Java Akójọpọ̀                              Java Compiler                        Java Compilateur

Orí 1

I Ìbẹ̀rẹ̀

Java jẹ́ ètòlẹ́sẹẹsẹ alákójọpọ̀ ti máa ń fún wa ni àǹfààní láti kọ ohun èlò ètò oríṣiríṣi, ó sì tún jẹ́ ètò alákójọpọ̀ tó tẹ̀ síwájú. Ọ̀nà méjì ni a ń fi kọ ohun èlò kọ́ńpútà  pẹ̀lú Java : Ọ̀nà Αpplet àti ohun èlò ayára bíi àṣá adádúró :
– Αpplet jẹ́ ohun èlò kọ́ńpútà ti máa ń ṣiṣẹ́ lórí aṣàwákiri íńtánẹ́ẹ̀tì.
– Ohun èlò kọ́ńpútà adádúró máa ń ṣiṣẹ́ lorí ayára bíi àṣá.

II Àwọn ìlànà ìpìlẹ̀

Tí a bá máa kọ àwọn  ètò wa pẹ̀lú  Java,  a máa kọ ìtọ́sọ́nà sórí ìpele kọ̀ọ̀kan, a sì máa pari ìpele náà pẹ̀lú àmì agbọ́nrìn.
Àmọ́ a tún lè kọ ìtọ́sọ́nà kan sórí ìpele mélòó kan.

Àpẹẹrẹ :

char
kodu
=
“D”

Ẹ máa gbìyànjú láti fi àyè sílẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìpele, kí ẹ lè nírọ̀rùn láti kà á.

1) Àwọn àfidámọ̀

Àwọn ọ̀wọ́, ohun ọ̀wọ́, ètò, àti àwọn oníyípadà máa ń ní orúkọ; a máa ń kọ́ wọn pẹ̀lú àwọn ìró, àwọn lẹ́tà

Irúfẹ́  ìríwí

Àpẹẹrẹ

Ìríwí kúkúrú

// ìríwí sórí ìpele kan

Int n=1 // àlàyé òǹkà

Ìríwí sórí ìpele mélòó kan

/*  ìríwí ìpele 1

Ìríwí ìpele 2

*/

Ìríwí àkọsílẹ̀ àdáṣiṣẹ́

/**   ìríwí

**/

2) Àlàyé àti ìlò oníyípadà

Oníyípadà máa ń ní orúkọ, àti irú ìsọfúnni ti à lè lò ó fún, Oníyípadà máa wúlò nínú àkópọ̀ ìṣe ;  tí a bá jáde kùrò nínú ìkójọ oníyípadà kò tún ṣiṣẹ́ mọ̀.

Àlàyé oníyípadà túmọ̀ si ìgbààyè fún un nínú ẹ̀rọ ìránti.

3) Àwọn irúfẹ́ oníyípadà;

Àpẹẹrẹ

long onka ;

Àwon orúkọ oníyípadà lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú lẹ́tà, àmì ìṣàmí ìsàlẹ̀ tàbí àmì dọ́la, àwọn ìró tó kù lè jẹ lẹ́tà, òǹkà àmọ́ kò lè jẹ àlàfo.

Ó ṣeé ṣe kí a ṣàlàyé oníyípadà mélòó kan lórí ìpele kannáà, àmọ́ a máa là wọn pẹ̀lú àmì ìdánudúro díẹ̀.

Àpẹẹrẹ :

int ijo, osu, odun ;
Java jé ètò àkójọpọ̀ líle tí kìí yí ìyípadà kan sí omìí tí á bá fà wàhálà. Fún àwọn ọ̀wọ́ ẹ ní láti ṣàlàyé wọn kí ẹ tó ṣẹ̀dá wọn. Ẹ ní láti tọ́jú ààyè nínú ẹ̀rọ ìránti fún ìṣẹ̀dá ọ̀wọ́  ( Àkíyèsí : ọ̀wọ́ ni àtẹ jẹ́ fún Java ) pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà new. Java ní ẹ̀rọ àdáṣé tí a ń pè ni “garbage collector” fún ìtúsílẹ̀ àwọn ààyè tí a ti lò.

Àpẹẹrẹ

Owomi ohun ;
ohun = new Owomi();
tàbí
Owomi ohun = new Owomi();

int[]  onka  = new int[10] ;

Ó ṣeé ṣe kí a ṣàlàyé oníyípadà kí a sì tún fi ìsọfúnni sínú ẹ.

4) Àwọn ìgúnrege àwọn oníyípadà ìpìlẹ̀

a)  Ìrúfẹ́ àwọn òùnkà rere
A lè kọ àwọn byte, short, int àti long pẹ̀lú òǹkà ẹlẹ́mẹ́wa, ẹlẹ́mẹ́rìndínlógùn, ẹlẹ́mẹ́jọ, ẹlẹ́gun.

Fún àwọn ẹlẹ́mẹ́wa, a máa fi àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ sí wájú.
Fún àwọn ẹlẹ́mẹ́jọ òùnkà wa  á bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òdo, àwọn àfòmọ́ ìparí máa jẹ́ l tàbí L, kí a fi mọ́ tó bá jẹ́ òùnkà long ni.

b) Irúfẹ́ àwọn òùnkà gidi

Àwọn float àti double máa ń gbà òùnkà oní àmì ojú aléfòó. Afidámọ̀ wọn ni àmì ojú tàbí kí wọ́n ní òùnkà alágbára, tàbí àwọn àfòmọ́ ìparí f F d D, a lè ṣàlàyé iyé òùnkà tó wà lẹ́yìn àmì ojú.

Àpẹẹrẹ

float  pi = 3.14f

double v = 3d

float f = +.1f, d=1e10f

5) Irúfẹ́ àwọn lẹ́tà tàbí ìró mìnín

Bíìtì 16 ní a ń fi kọ àfidámọ̀ lẹ́tà tàbí àwọn ìró mìn-ín nínú òfin Unicode 8. Α ní láti kọ ọ́ sàárin àmì àyọlò. Α lè kọ ìró pẹ̀lú òùnkà tó wà láàrin 0 pẹ̀lú 65535.

Àpẹẹrẹ

Class idanwo {
public static void  main ( String  args[] ) {

Char code = ‘D’;
int index = code – ‘Α’;

System.out.println( “ index = “ + index ) ;
}
}

6) Àwọn oníyípadà ìpìlẹ̀

Àpẹẹrẹ

int  onka ;                 //   àláyé
onka = 100 ;            //    ìpìnlẹ̀
tàbí
int onka = 100 ;        //  àlàyé àti ìpìnlẹ̀ṣẹ̀

Nínú àkójọpọ̀ Java àwọn oníyípadà ọ̀wọ́ ( Tó jẹ àfidámọ̀ ọ̀wọ́ ) máa ń ní ìsọfúnni àkùnàyàn tó somọ́ irúfẹ́ ìsọfúnni yìí nígbà ti a ṣẹ̀dá rẹ̀. Àmọ́ ìpìlẹ̀ṣẹ̀ àwọn oníyípadà yìí kò somọ́ àwọn oníyípadà àwọn ìṣe ìsọ̀wọ́.

Àwọn àkùnàyà ìsọfúnni oníyípadà lẹ́yìn ti a bá ṣẹ̀dá wọn

Àwọn àkùnàyà ìsọfúnni oníyípadà lẹ́yìn ti a bá ṣẹ̀dá wọn

Àwọn àfidámọ̀

Àkùnàyà ìsọfúnni

Boolean

false

 byte, short, int, long

0

float, double

0.0

Char

\u000

7) Ìfi sí

Àwọn oníṣe kan wà tí wọ́n jẹ́ ìsọ̀dìrọ̀rùn fún ìkọ ọ̀rọ̀ ìfi sí :

Oníṣe

Àpẹẹrẹ

Àlàyé ìtúmọ̀

=

a=10

ìtúmọ̀ rẹ : a = 10

+=

A+=10

ìtúmọ̀ rẹ : a = a + 10

−=

a−=

ìtúmọ̀ rẹ : a = a − 10

*=

A*=

ìtúmọ̀ rẹ : a = a * 10

/=

a/=10

ìtúmọ̀ rẹ : a = a / 10

%=

A%=10

Òpin pìpín

^=

a^=10

ìtúmọ̀ rẹ̀ : a = a ^ 10

<<=

A<<=10

ìtúmọ̀ rẹ̀ : a = a << 10 àfikun òdo ni apá ọ̀tún a

>>=

a>>=10

ìtúmọ̀ rẹ̀: a = a >> 10 àfikun òdo ni apá òsì a

>>>=

a>>>=10

 ìtúmọ̀ rẹ̀: a = a >>> 10 ìgbésósì ni àìní àmì

 7) Àfiwé

Oníṣe

Àpẹẹrẹ

Àlàyé ìtúmọ̀

>

a > 10

 ju lọ

<

a < 10

kéré sí

>=

a >= 10

ju lọ pẹ̀lú dọ́gba

<=

a <= 10

kéré sí pẹ̀lú dọ́gba

==

a == 10

dọ́gba

!=

a != 10

yàtọ̀ sí

&

a & b

PẸ̀LÚ alákóméjì

^

a ^ b

TÀBÍ alákóméjì àìdéú

|

a | b

TÀBÍ alákóméjì

&&

a && b

PẸ̀LÚ  ọgbọ́n (Fún àwọn ọ̀rọ̀ abèjì ) : ìgbélẹ́wọn ọ̀rọ̀ á dúró  nígbà tí kó bá jẹ́ òótọ́ mọ́

||

a || b

TÀBÍ ọgbọ́n (Fún àwọn ọ̀rọ̀ abèjì) : : ìgbélẹ́wọn ọ̀rọ̀ á dúró  nígbà tí ó bá jẹ́ òótọ́

? :

a ? b : c

Oníṣe ajẹmọ́-kání

Α máa n lò àwọn oníṣe fún àwọn ohun ìṣírò, a máa bẹ̀rẹ̀ láti òsì dé ọ̀tún, à sì tún máa lò àwọn agbára oníṣe láti òkè dé ìsàlẹ̀

  • Ìlọsókè àti ìlọ́sílẹ̀

  • Ìlọ́po, ìpín àti òpin ( module )

  • Àfikún

  • Àfíwé

  • Àmì = fún ìfi sí

Α máa lò àwọn àkámọ́ apá ọ̀tún àti ti òsì fi ní àǹfàànì láti kọ́kọ́ ṣé ìṣírò àwọn ohun tó wà láàrin wọn.

III Ìṣírò àwọn òùnkà

1) Ìṣírò àwọn òùnkà gidi

Fún àwọn òùnkà gidi , Java máa ń lò àdáṣe àyípadà àwọn òùnkà gidi sí int, ti a máa dá ààbò bó àwọn ìtọ́sọ́nà ; èyí tó túmọ̀ sí ìgbéga int.

Àpẹẹrẹ
short y = 5, t = 15;
y = y + t; // àṣìṣe ní àkójọpọ̀

Incompatible type for =. Explicit cast needed to convert int to short.
y = y + t ; // àṣìṣe àkójọpọ̀

^

1 error

Àwọn òùnkà  pẹ̀́lú ìbájade ni oníṣe máa yípadà sí int, àbájáde ni a máa gbé sínú short, èyí tí a máa fà àṣìṣe alákójọpọ̀, ìgbéga int tó ti fún wa ni àǹfààní láti yí  y àti t sí int ló fà àṣìkọ yìí tí tí kò hàn sí olùkọ́ ètò.
ƒi dójúkọ ìṣòrò yìí,  a máa ń lò olùyípadà ti a ń pe ni cast

Àpẹẹrẹ
 y= (short) ( y + t ) ;
Α ní láti gbé oníṣe sí àárin àwọn àmì àkámọ́ kí a fi ní àǹfààní láti yí abájáde ìṣe yìí pẹ̀lú olùyípadà cast tó ní agbára jú oníṣe lọ.

Ìpín lọ́nà òdo àwọn òùnkà gidi máa ń pe ètò àṣìṣe ΑrithmeticExeption. 

Àpẹẹrẹ
class Igbeyewo {
public static void main( String args[] ) {

int onka = 10;
double abajade = onka/0 ;

System.out.println( “ òunkà = “ + abajade );

}

}

2) Ìṣírò àwọn òùnkà àmì ojú aléfòó

Pẹ̀lú àwọn òùnkà float tàbí double, ìpín lọ́nà òdo kìí dá ètòlẹ́sẹẹsẹ dúró, àwọn abájáde wọn   Ní í :

  • Àìlópìn Float.NaN tàbí Double.NaN ( kìí ṣe nọ́mba ).

  • Àìlópin rere : Float.NEGΑTIVE_INFINITY tàbí Double.POSITIVE_INFINITY +∞

  • Àìlópin àlòdi : Float.NEGΑTIVE_INFINITY tàbí Double.NEGΑTIF_INFINITY +∞

Ní abẹ́ òfin IEEE754, àwọn òùnkà  àjèjì mònyìí ni abájáde  ìṣírò àìṣedééde NaN, òùnkà tó jú àláìlopin rere àti alòdì.

Y

T

Y/T

Y%T

Òùnkà dájú dájú

0

+∞

NaN

Òùnkà dájú dájú

+/- ∞

0

T

0

0

NaN

NaN

+/- ∞

Òùkà dájú dájú

+/- ∞

NaN

+/- ∞

+/- ∞

NaN

NaN

3) Ìlọsókè àti ìlọsílẹ̀

Àwọn oníṣe ìlọsókè àti ìlọsílẹ̀ ni n++,  ++n, n–,  –n.
Tí oníṣe bá ṣúwájú oníyípadà, ìyípadà rẹ̀ á wáyé lẹ́sẹ̀kẹ́sẹ̀ bí kò jẹ bẹ́ẹ̀ ìyípadà á wáyé lẹ́yìn ìṣe ìtọ́sọ́nà. Oníṣe ++ máa ń jẹ́ kí ìlọsókè t wáyé ti o bá wà ní wájú bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn ìlọsílẹ̀ a máa ní ìwárí yìí.

Àpẹẹrẹ

System.out.println(y++) ; // dọ́gba mọ́
System.out.println(y) ; y=y+1 ;
System.out.println(++y) ; y=y+1 ; // dọ́gba mọ́
y=y+1 System.out.println(y);

 4) Ètò agbára àwọn oníṣe

 Java ṣàlàyé àwọn agbára oníṣe sórí àtẹ yìí ( kúrò ni agbára ńlá dé kékere ).

Àwọn Àkámọ́

( )

Àwọn oníṣe ìlọsókè-ìlọsílẹ̀

++

Àwọn oníṣe ìlọ́po, ìpín, àti òpin ( modulo)

*
/
%

Àwọn oníṣe àfikún, ìyọkúrò

+

Àwọn oníṣe ìgbésósì-ìgbésọ́tun

<<
>>

Àwọn oníṣe àfíwé

<
>
<=
>=

Àwọn oníṣe ìdọ́gba

=
!=

Oníṣe TÀBÍ ìyàsọtọ̀

ˆ

Oníṣe PẸ̀LÚ

& 

Oníṣe TÀBÍ

|

Oníṣe PẸ̀LÚ ọgbọ́n

&&

Oníṣe TÀBÍ ọgbọ́n

|| 

Oníṣe oní ìfi sí

=
+=
-=

Àmì àkámọ́ jẹ́ àmì tó ní agbára jù, a lè lò ó fi ṣàtúntò àwọn ohun ìṣírò.

IV Àwọn ìtọ́sọ́nà ìdarí ètòlẹ́sẹẹsẹ

1) Àwọn ṣetúnṣe

While (  àkóméjì )                                                ṣetúnṣe ( àkóméjì )
{                                                                               {
// Àwọn ìtọ́sọ́nà                                                   // Àwọn ìtọ́sọ́nà

}                                                                              }

Nígbà tí àkóméjì yìí bá ti lè jẹ́ òótọ́ àwọn iṣé ìtọ́sọ́nà kòó níí dúró. Àmọ́ tí àkóméjì kòó bá tí jẹ́ òótọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn iṣé ìtọ́sọ́nà kòó níí wáyé láé.

Ẹ má fi àmì agbọ̀nrin sí ẹ̀yin àkóméjì, bí kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ ìṣetúnṣe kòó níí wáyé láé.

do {                                                                           ṣe    {
// Àwọn ìtọ́sọ́nà                                                   // Àwọn ìtọ́sọ́nà

}   While (  àkóméjì )                                              }  ṣetúnṣe ( àkóméjì )

for ( ìpilẹ̀ṣẹ̀ ; ajẹmọ́-kání , ìyípadà ) {

}

fún ( ìpilẹ̀ṣẹ̀ ; ajẹmọ́-kání , ìyípadà ) {

}

Àpẹẹrẹ

for (i = 0 ; i < 10; i++ ) { ….}

for (int i = 0 ; i < 10; i++ ) { ….}

for ( ; ; ) { … }           // ìṣetúnṣe àìdúró

A lè lò àwọn ìpinlẹ̀ṣẹ̀, ìyípadà àti atọ́ka sí lọ́nà tó wù wa.
Nínú ìpìnlẹ̀ṣẹ̀, a lè ṣàlàyé oníyípadà ti á jẹ́ atọ́ka sí abẹ̀lé nínú ìṣetúnṣe yìí.

ó ṣeé ṣe kí a fi àwọn ìtọ́sọ́nà sínú ìpìlẹ̀ṣẹ̀ àti ìyípadà ti ìṣetúnṣe yìí, a máa fi àmì àgbọ̀nrìn sí ẹ̀yìn ìtọ́sọ́nà kọ̀ọ̀kan.

Àpẹẹrẹ

For ( i=0, j=0 ; i*j<1000; i++,j+=2) { … }

Αjẹmọ́-kání lè má wà lórí atọ́ka sí ìṣetúnṣe.

Àpẹẹrẹ

boolean rii = false;
for ( int i=0; !rii; i++ ) {
if ( ate[i] == 1)
rii = true ;
…………. //   ìlò fún ìṣàwákiri òpin àtẹ

}
Ó ṣeé ṣe kí a fún ìṣetúnṣe ni orúkọ, tí á fún wa ni àǹfààní láti lè fópìn si í. Àmọ́ a ò níí gbàyín ní ìmọ̀ràn yẹn.

Àpẹẹrẹ

int onioka = 0;
boucle:
while (onioka < 100) {
for(int oka = 0 ; oka < 10 ; oka ++) {
onioka += oka;
System.out.println(“onioka = “+onioka);
if (onioka> 40) break boucle;
}
}

2) Àwọn ìsomọ́ ajẹmọ́-kání

if (boolean) {                                                                            ( àkóméjì ) {
………….


} else if (boolean) {                                                             bí kò jẹ bẹ́ẹ̀ bí ( àkóméjì ) {
………….                                                                        ………….

…                                                                                            …
} else {                                                                                   }    bí kò jẹ bẹ̀ẹ̀ {
………..                                                                           ………..

Pẹ̀lú àwọn oníyípadà irúfẹ́ èyí ti ìwọ̀n wọn kére tí kò jù bíìtì 32 ( byte, short, int, char ).
Tí ìtọ́sọ́nà bó bá jẹ́ ò níí ìtọ́sọ́nà jáde àwọn èyí tó tẹ́lè ni á kàn sí.
ó ṣeé ṣe kí a kì àwọn switch bọ inú ara wọn.

swith (ọ̀rọ̀ ajẹmọ́-kání) {                                                       ṣèpapòda ( ọ̀rọ̀ ajẹmọ́-kání ){
case lemolemo1 :                                                                    bó bá jẹ́ lemolemo 1 :
ìtọ́sọ́nà 1;                                                                                 ìtọ́sọ́nà 1;
ìtọ́sọ́nà 2;                                                                                 ìtọ́sọ́nà 2;

……                                                                                         ……

break;                                                                                       jáde;

case lemolemo 2 :                                                                    bó bá jẹ́ lemolemo 2 :
…                                                                                               …

default :                                                                                    àìyégé :
…                                                                                                …
}                                                                                              }

Α lè lò ṣèpapòdà pẹ̀lú àwọn oníyípadà irúfẹ́ èyí ti ìwọ̀n wọn kére tí kò jù
bíìtì 32 ( byte, short, int, char ).
Tí àwọn ìtọ́sọ́nà bó bá jẹ́ ò bá níí jáde àwọn ìtọ́sọ́nà tó tẹ́lè ni a máa lò.
Ó ṣeé ṣe kí a kì àwọn switch bọ̀ inú ara wọn.

Oníṣe onímẹ́ta ( ajẹmó-kání ) ? isofunni-ooto : isofunni-odi.

Àpẹẹrẹ

if (ipele == 5)      //  à total = (niveau ==5) ? 10 : 5;
gbogbo = 10;
else gbogbo = 5 ;
System.out.println((isori == « E ») ? « OK » : « OB »);

break  máa ń jẹ́ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ jáde kúrò nínú ìṣetúnṣe tàbí ìsopọ̀

continue : a máa ń lò fi kúrò nínú ìṣetúnṣe kan fi bẹ̀rẹ̀ omìí tó tẹ̀lé.
Α lè lò break àti continue pẹ̀lú àkọlé.
Ó ṣeé ṣe kí a lò àkọlé fi ṣàmì sí ibi tí ètòlẹ́sẹẹsẹ máa padà sí lẹ́yìn tí a bá lò àwọn ìtọ́sọ́nà break àti continue.
Àkọlé ni orúkọ tí a kọ ojú àmì méjì sẹ́yìn rẹ̀.

V Àwọn àtẹ ìsọ́fúnni

Àwọn àtẹ jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ọwọ baba ọ̀wọ́ Object : Àwọn àlàkalẹ̀ ọwọ Object ni a máa lò fún wọn, bíi equals() tàbí getClass(). Αtọ́ka ìsọfúnni àkọ́kọ́ máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú odò ( 0 ) !

1) Àlàyé àwọn àtẹ
Pẹ̀lú Java a máa ń àwọn àkámọ́ olópòó síwájú àti sẹ́yìn orúkọ àtẹ nínú àlàyé.

Àpẹẹrẹ

int ate[]= new int[];     tàbí
int[] ate = new int[50];  tàbí
int ateb[];     // ìríwí
ateb = new int[50];

Java ò fàyè gbà àlàyé àtẹ oní òpó púpọ̀ : a ní láti ṣàlàyé àtẹ nínú àlàyé àtẹ.

Àpẹẹrẹ

float tableau[][] = new float[10][10];

Àwọn ẹ̀kà àtẹ kèjì má lè jẹ́ ọ̀kannáà láàrin ara wọn.

Àpẹẹrẹ

int dim1[][] = new int[3][];

dim1[0] = new int[4];

dim1[1] = new int[9];

dim1[2] = new int[2];

Àlàyé àwọn àtẹ ní kedere Àpẹẹrẹ

int ate[5] = {10,20,30,40,50};

int ate[3][2] = {{5,1},{6,2},{7,3}};

Tí a bá ṣàlàyé àtẹ ní ìbẹ̀rẹ̀, a lè máa kọ ìwọ̀n ẹ.

Àpẹẹrẹ

int igba[] = {10,20,30,40,50};

Àwọn iyé ìsọfúnni àtẹ lórí àwọn ìlà lè màa dọ́gba

Àpẹẹrẹ

int[][] ateonka = {{1,2,3,4,5,6},

{1,2,3,4},

{1,2,3,4,5,6,7,8,9}};

Ìṣàwákiri nínú àtẹ

Àpẹẹrẹ
for (int i = 0; i < ate.length ; i ++) { … }

Oníyípadà lenght máa ń dá iyé ìsọfúnni àtẹ padà.

Kí iṣé tó lè lò àtẹ,  a máa sọ àyè tó wà fún nítorí pé a máa ń lò àtẹ bíi ohun ọ̀wọ́ ni.

Àpẹẹrẹ

public void printArray(String texte[]){ …

}

Tí a bá fẹ́ lò àtẹ pẹ̀lú ìwọ̀n tó jù agbára ẹ lọ́, iṣé ìyàtọ̀ java.lang.arrayIndexOutOfBoundsException ni á dá wa lóhùn.

VI Àwọn ìyípadà àwọn àfidámọ̀

Nígbà tí a bá fẹ́ ṣàlàyé àwọn oníyípadà, ó ṣeé ṣe kí a lò cast (ìyípadà ).

Àpẹẹrẹ

int entier = 5;

float flottant = (float) entier;

Oníyípadà lè mú kí ìsọfúnni má dọ́gba.

Kò síi iṣé nínú java fún ìṣàyípadà àwọn àfidámọ̀, àwọn àlàkalẹ̀ ọ̀wọ́ ni a ń lò fi ṣàyìpadà. Àkójọpọ̀ ọ̀wọ́ ΑPI  ní àwọn ọ̀wọ́ tí a màa ń  fi ṣàyìpadà àwọn àfidámọ̀ oníyípadà ìpìlẹ̀ :

Ọ́wọ́

Ìwúlò

String

Fún àwọn ìsopọ̀ ìró Unicode

Integer

Fún àwọn òùnkà gidi ( integer )

Long

Fún àwọn òùnkà gígun oní àmì ( long )

Float

Fún àwọn òùnkà  oní àmì ojú aléfòó ( float )

Double

Fun àwọn òùnkà oní àmì ojú aléfòó oní ìlọ́po méjì ( double )

Àwọn orúkọ ọ̀wọ́ wọ̀nyìí jẹ́ ọ̀kannáà pẹ̀lú àwọn ti àfidámọ̀ ìpìlẹ̀, àmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ wọn  ni lẹ́tà ńlá. Α máa ń ṣẹ̀dá àwọn ohun ọ̀wọ́ fi lò wọn.

Àpẹẹrẹ

String oromi;

oromi = new String(“oro”);

Ohun ọ̀wọ́ montexte máa fún wa ní àǹfáání láti lò àwọn iṣé ọ̀wọ́ java.lang.String

1) Ìyípadà òùnkà gidi sí àsopọ̀ ìró String

int i = 10;

String oromi = new String();

oromi =oromi.valueOf(i);

Α tún ń lò valueOf(), fún àwọn àfidámọ̀ boolean, long, float, double àti char.

2) Ìyípadà àsopọ̀ ìró String sí òùnkà gidi

Àpẹẹrẹ

String oromi = new String(« 10 »);

Integer onka = new Integer(oromi);

int i = onka.intValue();      //ìyípadà Integer sí int

3) Ìyípadà òùnkà gidi int sí òùnkà gidi long

Àpẹẹrẹint i=10;

Integer onka=new Integer(i);

long j = onka.longValue();

 

VII Ìlò àwọn àsopọ̀ ìró

Ìtumọ̀ àwọn ìró

Àpẹẹrẹ

char onte = ’%’
Ìtumọ̀ àwọn àsopọ̀ ìró

Àpẹẹrẹ

String oro = “kaaro”

Ohun ọ̀wọ́ ni àwọn àfidámọ̀ String jẹ́, ibi gbogbo tí àsopọ̀-ìró aláìṣeéyípadà wà ní àárin àwọn àmì àyọlò. Ètòlẹ́sẹẹsẹ akójọ́pọ̀ máa ṣẹ̀dá ohun ọ̀wọ́ àfidámọ̀ String pẹ̀lú àsopọ̀ ìró ní àárin àwọn àmì àyọlò.
Ó ṣée ṣe kí a kọ
String oro = “ Java Java Java”.replace( ‘a’, ‘o’);
Àwọn àsopọ̀ ìró yàtọ̀ sí àtẹ. Ẹ ní láti lò àwọn àlàkalẹ̀ ọ̀wọ́ String fi lò àwọn ohun ọ̀wọ́ ti ẹ ṣẹ̀dá.

1) Àwọn ìró pàtàkì nínú àsopọ̀-ìró

Àwọn ìró pàtàkì

 

Ìfihàn

\’

Àmì àyọlò

\”

Àmi àyọlò méjì

\\

Àmì ìfẹ́hìnti méjì

\t

táàbù

\b

Àmì ìdápadàsẹ́yìn

\r

Gbígbé padà

\f

Òpin ojú ìwé

\n

Fífọ́ ìlà

\0ddd

Ìró ΑSCII ddd  ẹlẹ́mẹ́jọ

\xdd

Ìró ΑSCII dd ẹlẹ́mẹ́rìndínlógùn

\uddd

Ìró Unicod dddd ẹlẹ́mẹ́rìndínlógùn

2)Àfikún àsopò-ìró méjì

Java máa ń lò oníṣe + fún ìsopọ̀ àsopọ̀-ìró méjì.
Oníṣe + lè fún wa àǹfààní láti ṣé àfikún àsopọ̀-ìró tó jù méjì lọ, a sì tún lè lò +=

Àpẹẹrẹ

String oro = “    “;
oro += “ bawo “;
oro += “abaye “;

Oníṣe yìí tún máa fún wa ni àǹfààní láti so àsopọ̀-ìró pẹ̀lú àwọn àfidámọ̀ ìpìlẹ̀.

Oníyípadà tàbí aláìṣeéyípadà, ni a máa yípadà sí àsopọ̀-ìró ti a fikún àsopọ̀-ìró tí wájú. Nǹkan tó ṣepàtàkì ni kí àsopọ̀-ìró wà nínú àwọn ohun àfikún wọ̀nyìí, bí kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ oníṣe + máa ṣiṣẹ́ bíi àfikún ìṣírò.

Àpẹẹrẹ

System.out.println(“ La valeur de Pi est : “+Math.PI);

int wakati = 121;

System.out.println(“ wakati = “ +wakati);

3) Àfiwé àwọn ìsopọ̀-ìró

Α ní láti lò iṣé equals

Àpẹẹrẹ

String oro1 = « oro 1 »;

String oro2 = « oro 2 »;

if ( oro1.equals(oro2) )…

4) Ìṣírò gígùn àsopọ̀

Iṣé length()  ni a máa lò fi ṣírò.

Àpẹẹrẹ

String ikoro = « ikoro »;

int gigun = ikoro.length();


5) Ìṣàtúnṣe ìwọ̀n ìrísí-lẹ́tà

Àwọn àlàkalẹ̀ Java toUpperCase() àti  toLowerCase() máa fún wa láǹfààní ṣèyípadà ìwọ̀n ìrísí lẹ́tà àsopọ̀-ìró sí ńlá tàbí kékere.

Àpẹẹrẹ

String oro = “ oro “;
String oronla = oro.toUpperCase();

 

Akim Agueh
Author: Akim Agueh

Compte