̀rọ̀ ànìkànṣe interface tí a sì máa lò ó nínú àwọn ọ̀wọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ànìkànṣe implements.
Αtọ́kun ní àdáṣe àlàyé pẹ̀lú àfidámọ̀ àtúnṣe abstract.

Àlàyé àwọn atọ́kun

               Public interface orúkọ-atọ́kun [ extends orúkọ-atọ́kun1, orúkọ-atọ́kun2, ……] {

                         // àwọn ìtọ́sọ́nà, àwọn ìsọfúnni…….
}

Ìmúlò atọ́kun

 

Àṣàtúntò class OwoMi [ extends baba Ọ̀wọ́ ] [ implements orúkọ-atokun1, orúkọ-atokun2, …] {   // àwọn ìtọ́sọ́nà  }

Àpẹẹrẹ
interface Αfihan {
void Αfihan() ;
}
classe Eeyan Implements Αfihan {
public void afihan() {
System.out.println( “ Èèyan ni mi “);
}
}

                   Class Moto implements Αfihan {
public  void afihan() {
System.out.println( “ Moto ni mi “);
}
}
Àpẹẹrẹ :

Αtọ́kun  ti gbogbo ti gbogbo èèyàn máa ń múlò.

                             Interface  Eeyan  {
String getOruko();
String getOruko();
Date  getOjobi();
}

Gbogbo àwọn àlàkalẹ̀ atọ́kun jẹ́ ti ogúnlọ́gọ ( public ) àti àfòyèmọ̀( abstact ). Àdáṣe àlàyé wọn ni abstract, atọ́kun lè jẹ́ ti ogúnlọ́gọ tàbí ti àkópọ̀ ( package ).
Nígbà tí atọ́kun bá jẹ́ ti gbogbogbò, gbogbo àwọn àlàkalẹ̀ rẹ̀ pàápàá máa jẹ́ ti ogúnlọ́gọ ti a bá tíẹ̀ ṣàlàyé bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ti ìlò ẹ bá jẹ́ ti package, èyí tó túmọ̀ sí pé atọ́kun àwọn ọ̀wọ́ ni, àwọn àlàkalẹ̀ ṣílẹ̀ fún àwọn ọ̀wọ́ package.
Àwọn oníyípadà adágunti wọ́n jẹ́ oníyípadà ọ̀wọ́. Àdáṣe àlàyé wọn ni ìṣàtúntò final àti static.
gbogbo àwọn ọ̀wọ́ tó bá máa múlò ní láti ní àlàkalẹ̀ ti a ṣàlàyé ẹ sínú atọ́kun ( interface )

Nígbà tí atọ́kun ni kó fún wa ni atọ́kun àwọn àlàkalẹ̀ ti a máa ṣàlàyé nínú ọ̀wọ́ tó máa múlò  ni ọ̀nà ìmúlò.
Àwọn àlàkalẹ̀ tí a ṣàlàyé pẹ̀lú ìṣàtúnṣe public nínú atọ́kun public jẹ́ public ti gbogbo àwọn ọ̀wọ́ tó béèrè láti ṣàmúlò ẹ máa jogun àwọn àlàkalẹ̀ náà, àwọn ọ̀wọ́ wọ̀nyìí láti jẹ́ àwọn èyí tó lè ṣẹ̀dá ohun ọ̀wọ́; wọ́n sì ní láti ṣàlàyé gbogbo àwọn àlàkalẹ̀ atọ́kun.
Ọ̀wọ́ kan lè ṣàmúlò atọ́kun púpọ̀ tí á sì jogún ọ̀wọ́ baba rẹ̀. Ìmúlò atọ́kun máa ṣàlàyé ìyípadà ìmúlò atọ́kun dàbí ìjogún ni.
Ìmúlò atọ́kun máa ṣàlàyé àṣàtúnṣe ( cast ). Ìmúlò atọ́kun máa ń dàbí ìjogún.

Ìmọ̀ràn sórí ìjógún
Nígbà tí a bá ṣẹ̀dá baba ọ̀wọ́ a máa ṣàkíyèsí àwọn nǹkan wọ̀nyìí :

  • Ìṣàtúnṣe àwọn oníyípadà ti máa ń sàbá jẹ́ ìkọkọ ( private ) láti jẹ́ ti ìdáàbòbò ( protected )

  • Nígbà tí a ò bá fẹ́ kí àwọn àlàkalẹ̀ wa ní ìṣàtúnkọ a ní láti lò ìṣàtúntò final.

     

 

Akim Agueh
Author: Akim Agueh

Compte