Semikọ́ndọ́kítọ̀                              Semiconductor                        Semiconducteur

Àwọn adàìtanná-níwọ̀nba  ( Semikọ́ndọ́kítọ̀ )

 

Ìbẹ̀rẹ̀

Inú ohun ìṣẹ̀da kan a lè rí bíi bílíọ́nù ọ̀nà bílíọ́nù atómù ( èròjà akéréjojú )  (ọta).
Αtómù ní kúró ti àwọn ìtanná ( elekítírónì ) máa ń yí àyíká ẹ. Kúró yìí tún ní àwọn èròjà ” kékere méjì : orúkọ wọn ni néútrónì pẹ́lù prótónì. Àwọn néútrónì wọ̀nyìí wọ́n ò níí agbára ìtanná kan. Àmọ́ àwọn prótónì ní agbára ìtanná rere
(+e ). Nínú kúró àwọn èròjà  méjì ti ó ṣe pàtàkì  ni prótónì àti néútrónì
(Àwòran 1).

 

Nígbàgbogbo  àwọn nǹkan ti máa jẹ́ kí a dá atómù mọ̀ ni àwọn òǹkà méjì yìí :

Z : nọ́mbà atómù. Ohun ni ṣe afihan iyé prótónì tó wà nínú kúró atómù, bákan náà ní  tún fún wa ni agbára ìtanná kúró lápàpọ̀ ( +Ze ).

Α: iyé atómù  tàbí ìwọ̀n atómù. Ohun ni fún wa ni iyé nukléónì ( néútrónì àti prótónì )  lápàpọ̀.

Nígbà ti ìwọ̀n nukléónì  àti atómù fẹ́ẹ́ dọ́gba,  a lè sọ wípé ìwọ̀n yìí  dọ́gba mọ́ ìwọ̀n kúró atómù. Bíi àpẹẹrẹ Àwọn ohun àlùmọ́nì méjì ti a máa sábà á lò fi rọ̀ àwọn ẹ̀rọ ìtanná ( rédíò, fóònù,ayára bíi àṣá  …  )  ni Sílíkíọ́mù ( yanrìn, òkuta fúnfún ) àti gẹ́rẹ́maníọ́mù ( inú máínì ẹdẹ ni a ti máa ń ri ). Àwọn ààmi ti a máa lò fún wọn ni Si àti Ge.

                                  Z                                    Α

Ge                            32                                   73

Si                             14                                   28

Lórí àtẹ yìí a lè ri wí pé kúró sílíkíọ́mù ní néútrónì 14 ti gẹ́rẹ́maníọ́mù sì ní 41 néútrónì. Nígbà ti a ti ri àwọn nǹkan tó wà nínú kúró, ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀  nípa àwọn ìtanná ti  ń yí àyíká kúró atómù. Nígbà ti  atómù lápàpọ̀ kò níí agbára ìtanná kan. A lè mọ̀ iyé ìtanná láti ara nọ́mbà atómù Z.
Iyé prótónì tó wà nínú kúró atómù dọ́gbá mọ́ iyé ìtanná ti máa ń yí àyíká kúró ẹ. Bẹ́ẹ̀ atómù ní iyé prótónì (+ Ze) kan náà pẹ̀lú iyé ìtanná (-Ze), nítorí ẹ ni atómù kò níí agbára ìtanná kan. Ìwọ̀n àwọn ìtanná kére púpọ̀ sí ti kúró débi ti a lè sọ wípé ìwọ̀n atómù ni ìwọ̀n kúró ẹ.
Gbogbo àwọn ìtanná ti máa ń yí àyíká atómù, wọ́n ò sopọ̀ mọ́ kúró ẹ bákan náà, Nǹkan tó fà á ti ipá ti wọ́n máa ń kó ni àyìká kúró yìí yàtọ̀. Àwọn ìtanná tí kò jinnà sí kúró ti a máa ń pè ni àwọn ìtanná abẹ́nu, wọ́n so mọ́ kúró púpọ̀, àmọ́ àwọn ìtanná tó jinnà sí kúró wọ́n ò níí àsopọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú kúró, àwọn ìtanná yìí ni a máa ń  pè ni  ìtanná àgbègbè. Àwọn ìtanná yìí ni a tún máa ń pè ni àwọn  ìtanná ìjọ ìta.

Bíi àpẹẹrẹ ti a bá mú atómù sílíkíọ́mù :

Z = 14

Α = 28

Αtómù yìí  ní ìtanná 14, àmọ́ ìtanná 4 ni ti ìjọ ìta.
Èyi fi yé wa wípé, ní àyíká atómù àwọn ijọ̀ ìtanná tó mélòó kan, ìjinnà wọn sí kúró atómù sì yàtọ̀. Ẹ̀rọ ìwòran sípẹ́kitrógráfù fún wa ni àǹfààní láti mọ̀ nọ́mbà Z ti atómù, pẹ̀lú bí ti àwọn ìtanná ṣe pín sí àyíká kúró ẹ. Àwọn olùwadì fún àwọn ìjọ ìtanná ìpele kọ̀ọ̀kan àyíká kúró ni orúkọ, àwọn Orúkọ wọ̀nyìí tún fún wa ni agbára ìtanná àwọn ìpele wọ̀nyìí. Àwọn orúkọ náà ni  K, L, M, N, O, P, Q lórí ìpele kọ̀ọ̀kan àwọn ìtanná kò níí láti pọ̀ju iyé kan lọ, àwọn  iyé náà ni :

  • Ìtanná 2 fún ìpele K

  • Ìtanná 8 fún ìpele L

  • Ìtanná 18 fún ìpele M

  • Ìtanná 32 fún ìpele N

Tí iyé  ìtanná tó wà  lórí ìpele kan bá jẹ́ iyé ti a ṣàlàyé ẹ sókè, a sọ pé ìpele yẹn kún tó. Àwọn oní ìmọ̀-ìṣìrò ri wí pé ti a bá fẹ́ mọ̀ iyé ìtanná ti á jẹ́ kí ìpele kan kún tó a máa lò agbékalẹ̀ yìí : 2n²
Oníyípàdà n ni a máa gbà àwọn òǹkà yìí  1, 2, 3,4.  Òǹkà àwọn ìtanná a máa jẹ́  2, 8, 18, 32 lórí àwọn àyíká K, L, M, N. Pẹ̀lú gbogbo àlàyé ti a ṣe sẹ́yìn wa , a ti rídìí ìgbékalẹ̀ finifini àwọn nǹkan ìṣẹda Líle tàbí èyì ti ń ṣàn bíi omi  tàbí omìí …
Gbogbo nǹkan ti a ṣàlàyé yìí fún wa ni àǹfààní láti mọ̀ ìgbékalẹ́ àwọn ohun àlùmọ́ní, àmọ́ gbogbo àwọn nǹkan kìí ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀, gbogbo ẹ kò sì rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́ àwọn àlàyé yìí ti fún wa ni àǹfààní láti jẹ́ kí ìṣiṣẹ́  àwọn ẹ̀rọ ( ẹ̀rọ ẹlẹ́nu méjì, ẹ̀rọ ẹlẹ́nu mẹ́ta, àtako, ẹ̀run ìtanná …) yé wa.

Àwọn èèyàn fẹ́ran láti fi ètò sí nǹkan ti wọ́n bá ń ṣe, nítorí ẹ ni wọ́n to àwọn atómù pẹ̀lú oǹkà ìwọ̀n wọn ( Α ) sórí àtẹ láti ìwọn kékere fi dé ìwọ̀n ńlá.

Ọgbẹ́ni Mandeleef ni ó ṣe ètò àwọn atómù ti ó wà lórí atẹ àworan 2.

Àwòran 2

Ti a bá wo àworan 2 yìí dáadáa a máa ri wípé ìwọ̀pọ̀ pùpọ̀ ló wà lórí ẹ. Ìwọ̀pọ̀ 8 ni àwọn atómù ti àwọn àyíká agbègbè wọn kún tó. àwọn atomu ìdúrósisin ni wọ̀nyẹn. Àwọn atomu ijọ̀ 1 ni àwọn èyí ti ìtanná ọ̀kan ló wà ni àyiká agbègbè wọn.
Bó  tilẹ̀ jẹ́ wípé fún àwọn atómù pẹ̀lú iyé ìtanná agbègbè ìta tó dọgba, nǹkan ti a lè fi mọ̀ wọn yàtọ̀ ni òǹkà ìwọ̀n atómù ( ni ìnàró lórí atẹ ).
Αtẹ yìí ṣe àfi han bí tí àyiká agbègbè ìta ti ṣe pàtàkì fún ètò àwọn atómù. Àwọn

ìtanná ti ó wà lórí àwọn àyiká agbègbè wọ̀nyìí ni máa ń jẹ́ kí àsopọ̀ wà láàrin àwọn atómù,  èyí ni sì máa ń fún wa ni àǹfààní láti ṣé àwọn éwé, oogùn, àti oríṣiríṣi nǹkan ìlò.
Nítorí náà ohun ìṣẹda ti àwọn atómù ẹ jẹ́, àwọn èyí ti àwọn ìtanná àyíka agbègbè ìta wọn kún to, wọ̀n kò níí  lè so mọ́ àwọn ohun ìṣẹda mì ín.
Bíi àpẹẹrẹ ti a bá wo gáàsì Hélíọmùn, a mọ̀ wípé gáàsì ìdúrosinsin ni, ti a bá sì wo iyé ìtanná ti ó wà ni àyíká agbègbè ìta àwọn atómù rẹ̀, a máa ri wípé àwọn  àyíká wọ̀nyìí kún tó, iyé ìtanná 2 ni atómù ẹ ní , èyí ti ó túmọ̀ sí wípé àyíka ( K ) yìí kún tó. Ti a bá wo ìgbékalẹ̀ àwọn atómù ti gáàsì tàbí ti àwọn ohun ti máa ń ṣàn bíi omi, a á ri pé àwọn atómù wọn kò ní ètò. Ó yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé àwọn nǹkan ti máa ń ṣàn tàbí àwọn nǹkan bíi gáàsì yàtọ̀ sí àwọn nǹkan líle. Nínú àwọn nǹkan wọ̀nyìí, àwọn atómù wọ́n ò sí lórí ètò.
Nínú àwọn nǹkan ṣíṣàn tàbí nínú àwọn gáàsì àwọn atómù, wọ́n kìí pàrọ̀ àyè nígbà gbogbo. Nínú gáàsì  àwọn ìjinnà atómù kan sí omìí jú ìjinnà àwọn ìtanná sí kúró lọ. Èyí tó túmọ̀ sí wí pé àwọn atómù kan wọn kìí fà á àwọn ìtanná atómù mì ín. Fún àwọn nǹkan ti máa ń ṣàn bíi omi, ìjinnà àwọn atomu ní àárin ara wọn kò pọ̀, Èyí túmọ̀ sí wí pé àwọn kúró atómù pẹ̀lú àwọn ìtanná lè máa  fara wọn, nǹkan ti máa fà á ki àwọn ohun ìṣẹda mì ín máa ń le nì yẹn.
Ti a bá wo ohun àlùmọ́nì bíi òkuta iyébíye (díámọ́nì ) a ó  rí wí pé ìgbékalẹ̀ àwọn atomu ẹ ní ètò tó ya ẹni lẹ́nu. Àwọn ohun àlùmọ́nì ti kò mọ́ bíi okuta iyébíye máa  ń ní àwọn ẹ̀yà tó ní ètò dáadáa. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ri wí pé àwọn ètò yìí ni máa  jẹ́ kí líle àwọn ohun àlùmọ́nì yàtọ̀ sí ara wọn. Àwọn atómù sílíkíọ́mù wọ́n kìí ní ètò pípé. Àmọ́ àwọn èyí tí gbogo atómù wọn  bá jẹ́ ọkan náà àwọn náà máa ní ètò pípé,  nígbà mì ín àwọn ètò  yìí máa dàru. Nígbà mì ín àwọn atómù àìmọ́  máa ń wọ àárin àwọn  oní atómù ẹyọ kan. Àwọn atómù àìmọ́ tó kó sí àárin àwọn atómù ohun àlùmọ́nì wọ̀nyìí ni máa ń fún wọ́n ni àwọ̀ ìyàtọ̀.

Bíi àpẹẹrẹ :
Ìjinnà láàrin atómù méjì ni bíi 1 Å, ó jẹ́ 0,1 nm.
Rédíósì kúró atómù ní bíi 10 Å, ó  jẹ́ 1 nm.
Αngström kan jẹ́ 10-10 mita, àmọ́ a ò lò ó  mọ́, nano-mita( = 10 Å ) ni a máa ń lò lónìí. Níbi ti a bá àlàyé wa dé báyìí, a lè máa béèrè wí pé kí ló fà á ti sílíkíọ́mù máa ń le ?  Α á ṣé àlàyé bí ti àwọn atómù máa ń sábà á somọ́ ara wọn ti wọ́n  máa fi di ohun ìṣẹda.

Sísopọ̀ yìí pé oríṣi méjì:

Ìde agbára ìtanná (electrovalent bond )

 

Bíi àpẹẹrẹ ti a bá mú sódíọ́mù  kílóráídì ( iyọ̀ )


   Àwòran 3 :    ìgbékalẹ̀ sódíọ́mù kiloraidi ( iyọ̀)

 

Ti a bá wò ìgbékalẹ̀ àwọn atómù ẹ, a máa ri wípé onígún ni wọ́n  ( àworan 3 ) . Ni ọ̀kọọkan okè gíga onígún yìí àwọn iọ́nù ló wa níbẹ̀. Αtómù sódíọ́mù ( Na) tó sọ ìtanná ẹyọ kan ti  àyíka agbègbè ìta ẹ nù. Nǹkan tó fà á ti ó fi di iọ́nù rere ( Na+)  ( Ìtanná ní agbára òdì, àmọ́ atómù fún ara rẹ̀, kò ní í agbára kan àmọ́ tí ó bá sọ ìtanná  kan nù a máa wá gbà agbára rere +). Αtomu kiloraidi á gbà ìtanná ti atómù sódíọ́mù sọ nù, á wá fi kún àwọn ìtanná méjè àyíká agbègbè ìta ẹ, àyíká yìí á wá kún tó, àmọ́ agbára ìtanná ẹ á wá di agbára òdì. Àwọn òkè àwọn onígún tí máa ń jẹ́ àworan àwọn atómù iyọ̀ ni sódíọ́mù Na+ pẹ̀lú Cl-. Ìṣẹda agbára ìtanná á wàyé ni àárin iọ́nù méjèjì, àwọn agbára wọ̀nyìí ni á so gbogbo àwọn atómù pọ̀. Nǹkan ti a ń pè ni ìde agbára ìtanná nìyẹn (electrovalent bond )

Ìde àsopọ̀ pẹ́lù àwọn ìtanná ( Covalent bond )

Pẹ̀lú ìde yìí àwọn atómù ẹgbẹ̀ẹ́gbẹ̀ méjì, wọ́n máa ń kó àwon ìtanná wọn tó wà ni àyíká agbègbè ìta wọn pọ̀.

Bíi àpẹẹrẹ ti a bá  wò sílíkíọ́mù , atómù ẹ kọ̀ọ̀kan máa kó àwọn ìtanná ìta ẹ mẹ́rẹ́rìn pọ̀ mọ́ ti atómù tó wà ni ẹgbẹ̀ rẹ̀. Àwọn àyíká àwọn atómù méjèjì wọ́n máa wá kún tó. nǹkan ti máa ń fà á kí àwọn ohun àlùmọ́nì mìí má le nìyẹn. Nǹkan ti a ń pè ni ìde àsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ìtanná nì yẹn ( Covalent bond ).

Ní báyìí a lè ṣàlàyé lórí ìmọ̀toto àwọn ìtanná pẹ̀lú kúró atómù sílíkíọ́mù àti ìgbékalẹ̀ àwọn atómù ẹ tàbí ti àwọn ohun àlùmọ́nì mì ín.

Àwọn ohun àlùmọ́nì oríṣiríṣì ló wà:

  • Ohun adàìtanná

  • ohun àìdàìtanná

  • Ohun adàìtanná-níwọ́nba

Àwọn ohun adàìtanná

Idẹ àti aluminiọ́mù ni àwọn ohun adàìtanná ti wọ́n ní agbára jù, tí a bá wo ìgbékalẹ̀ àwọn ohun àlùmọ́nì wọ̀nyìí a máa rí pé àwọn ìtanná arọ́wọ́tó pò tí wọ́n sì yí kiri

Àwòran 4  Ìyípó kiri àwọn ìtanná nínú okun ohun adàìtanná nígbà ti agbára ìtanná kò bá sí
níbẹ̀

Tí a bá lò ìyàtọ̀ agbára sí àwọn èbúté méjèjì okùn ohun adàìtanná, a máa ṣẹ̀da àwọn agbára ìtanná nínú ẹ . Àwọn agbára ìtanná wọ̀nyìí wọ́n a máa dári àwọn ìtanná arọ́wọ́tó wọn. Àwọn ìtanná  pẹ̀lú àwọn agbára ìtanná ibi kan náà ni wọ́n á kọrí sí ( Àwòran 4-1 ).
Bíi àpẹẹrẹ, nínú onígún mita kan a lè ri bíi 1028  ìtanná arọ́wọ́tó.

Àwọn ohun àìdàìtanná  

Nínú àwọn ohun àlùmọ́nì wọ̀nyìí àwọn ìtanná arọ́wọ́tó wọ́n ò pọ̀. Nǹkan ti kìí jẹ́ ki wọ́n máa lè dári àwọn ìtanná wọn nì yẹn.

Nínú onígún mita kan a lè ri bíi 107, àmọ́ ti ìgbóná ohun àlùmọ́nì yìí bá lọ sókè, àwọn  ìtanná arọ́wọ́tó máa pọ̀ sì, nítorí àwọn ìsòpọ̀ àwọn ìtanná àyíká agbègbè ìta pẹ́lù kúró atómù máa  ja, èyí a máa jẹ́ ki wọ́n pọ̀, ti wọ́n sì máa wá yí kiri.

Tí a bá gbé ohun àìdàìtanná sí ibi ti agbaára ìtanná wà nńkan kan kò níí ṣẹlẹ̀ nítorí pé àwọn ìtanná àrọ́wọ́tó wọ́n ò pọ̀, àmọ́ ti a bá gbé ohun àìdàìtanná yìí sí ibi tí agbára ìtanná yìí pọ̀ gan an. Àwọn ìsòpọ̀ àwọn ìtanná pẹ́lù kúró atómù wọ́n máa ja, èyí tó túmọ̀ sí pé àwọn ìtanná àrọ́wọ́tó wọ́n ò níí kére mọ́.

Αdàìtanná-níwọ̀nba ( Semikọ́ndọ́kítọ̀ )

 

Àwọn wọ̀nyìí ni àwọn ohun adàìtanná ti kò níí agbára, àmọ́ pẹ̀lú agbára ìtanná ti kò pọ̀ a lè tú àwọn ìsòpọ̀ àwọn ìtanná pẹ̀lú kúró atómù wọn.

Tí ìtanná bá kúrò lára atómù, agbára ìtanná á di agbára òdi (-) atómù tó sọ ìtanná nù á gbà agbára rere ( + ), atómù yìí á dì nǹkan ti a ń pè ni iónù. ìwọ̀n agbára ti a máa lò fi yọ ìtanná kan lára atómù ni ìtanná-folt ( ev ).
agbára ti ń sọ atómù ohun àlùmọ́nì bíi sílíkíọ́mù di iónù ni ( wi ), ní ìgbóná 27º jẹ́ 1,1 ev. Ti gẹ́rẹ́maníọ́mù ( wi ) ni 0,7 ev . Tí àìdàìtanná gidi bíi òkúta ìyébíye
( diamond ) ní 0,0 ev.
Fún ohun adàìtanná-ìwọ̀nba ìṣẹda àwọn iónù máa ń pọ̀ sì, ti ìgbóná ẹ bá ń lọ sókè, nǹkan ti máa mú ki àwọn ìtanná arọ́wọ́tó máa pọ̀ sì.

 

Lórí àwòran yìí  atómù  ti a pè ni Α ti di iónù rere ( + ) tó sì wà lójú kan, nítorí wípé ó so mọ́ ìgbékalẹ̀ sílíkíọ́mù yìí. Àmọ́ ìtanná tó kúró lára ẹ ti di ìtanná arọ́wọ́tó tí á sì máa yí kiri, ti agbára ìtanná ẹ jẹ́ agbára òdì ( -e ).
Nínú àwọn ohun adàìtanná-ìwọ̀nba, àwon èròjà ti wọ́n ní agbára ìtanná òdì ti wọ́n sì ń gbé e kiri ni àwọn ìtanná nìkan ; agbára ìtanná wọn ni ( -e ).
Ìṣẹda àwọn iónù nínú àwọn adàìtanná-níwọ́nba pẹ̀lú ìgbóná wọn kò tó nǹkan.
Fún ohun àlùmọ́nì bíi sílíkíọ́mù, a lè ri iónù atómù 3 ni àárin 10000 bílíọ́nù atómù ní ìgbóná 27º. Bíi ti àwọn adàìtanná, àwọn ìtanná máa yí kiri nínú àwọn adàìtanná-níwọ̀nba. Ó ṣe é ṣe nígbà mì ín kí ìtanná arọ́wọ́tó kan dé ẹ̀gbẹ́ iónù rere (+) atómù tó sọ ìtanná kan nù . Nígbà yẹn ìtanná yìí lè dàràpọ̀ mọ́ iónù ti agbára ẹ jẹ́ rere ( + ) àwọn nǹkan ti a pè ni ìsọdọ́kan, àwọn atómù wọ̀nyìí wọ́n á padà sí àsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ìtanná. Iónù rere(+) pẹ̀lú ìtanná òdì(-) máa ń fara wọn nítorí wọ́n lòdì sí ara wọn. Nínú àwọn ohun àlùmọ́nì sílíkíọ́mù, àwọn ìsọdọ̀kan máa sábà á ṣẹlẹ̀ ni àárin àwọn atómù. Bíi àpẹẹrẹ ìṣẹda iónù ti atómù Α tó ṣẹlẹ́, ti a sì ṣe àfi han lórí àwòran 5, ìṣẹda iónù mì ín tún lè ṣẹlẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ atómù yìí ti a sọ ní Α1 lórí àwòran 6.

àwòran 6

 

Àǹfààní lè wà fún ìtanná tó kúró ni Α1 láti dárapọ̀ mọ́ iónù Α bí ti a ṣé àfi han lórí àwòran7.

àwòran7

Tí a bá fójú inú wò ó , a máa ri wípé, ó dàbí kí agbára rere (+) kúró níbi kan fi bọ sí ìbòmìí. Nǹkan ti a ǹ pè ni ìyí kiri agbára rere nìyẹn, a tún ń pè ni ìyí kiri kòtò. Ninú adàìtanná-níwọ̀nba yìí agbára òdì ( – ) lè máa yí kiri pẹ̀lú ìtanná arọ́wọ́tó, bẹ́ẹ̀ sì tún ni agbára rere ( + ) lè máa yí kiri pẹ̀lú àwọn kòtò. Nínú ohun adàìtanná-ìwọ̀nba ìtanná  arọ́wọ́to ni máa ń gbé agbára òdì (-e) yí kiri, àwọn kòtò ni sì gbé agbára  rere ( +e ) yí kiri.
Bí tí a ṣe sọ láti ẹ̀yin wá àwọn èròjà wọ́n ò pọ̀ tó nínú àwọn ohun adàìtanná.
Àmọ́ àwọn olùwadìí dọ́gbọn láti fi ohun àlùmọ́nì mì ín díẹ̀ sínú àwọn atomu sílíkíọ́mù ( yanrin )  gidi wọ̀nyìí, ọ̀nà àti jẹ́ ki àwọn ìtanná tàbí ki àwọn kòtò pọ̀ fikun, nǹkan yìí ni a ń pè ni ìró ní agbára ohun adàìtanná-níwọ̀ba.
Bíi àpẹẹrẹ ti a bá dà atómù aréséníkì díẹ̀ sí àárin àwọn atómù sílíkíọ́mù ( yanrin ) ti gbogbo ẹ máa sì di ohun àlùmọ́nì àìmọ́. Èyí tó túmọ̀ sí pé a fi agbára kún agbára adàìtanná-ìwọ̀nba náà. Tí àwọn oní ìmọ̀-ẹ̀rọ bá fẹ́ lò ohun àlùmọ́nì àìmọ́, nǹkan ìwọ̀nba ni wọ́n máa sàbá  á bú sínú ohun àlùmọ́nì mímọ́ ( 1 sínú mílíọ́nù 1 );  àmọ́ ìró agbára yìí kìí kére. Nígbà ti a bú atómù aréséníkì díẹ̀ sínú sílíkíọ́mù, ìyẹwò nínú egùngun X atómù fi han pé àwọn atómù arésénikì dara pọ̀ mọ́ ìde àsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ìtanná ti àwọn sílíkíọ́mù.  Nńkan tí a ṣe túmọ̀ sí wí pé a fi agbára ìdàìtanná fikun agbára sílíkíọ́mù, Αtómù aréséníkì ní àwọn ìtanná ìta márùn ún ti sílíkíọ́mù jẹ́ mẹ́rin ìtanná arọ́wọ́tó kan lé nílẹ̀, ìtanná yìí kò lẹ̀ mọ́ kúró kan. Αgbára ìṣẹda iónù atómù yìí ni wi=0,05 ev. Ti atómù aréséníkì bá di iónù, adàìtanná–níwọ̀nba máa wá ni ìtanná arọ́wọ́tó kan pẹ̀lú iónù tó ní agbára rere tó sì wà lójú kanna.
Bí ti a ṣe wí, ojú kanna ni iónù yìí wà, a ò lè fi wé kòtò ti a sọ̀rọ̀ ẹ sẹ́yìn nítorí a máa ṣòrò fún atómù sílíkíọ́mù láti fà ìtanná fi padà sí àyè ẹ, tó bá tún padà ṣẹlẹ̀, kò níí pẹ́ ti a máa tún padà di iónù. Èyí á mú wa ṣe àtunṣe àwòran 7 tí a sì lò àmi mì ín lórí  àwòran 8.

Ìró lágbára ti a lò sẹ́yìn wá, ló mú atómù aréséníkì tó fi fún ìtanná kan. Nínú sílíkíọ́mù ìró lágbára yìí wáyé pẹ̀lú àwọn atómù olùfúnni, àwọn ìtanná ( – ) pọ̀ jú àwọn kòtò ( + ). Àwọn olùgbéagbára tó pọ̀jù ni àwọn ìtanná arọ́wọ́tó. Ohun àlùmọ́nì ti a ṣẹ̀da ẹ ni a pè ni N, nítorí àwọn ìtanná ti wọ́n ń gbé agbára òdì ló pọ̀. Bí a ti ró sílíkíọ́mù pẹ̀lú àwọn atómù olùfúnni, bẹ́ẹ̀ ni a lè ró ohun àlùmọ́nì pẹ̀lú àwọn atómù olùgbà.
Nínú adàìtanná-ìwọ̀nba sílíkíọ́mù yìí, àwọn atómù olùgbà ní láti ní àwọn ìtanná ìta mẹ́ta. ọ̀kan lára ohun àlùmọ́nì ni atomu ( B ) Bọ́rọ̀. Ójúsí atomu Bọ́rọ̀ ni ọ̀kan láàrin milliọ́nù sílíkíọ́mù. Àwọn atómù Bọ́rọ̀ máa sopọ̀ dáadáa pẹ̀lú àwọn atómù sílíkíọ́mù, àmọ́ o kù ìtanná kan ti wọ́n a máa fi ní àsopọ̀ tó péye , nǹkan ti àwọn atómù bọ́rọ̀ wọ̀nyìí máa ń ṣe ni kí wọ́n máa fà á  àwọn ìtanná atómù sílíkíọ́mù, atómù bọ́rọ̀ a máa wa di iónù òdì , wọ́n máa  wa ṣe ìṣẹ̀da kòtò ti a máa yí kiri. A lè sọ pé iónù òdì yìí á wà lójú kan nítorí agbára ìtanná ti ń mú dúró pọ̀. Ìró agbára adàìtanná-níwọ̀nba sílíkíọ́mù pẹ́lù agbára rere ni a ń pè ni P, nítorí àwọn olùgbé-agbára wọ̀nyìí ni àwọn kòtò. Àwọn olùgbé-agbára òdi ò pọ̀.
Ti a bá gbé okun adàìtanná-níwọ́nba sínú àwọn agbára ìtanná àwọn kòtò wọ́n á máa dà lọ síbi ti agbára ìtanná kọ́ri sí , àwọn ìtanná wọ́n á máa dà lọ síbi òdì.

 

Akim Agueh
Author: Akim Agueh

Compte